Share this:

ILANA ISE SAA KEJI

 

ISE : EDE YORUBA  KILAASI: J.S.S.3

 

ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KEJI

1  EDE: Ihun orisii awe gbolohun po di odidi gbolohun.

 ASA:  Awon asa to suyo lati inu orin etiyeri ati dadakuada.

 LIT:  Akoonu orin etiyeri ati dadakuada

2  EDE:  Aroko leta ( Leta aigbefe).

 ASA:  Awon orisa ati eewo to suyo ninu litireso alohun Yoruba.

 LIT:  Ifaara lori awon litireso alohun ti a fi oro inu won da won mo.

3  EDE:  Iyato to wa laarin apola ati awe gbolohun.

 ASA:  Itan isedale agbalaaye.

4  EDE:  Aroko alalaye –itonisona ati aroso.

 ASA:  Owe Yoruba.

ecolebooks.com

 LIT:  Oriki orile elerin, olokun-esin abbl.

5  EDE:  Aroko alalaye.

 ASA:  Awon akanlo ede Yoruba.

 LIT:  Kika iwe apileko ti ijoba yan.

6  EDE:  Akaye: oloro wuuru/geere.

 ASA:  Awon imole/orisa to suyo ninu litireso.

 LIT:  Kika iwe apileko ti ijoba yan.

7  EDE:  Akaye/Ewi.

 ASA:  Awon imole/orisa to suyo ninu litireso alohun

 LIT:  Kika iwe apileko

8  EDE  Atunyewo Eyan.

 ASA:  Igbese igbeyawo nile Yoruba.

 LIT:  Kika iwe litireso apileko ti ijoba yan.

9  EDE:  Atunyewo awon Oro Aponle.

 ASA:  Ikomojade nile Yoruba.

 LIT:  Kika iwe litireso apileko ti ijoba yan

 1. Atunyewo ise saa kin-in-ni lori ede, asa ati litireso alohun.
 2. Atunyewo ise saa keji lori ede, asa ati litireso alohun.
 3. Atunyewo ise lori iwe apilko ti ijoba yan.
 4. Idanwo saa keji.

 

IWE ITOKASI

 1. Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keta Iwe (J.s.s.3) Longman Nig Plc.
 2. S.Y Adewoyin (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta Iwe (J.s.s.3) Copromutt (Publishers) Nigeira Limitted

 

 

 

OSE KIN-IN-NI

Deeti: …………….

HIHUN ORIISIRISSI AWE GBOLOHUN PO DI ODIDI GBOLOHUN


AKOON:  ODIDI GBOLOHUN

   AWE GBOLOHUN

 

Gbolohun ni iso ti o kun lati ero okan eni wa TABI ki a so wi pe Gbolohun ni ipede ti o kun pelu itumo ti o si ni ise ti o n se. Bi a ba fe ba enikan soro tabi ti a ba fe se iroyin, a maa n se amulo orisii eya gbolohun bi: gbolohun eleyo oro ise, olopo oro ise,alakanpo, ibeere abbl. Ki a ranti pe ninu gbolohun kan, oro ise se pataki nibe. Fun apeere ( odidi gbolohun).

 Wa.

 Ade sun si ori aga.

 Mo wa nile.

 Kunle je eba ni ana.

Ti a ba wo awon gbolohun oke yii a o ri wi pe gbogbo won ni won ni itumo kikun. Nitori naa awon wonyi ni apeere odidi gbolohun. Awe gbolohun ni apa kan odidi gbolohun. Laisi odidi gbolohun ko le si awe gbolohun nitori pe ara odidi gbolohun ni a ti fa a yo. Orisii awe gbolohun ti a ni ni olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe. Ninu odidi gbolohun a le ri awe gbolohun meji tabi ju bee lo. Fun apeere.

 Mo je eba ni agogo meje.

 Mo ti lo ki o to de.

Ti a ba wo awon gbolohun yii daadaa a o ri wi pe gbolohun alakoko, a le pin si meji: Mo je eba ati ni agogo meje. Ni gbolohun keji, a ri Mo ti lo ati ki o to de. Ege kookan yii ni a pe ni awe gbolohun ninu odindi gbolohun.

 Mo ti lo ki ore mi to de

(Olori awe gbolohun) ( awe gbolohun afarahe )

 Mo je eba ni agogo meje

(olori awe gbolohun) ( awe gbolohun afarahe)

 

IGBELEWON

 1. Ki ni gbolohun?
 2. Ki ni awe gbolohun?
 3. Iyato wo lo wa laarin gbolohun ati awe gbolohun?

 

AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta J S S 3 oju iwe 10-12 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.

 

 

 DEETI…………………….

ORIN ETIYERI

Orin idaraya ni orin etiyeri, won maa n gbe eku sori ni bi i ti eegun, eni to gbe eku sori ni yoo maa le orin ti awon yoku a si maa gbe e. Won fi n tu asiri iwa ibaje. A si maa n ri oro awada ati oro alufasansi nibe. Orin yii wopo ni agbegbe ilu Oyo. Apeere.

 

ORIN ETIYERI.

 LILE:  E ma a pe yoo se

 EGBE:  A a se

 LILE:  Ema a pe yoo se

 EGBE:  A a se

 LILE:  Ode roko ode peran

 EGBE:  A a se

 LILE:  Eran kilode pa

 EGBE:  A a se………… .

 DEETI…………………..

DADAKUADA

Orin amuludun to ni oriki, iyin, ilu ati orin ninu ni dadakuada. O wopo ni adugbo igbomina/Ilorin. Bi olori ba ti n le orin ni enikan yoo maa gbe. O maa n kun fun oro apanilerin, won fi n ki eniyan tabi kilo iwa ibaje. Won maa n lo nibi igbeyawo, isile isomoloruko, ayeye oku agba, iwuye. Won maa n lo ilu gangan bi meta nibe. Apeere

 Ile to jo ti olonginni joha le

 Aso lologinni mabi sokoto

 Abinsi, mongani duniyan………..

 

IGBELEWON

 1. Salaye perete lori orin etiyeri
 2. Salaye perete lori dadakuada.

 

AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2004) New Simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 10-12 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.

 Deeti……………………….

ASA TO SUYO NINU ORIN ETIYERI ATI DADAKUADA

ORIN ETIYERI

Orin, ilu ati ijo

Iwure/epe/eebu.

Awada.

Ikilo iwa ibaje.

Koriya.

 

DADAKUADA

Orin, ilu ati ijo

Awada/eebu

Iyin

Oriki

Ikilo iwa

Koriya.

 

IGBELEWON

 1. Awon asa wo lo suyo ninu orin etiyeri?
 2. Awon asa wo lo suyo ninu dadakuada?

 

APAPO IGBELEWON

 1. Ki ni gbolohun?
 2. Ki ni awe gbolohun?
 3. Iyato wo lo wa laarin gbolohun ati awe gbolohun?
 4. Awon asa wo lo suyo ninu orin etiyeri?
 5. Awon asa wo lo suyo ninu dadakuada?
 6. Adugbo wo ni orin etiyeri ti wopo?

 

AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 44-50 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.

 

ATUNYEWO ISE

 1. Ko aroko lori bi o lo isinmi keresimesi ti o koja.

   

ISE ASETILEWA

 1. Ewo lo kun ju lati gbe ero okan eni kale? (a) oro (b) awe gbolohun (d) odidi gbolohun.
 2. Ewo ni ki i se orisii gbolohun Yoruba (a) olopo oro ise (b) alakanpo (d) alatunto
 3. Awe gbolohun wo lo le da duro bi odidi gbolohun (a) olori (b) afarahe (d) asaponle.
 4. Adugbo wo ni orin etiyeri ti wopo ? (a) Ekiti (b) Oyo (d) Osun.
 5. Asa wo lo maa suyo ninu dadakuada? (a) esin (b) eto oselu (d) awada

APA KEJI

 1. Iyato wo lowa laarin odidi gbolohun ati awe gbolohun?
 2. Awon asa wo lo suyo ninu orin etiyeri ati dadakuada?

 

 

OSE KEJI

DEETI…………………..

AROKO LETA AIGBEFE

Leta kiko je ona kan pataki ti a n lo lati ranse si ara eni. Kiko ni a maa n ko o. Ko si ohun ti a o le ko si eniyan afi eyi ti a ko fe ko. A le pin leta kiko si orisii ona meji pataki. Akoko ni leta gbefe (informal letter) nigba ti ekeji je leta aigbefe (formal letter).

Leta gbefe ni leta ti a n ko si eni ti o sunmoni bi baba, iya, aburo, egbon. Leta aigbefe/ alaigbefe ni eyi ti ofin de pe o gbodo tele eto tabi ilana kan pato ti ijoba fowo si. Irufe leta yii ni leta ti a n ko si ile ise ijoba, eyi ti a n ko si ile ise nlanla, leta si ijoba ibile, leta iwase, leta igbaaye lenu ise abbl.

 

 

ETO IGBEKALE LETA AIGBEFE

 • Adiresi
 • Ibere
 • Ori
 • Ikini
 • Koko oro
 • Ipari/igunle.

Adiresi leta aigbefe pin si orisii meji. Adiresi eni ti o n ko leta ati adiresi ibi ti leta nlo (eni ti a n ko leta si). Fun apeere:

12, Opopona Ayedaade,

Ibudoko U-Turn,

Abule Egba

Eko.

10-08-2014.

 

Oga Ile Iwe,

Good Shepherd School,

3, Opopona Olayinka, Moroga,

Meiran.

Oga Agba,

 

Adiresi eni ti o n ko leta yoo wa ni oke apa otun nigba ti adiresi eni ti a n ko leta si yoo wa ni oke apa osi. Leyin eyi ni ibere ati ori pelu awon igbese to ku. Ki i se dandan ni ki a ki eniyan ninu leta aigbefe bakan naa ni a gbodo kiyesi awon oro awada/alufasansi ninu leta yii. A o ki n se awada ninu leta aigbefe.

 

IGBELEWON

 1. Ko adiresi ile re sile.
 2. Ko adiresi ijoba ibile re sile.

 

AKATILEWA

Oyebamji Mustapha (2005)Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (S.S .S.1) oju iwe 16- 21 University Press Plc.

 

AWON ORISA ATI EEWO DEETI……………………

 Eewo je ohun ti eniyan ko gbodo se. O fere je pe gbogbo awon orisa ti won n bo ni ile Yoruba lo ni ohun ti won fe ati ohun ti won ko fe. Ohun ti won fe le je ohun jije tabi mimu nigba ti ohun ti won ko fe le je iwa tabi isesi. Awon ohun ti won ko fe yii ni a n pe ni eewo. Die lara won ni wonyi:

 

 

 

ORISA   EEWO TO JE MO JIJE/MIMU   EEWO TO JE MO IWA/ISESI

Obatala Obatala ko gbodo mu emu funfun tabi

Oti   aisooto, iwa eeri

Ogun eke sise, ole jija,agbere, ile dida, iro pipa

 

Sango won ki I je ewa sese, eku ago ati eso.

won ko gbodo mu siga,won ko gbodo gbe ina ka ori  Igi abo

 

Oya oloya ko gbodo je eran agbo  agbere sise

 

Orisa ibeji  ibeji ko gbodo je eran obo lanbe  ole jija

 

Elegbara/esu  elesu ko gbodo lo adi tabi yanko  ireje, ole, omugo

 

Orisa oko  olusin ko gbodo je isu tuntun lai ti  olusin ko gbodo gba aje

la isu odun fun orisa oko  

 

Ifa onifa ko gbodo je ejo,won ko gbodo fe ireje, iro pipa, olusin ko

gbodo fe iyawo ara won. Adi tabi yanko

 

Gelede  onigelede ko gbodo je ejo ………………

 

Buuku  won ki i je ejo ole jija, eke sise.

 

Ayelala  ………………  ole jija, iro pipa, ile

dida.

 

IGBELEWON

 1. Ki ni eewo jije/mimu sango
 2. Ki ni iwa /isesi ti Oya korira

 

AKATILEWA

Oyebamji Mustapha(2002) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 120-127 UniversityPress Plc.

 

DEETI………………

IFAARA LORI LITIRESO ALOHUN TI A N FI ORO INU WON DA WON MO.

Awon litireso wonyi ki i ni isori kan taara, won o je mo esin bee naa ni won o je mo ayeye lo ju. Apeere won ni oriki, ofo, ese ifa, itandonwe, oro akonilenu, aalo, ewidowe, ede asiko abbl.

A Oriki Orile (family name/praise): Oriki orile ni ewi alohun ti o da lori baba nla eni ati ibi ti won ti se wa. Apeere oriki orile ni onikoyi, Oluoje, Oko irese, Ajisola, Erin, Opomulero, Olofa, Ologbin-in Olufe, Iloko abbl.

B OFO (incantation): Ofo je oro agbara ti awon Yoruba maa n lo pelu oogun. Ofo ni o n fi igbagbo awon Yoruba han ninu agbara oro. Aarin awon adahunse ati onisegun ni o ti wopo. Awon nnkan ti a fi maa n da mo ni: A ki i, oro ase, ebe, awitunwi, iforodara, afiwe.

D ESE IFA (ifa divination ): Awon ni oro agbara ti awon onifa maa n lo. Awon babalawo/onifa ni o maa n da ifa. Awon ti won maa n da ifa maa n wo aso funfun, bata funfun pelu inu mimo. Awon ohun ti a fi maa n da ese ifa ni: Adia fun, ebo riru, awon oruko emi airi.

E ORO AKONILENU; awon oro ti o soro sare pe ni oro akonilenu. Apeere oro akonilenu ni: obo n gbe obo gun ope, Alira n lora rela, Mo je dodo nido ma wa fi owo dodo pa omo onidodo ni idodo.

 

IGBELEWON

 1. Awon ewi alohun wo ni a maa n fi oro inu won da won mo?
 2. Ko oriki orile marun-un sile.
 3. Salaye perete lori ofo.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 55-58 Copromutt (publishers) Nigeria Limited

 

APAPO IGBELEWON

 1. Ki ni eewo jije/mimu sango
 2. Ki ni iwa /isesi ti Oya korira
 3. Ki ni eewo jije/mimu sango
 4. Ki ni iwa /isesi ti Oya korira
 5. Awon ewi alohun wo ni a maa n fi oro inu won da won mo?
 6. Ko oriki orile marun-un sile.
 7. Salaye perete lori ofo.

 

ATUNYEWO ISE

 1. Fun awon gbolohun yii ni apeere mejimeji: gbolohun abode, Olopo Ooro-Ise, Alakanpo.

   

ISE ASETILEWA

 1. Leta …….ni leta iwase. (a) ore (b) gbefe (d) alaigbefe.
 2. Ibi ti adiresi eni ti a n ko leta si maa n wa ni….. (a) isale leta patapata ni apa osi (b) oke leta ni apa otun (d) oke leta ni apa osi
 3. Adiresi eni ti n ko leta maa n wa ni ….. (a) isale leta ni apa otum (b) oke leta ni apa osi (d) oke leta ni apa otun
 4. ……. je okan lara ewi ti a n fi oro inu won da won mo (a) rara (b) bolojo (d) ofo
 5. Orisa wo ni ki I mu emu funfn tabi oti (a) ogun (b) obatala (d) ifa.

APA KEJI

 1. Ko adiresi ile ibi ti o n gbe ati adiresi ijoba ibile re sile
 2. Ko oriki re sile
 3. Ko eewo sango ati orisa oko sile/

 

OSE KETA

DEETI…………………….

IYATO TO WA LAARIN APOLA ATI AWE GBOLOHUN

Awe gbolohun – Laisi gbolohun, ko le si awe gbolohun rara. Ara gbolohun ni a ti fa awe gbolohun yo. Gbolohun eleyo oro ise a maa je olori awe gbolohun, nitori wi pe eyo oro ise kan ni o wa ninu re ti ko si gun gbooro. Sugbon ninu gbolohun olopo oro ise tabi gbolohun alakanpo ni a ti maa n ri awe gbolohun afarahe.

 Awe gbolohun afarahe je eyo oro tabi akojopo oro ti ko le da duro funrare laisi olori awe gbolohun. Awe gbolohun afarahe le je:-

i.awe gbolohun afarahe asaponle.

ii. awe gbolohun afarahe asodoruko.

iii. awe gbolohun afarahe asapejuwe.

AKIYESI-Odidi gbolohun leyin pe o gbodo ni olori awe gbolohun le ni ju awe gbolohun afarahe kan lo.

APOLA.

Apola; – apola ni eyo oro tabi akojopo oro ti o le sise gege bi a ba se lo won ninu gbolohun, won le sise oro-oruko, oro ise, oro aponle ati bee bee lo.

APOLA:-1. Apola oro oruko.

2. Apola oro-ise.

3. Apola oro aponle.abbl

 Ninu gbolohun tabi awe gbolohun akude, oro ni apola ti o ba da wa ni gberefu. Awon wonyi ni apeere apola.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 13-14 Copromutt (publishers) Nigeria Limited

 

IGBELEWON

A 1 Sealaye ohun ti a n pe ni awe gbolohun.

2 Ko iyato to wa laarin awe gbolohun ati apola.

B  Fa awon awe-gbolohun yo ninu awon gbolohun wonyii,iru eya awe gbolohun wo ni okookan won n se?

 1. Baba gba ki a se ise naa lola.
 2. iwa buruku ti Ajayi hu yen kii se ti omoluwabi.
 3. owo mi ti te eeku ida.
 4. omobinrin yen le pada bi o ba fe.
 5. mo ran-an lowo gege bi Eledaa ti o da mi se ran mi.

 

 

DEETI…………………..

ITAN ISEDALE AGBALAYE

AKOOONU: Itan isadale agbalaye.

Igbagbo awon Yoruba.

Igbagbo awon Juu.

Imo awon Sayensi.

Igbagbo awon Yoruba, itan fiye wa wi pe Olodumare funra re lo ran iko merindinlogun wa si ode aye lati wa te ile aye do. Itan so pe obatala ni Olodumare ni ki o se olori iko naa. Olodumare si fun obatala ni ikarahun igbin to ko erupe si inu re. O si tun fun ni eyele onika marun-un lati lo fi da aye. Igba ti won n ti ikole orun bo wa si aye ni obatala ba mu oti yo, o si sun lo fon-fon.

Bayii ni Oduduwa ba gba awon nnkan iseda aye ti Olodumare ko fun obatala, o si ko awon yoku mora ti won fi de ode aye. Omi nikan lo wa ninu aye ko si ile kankan ni akoko yii. Oduduwa wa mu erupe to wa ninu ikarahun igbin, o daa sori omi, o fi eyele naa le ori erupe naa, ni eyele ba bere si tan erupe naa ti ile si n fe titi to fi de ibi ti a n pe ni ile- ife ni aye ode oni.

Igbagbo awon Juu ni pe Olorun da aye pelu oro enu (ase) eyi fidi mule ninu Bibeli mimo pe omi ni gbogbo ile aye tele, Olorun si pase pe ki iyangbe ile ko wa, ko si maa hu eso, o si ri bee.

Awon onimo sayensi ni ohun kan bii boolu to gbona jainjain lo jabo lati orun to si bu gbamu to si fon ka. Eyi to tutu nigba to doju bole di ile gbigbe, eyi to koju soke di omi (odo).

 

IGBELEWON

 1. Salaye itan isedale agbalaye nipa ti igbagbo awon Yoruba
 2. Salaye itan isedale agbalaye nipa imo awon sayensi
 3. Ijora wo ni o wa laarin igbagbo awon Yoruba ati ti imo awon Juu.

 

APAPO IGBELEWON

 1. Sealaye ohun ti a n pe ni awe gbolohun.
 2. Ko iyato to wa laarin awe gbolohun ati apola.
 3. Fa awon awe-gbolohun yo ninu awon gbolohun wonyii,iru eya awe gbolohun wo ni okookan won n se?
 4. Baba gba ki a se ise naa lola.
 5. iwa buruku ti Ajayi hu yen kii se ti omoluwabi.
 6. owo mi ti te eeku ida.
 7. omobinrin yen le pada bi o ba fe.
 8. mo ran-an lowo gege bi Eledaa ti o da mi se ran mi.
 9. Se alaye ijora laarin itan isedale abgalaye Yoruba ati ti igbagbo awon Juu.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 14-17 Copromutt (publishers) Nigeria Limited

 

ATUNYEWO ISE

 1. Salaye lori oge sise ile Yoruba.
 2. Orin ibile Yoruba kan.

 

ISE ASETILEWA

 1. Oro …… je ki awe gbolohun yato si apola (a) atokun (b) oruko (d) ise.
 2. …….. ni nnkan ti o se dandan ju ninu ihun gbolohun (a) apola (b) olori awe gbolohun (d) oro ise.
 3. Ewo ni ki i se otito ninu awon wonyi (a) awe gbolohun maa n ni oro ise (b) awe gbolohun ko kun to apola (d) awe gbolohun maa n ni itumo (e) apola le ni oro ise.

4.  _______ ni Olodumare fi se olori iko to wa te ile aye do (a)Oreluere (b) Obatala (d) Ogun.

5.  _______ kii se ara won (a) Aso (b) Eyele (d) Ikarahun igbin.

APA KEJI

 1. Ko iyato meta ti o wa laarin apola ati awe gbolohn sile
 2. Salaye perete lori itan isedale agbalaye

 

 

OSE KERIN

AROKO ALALAYE DEETI……………………..

AKOONU: Aroko Alalaye

Ilapa ero

Aroko alalaye ni a fi n se ekunrere alaye lori ori-oro kan ti eni ti o ba ka aroko bee ko fi ni ni isoro lati mo ohun ti alaye wa da le lori. Apeere ori oro aroko alalaye ni :

 1. Ise ti mo fe se lojo iwaju.
 2. Igba erun.
 3. Eba tite.
 4. Ise tisa.
 5. Eran osin.

ILAPA ERO ( Ise ti mo fe se lojo iwaju).

 Iru ise wo ni o fe se lojo iwaju

 Alaye lekun-un rere lori ise naa

 Idi ti ise naa fi wu o

 Iru ipo wo ni ise yii le gbe o de

 Ero re lori ise yii.

 

IGBELEWON

 1. Kin ni aroko alalaye?
 2. Ko apeere aroko alalaye meta sile.
 3. Ko ilapa ero lori Igba eerun
 4. Ko aroko lori eba tite.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 80-83 Copromutt (publishers) Nigeria Limited

DEETI………………………….

OWE

Owe ni awon oro ti itumo won jinle ninu asa. Won maa n jeyo ti a ba n so nipa asa Yoruba kan. Bi apeere:

ASA IGBEYAWO

 Bi aya ba moju oko tan, alarina a yeba

 Obe ti bale ile ki i je iyaale ile ki i se

 Eni fun ni lobinrin pari ore.

ASA ISOMOLORUKO

 Ile laawo ki a to somoloruko.

 Agba ki I wa loja ki ori omo tuntun wo.

 Oruko omo ni ijanu omo.

Ti oko ba mo oju aya tan alarina a yeba

IFOWOSOWOPO

 Ajeji owo kan o gbe eru dori.

 Owo omode ko to pepe, ti agbalagba kan ko wo keregbe.

 Gba mi lojo, ki n gba o leerun.

IGBELEWON

 1. Pa owe meta ti a lo fun ifowosowopo.
 2. Pa owe meji ti a le ri nibi igbeyawo.

AKATILEWA

New simplified Yoruba L1 iwe keta oju iwe 68-69 lati owo S.Y Adewoyin

DEETI…………………

ORIKI ORILE

Oriki ni akojopo ewi alohun ti o so nipa itan baba nla wa. O n se alaye nipa awon eniyan kookan ti o je abinibi ile Yoruba. Iran kookan ni o ni orile ibi ti o ti se wa. Iran tabi orile ti onikaluku ba si ti wa ni won maa n ki i mo. Lara ogunlogo iran ti won le ki ojulowo omo ile Yoruba mo ni iran Onikoyi, Oluoje, Ologbin-in Olokun-esin, Aresa, Alaran, Aagberi, Iloko, Erin, Ayerounfe. Apeere oriki:

OLOGBIN-IN

 Bariola elegba ope.

 Omo oba dudu igbo ekoro.

 Omo feni sepo ni bi Resa ninu

 Omo boole o bupo ni i ya Mode lara.

 

 

ORIKI ESO

Eso ikoyi

Iwaju ni onikoyi fi n gbota.

Ikoyi to fi eyin gba ota ojo lo se

Onikoyi kii je okete

Nijo ti omo onikoyi ba je okete

O je eran ara baba re ni…………..

 

IGBELEWON

 1. Ki oriki ologbin
 2. Ki ni oriki ikoyi ati pe ki ni eewo awon omo onikyi?

 

APAPO IGBELEWON

 1. Kin ni aroko alalaye?
 2. Ko apeere aroko alalaye meta sile.
 3. Ko ilapa ero lori Igba eerun
 4. Ko aroko lori eba tite.
 5. Pa owe meta ti a lo fun ifowosowopo.
 6. Pa owe meji ti a le ri nibi igbeyawo.

 

IWE AKATILEWA

 

ATUNYEWO ISE

 1. Ko asa iranra-eni-lowo marun-un sile.
 2. Salaye meta ninu won.

   

ISE ASETILEWA

1  Ewo ni o je mo aroko alalaye ninu awon wonyi? (a) ise tisa (b) ojo ibi mi ti o koja (d) oja ilu mi

2  Ohun akoko ti a gbodo se ti a ba ji laaro ni ……. (a) ki a rin erin (b) ki a jeun (d) ki a ki awon obi wa.

3  Aroko wa gbodo …….. (a) pani lerin (b) mu ki eniyan sun (d) koni logbon

4  Ile laawo ka to somoloruko je mo owe …….. (a) ifowosowopo (b) asa igbeyawo (d) isomoloruko

5  Oro ti itumo re jinle ni awon Yoruba n pe ni ………. (a) owe (b) oro to yidande (d) akoto.

APA KEJI

 1. Ki ni aroko alalaye
 2. Ko itonisona aroko alalaye sile
 3. Pa owe isomoloruko meta sile
 4. Pa owe ifowosowopo meta sile.

 

 

 

OSE KARUN-UN

DEETI………………………………..

AROKO ALALAYE

KIKO AROKO ALALAYE (APEERE)

ISE TI MO FE SE LOJO IWAJU

Iru
ise wo ni o fe se lojo iwaju

Alaye lekunrere lori ise naa

Idi ti ise naa fi wu o

Iru ipo wo ni ise yii le gbe o de

Ero re lori ise yii.

 

EBA TITE

Iru ounje wo ni eba?

Ibo ni eba yii ti wopo?

Bawo ni won se n te eba ( alaye ekunrere)

Ki ni o fa ti o fi feran eba?

Iru ise wo ni eba n se lara.

 

IGBELEWON

 1. Ko aroko lori ” ise ti o fe se lojo iwaju”
 2. Ko aroko lori ” eba tiite

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 82-83 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.

 

DEETI……………………..

AKANLO EDE

Akanlo ede ni awon ipede ti itumo won farasin. Won ki I ni itumo lerefee. Fun apeere: ti a ba so pe “eja n bakan” ti eniyan ba dahun pe “akan” iyen ni pe o dara. Itumo eja ni pe ko dara. E je ki a wo awon apeere miiran ti o je akanlo ede.

 Iyawo su sile iyawo bimo sile

 Fabara kekere gba nla  fi iya je ara eni

 Ta lolobo sofofo fun eniyan

 Teri gbaso ku

 Oba waja oba ku

 Fi aake kori ko jale

 Reju sun

 Fese fe e salo

 Kan oju abe niko  so okodoro oro

 Iseju akan kiakia

 

IGBELEWON

So itumo awon akanlo ede wonyi

 1. gbewiri
 2. oba waja
 3. reju
 4. fi aake kori
 5. iseju akan

 

APAPO IGBELEWON

 1. Ko aroko lori ” ise ti o fe se lojo iwaju”

So itumo awon akanlo ede wonyi

 1. gbewiri
 2. oba waja
 3. reju
 4. fi aake kori
 5. iseju akan

 

AKATILEWA

Egbe akomolede ati asa Yoruba(2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keta (J.S.S.3) oju iwe 69-71 Longman Nig Plc.

 

ATUNYEWO ISE

 1. ki ni iro konsonanti?
 2. Ko gbogbo iro konsonanti sile.

   

ISE ASETILEWA

 1. Aroko wa gbodo …….. (a) pani lerin (b) mu ki eniyan sun (d) koni logbon
 2. Orisii aroko to tun wa ni …… (a) aroso (b) agbaso (d) alalaye
 3. Ti a ba fe ko aroko, a gbodo yan …..(a) ikadi (b) ifaara (d) ori oro
 4. Itumo “reju” ni ……. (a) sun (b) salo (d) jeun (e) sa ere
 5. Itumo fese fe e ni (a) sun (b) salo (d) jeun.

APA KEJIi

 1. Ko aroko lori ” eba tite ”
 2. Ko aroko lori ise ti mo fe se lojo iwaju.
 3. Tumo awon oro wonyi.
  1. reju
  2. ta lolobo
  3. fi aake kori.

 

 

OSE KEFA

AKAYE

(Ni ile akanbi, Adetutu n fo aso, Omolola, iyawo n gbale)

Omosola gbale si Adetutu lara, o da aso re nu. Wahala bere. Omosola gba kuuru mo iyaale re, oni … enikan ni yoo lo fun enikeji ninu ile yii…. Omosola ni iyaale oun ni ko je ki oun loyun. Adesola fun aso mo Adetutu lorun. Adetutu kigbe pe ara ile e gba mi. Omosola de eyin mo on lapa. Adetutu ja ara re gba, o sa wole. Omosola bu serin. O ni mo fi eyin dara si lara….. Omosola n da soro ko mo pe Adetutu n gbo: “Sebi Adesewa, akobi re, emi ti mo yanju re niyi…. Adepeju abitele, emi ti mo je ko fo sanle ko ku niyi…. Abigbeyin loro wa kan bayi…. Looto omo odun mefa ni sugbon kekere Daodu kan ko si…. Oro yii ba Adetutu leru, kia, o gbe apoti re ati omo re , Adeolu, o salo.

Inu Omosola dun wi pe oun ti le iya ati omo re jade. Oni ki oun wa fi abo ba oko oun lo ku ati pe ko si eni yoo ba oun pin ninu gbogbo nnkan ini Akanbi. Akanbi wole, o wadii oro ti

Adetutu fi ko jade nile. Omosola rojo eke pe ooto ni aawo kekere wa laarin awon sugbon…… “to ba je pe nitori gbolohun aso ranpe to waye lonii ni iyaale se gberu, n ko ro wi pe ebi to si mi rara.” Oko won sare jade lati wa a lo. Inu Omosola baje, o bere si soro bi ofo pe osan ati oru ki I pade, Akanbi ati Adetutu ko ni foju ri ara won laelaae.

 

IGBELEWON

 1. Daruko awon iyawo meji ti a ri ninu akaye yii
 2. Ta ni alaseju ninu ayoka yii
 3. Ta ni baale awon iyawo wonyi
 4. Se alaye ayoka yii lerefee

 

AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 45-45 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.

 

 

 

DEETI …………….

AKORI ISE: – SANGO PIPE  

AKOONU: –  

 • Ohun ti oro inu re da le lori
 • Agbara Sango
 • Awon aya Sango
 • Eewo Sango

   NOOTI

   Sango olukoso oko oya

   Oloju orogbo, elereke obi

   Ina loju, ina lenu

   Ajagajigi, ewelere ajija

   Ayan ran ina

 Ina gori ile feju

 Iku tii pa ni tenikan o le mu

 Sango ma ba mi ja

 N o lowo ebo ni le

 Ibinu olukoso o see so

 Ija re gan-an oran

 A fose yo ni loju

 A fedun yo fun

 A feefun se ni ni pele

 A fina fahun bi o soro

 O benikan ja fowo gun gbogbo ile loju

 Oro gon oparun jokoo

 Ako olongo ti n wewu ododo

Sango je okan lara awon oba to ti je ni Oyo ile laye atijo gege bi oba, Sango ni agbara, oogun ati igboya, ina si maa n jade lenu re bulabula to ba n soro, Nigba ti ilu dite mo nitori asilo agbara re lo lo pokun so nidi igi aayan ni ibi ti won n pe ni koso.

 Oriki sango lo maa n poju ninu sango pipe won maa nlo lati yin-in lati dupe lowo re bi o ba se won loore ati lati be e fun idaabobo, bibo asiri won ati lati beere fun awon nnkan ti won se alaini. Awon nnkan ti sango n lo gege bi agbara ni ose sango, edun ara ati ina to maa n yo lenu re.

 Iyawo meta ni Sango ni nigba aye re, Oya, Osun ati Oba, Oya wole ni Ira o si di odo ti a mo si odo oya di oni oloni. Sango korira siga mimu, obi, ewa ati eku ago jije.

 

IGBELEWON

1.  Ki ni awon oro inu sango pipe maa n da le lori

2.  Awon nnkan wo ni sango maa ri fi se agbara

3.  Iyawo meloo ni sango ni, Daruko won

4.  Ki ni awon nnkan to je eewo fun sango

 

APAPO IGBELEWON

1.  Ki ni awon oro inu sango pipe maa n da le lori

2.  Awon nnkan wo ni sango maa ri fi se agbara

3.  Iyawo meloo ni sango ni, Daruko won

4.  Ki ni awon nnkan to je eewo fun sango

 

AWON IWE KIKA

1.  S.Y Adewoyin (2004) New simplied Yoruba L1 book three(J.S.S.3) oju iwe 43 – 44 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.

2.  Oyebamiji Mustapha (2002) Eko ede Yoruba titun Iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 11, 12 University Press Plc.

3.  Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba (J.S.S.3) Iwe keta oju iwe 22- 23 Longman Nigeria Plc.

 

ATUNYEWO ISE

 1. Se akosile itan isedale Yoruba.
 2. Fun akoto ede Yoruba ni oriki.

 

ISE ASETILEWA

1  Aroko wa gbodo …….. (a) pani lerin (b) mu ki eniyan sun (d) koni logbon

2  Orisii aroko to tun wa ni …… (a) aroso (b) agbaso (d) alalaye

3  Ti a ba fe ko aroko, a gbodo yan …..(a) ikadi (b) ifaara (d) ori oro

4  …. Je okan lara awon iyawo sango. (a) Moremi (b) Efunsetan (d) Osun.

5  Okan ninu agbara sango ni ……. (a) edun ara (b)ijakadi (d) omi.

APA KEJI

 1. Awon nnkan wo ni sango fi se agbara
 2. Awon nnkan wo ni oro inu sango pipe maa n da le lori

3   Ki ni akaye

4 Awon ilana wo ni a gbodo tele bi a ba fe ko aroko

 

 

 

OSE KEJE

AKAYE (EWI)

Deeti…………….

IWULO IYIPADA

 Iyipada ki i se ohun eru

 Iyipada ki i se ohunn a sa fun

 Nse lo ye ka maa reti re

 Nitori bi o si iyipada,

Eyin o le dakuko

 Agbado te e si ri n ko?

Won iba ti dogi.

Isu iba ma parada legan,

Nse ni iba ti si ohun ti n je iyan,

Iyan to je ounje gidi.

Kiba ma ti si iyipada,

Akekoo iba si wa ni yara ikawe kan soso

Kiba si ti je ohun ti n je ipo kin-in-ni laelae.

Yiyi ti igba n yi,

Sebi oun lo n mu igba eda dun.

Ti ko je ka wa bi omi adagun

Toro awon agba ja si otito pata

Pe igba laso

Igba leeyan

Akekoo, ma se beru iyipad mo

Ohun gidi ni i se.

 

IGBELEWON

 1. Ki ni koko ewi yii
 2. Fa ona ede yo ninu ewi yii
 3. Ko ibeere pesije inu ewi yii sile

 

AKATILEWA

S.Y Adewoyin (2004) New simplied Yoruba L1 book three(J.S.S.3) oju iwe 117-125 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.

 

DEETI……………………………..

AWON IMOLE/ORISA ILE YORUBA

OGUN( god of iron)

Ode ni Ogun ni aye atijo.

Tabutu ni oruko iya ogun.Oririnna si ni baba re

O je oye Osinmole ni ile Ife, ki o to lo si ilu ire Ekiti

Mariwo ni aso Ogun, eje lo si maa n mu

Gbogbo ohun to je mo irin je ti ogun

Ogun korira ki won gbe koronfo agbe emu duro

O tun korira iwa eke, iro pipa, ole jija

MOREMI

Moremi je omo ilu ofa, o fe oko ni ile ife

Akinkanju obinrin ni. O ran awon ara ile ife lowo lati segun awon igbo ti won wa n ko won leru

Ni odun ti ogun de, ofi ara sile, won ko leru

Ni ilu awon igbo, o ri asiri pe iko gbigbe ni won n da bora

O sa pada si ile ife, lati tu asiri naa.

Odun keji ti won de. Gbogbo ilu tan ina ogunso onigi gbogboro, won si ko opolopo awon igbo leru

Moremi fi omo re rubo gege bi ileri to se

 

IGBELEWON

 1. Salaye perete lori Ogun
 2. Salaye perete lori Moremi

APAPO IGBELEWON

 1. Salaye perete lori Ogun
 2. Salaye perete lori Moremi
 3. Ko akanlo ede ayaworan merin sile

ATUNYEWO ISE

 1. Se alaye lekun-un rere lori oro-aponle pelu apeere.

AKATILEWA

S.Y Adewoyin (2004) New simplied Yoruba L1 book three(J.S.S.3) oju iwe 59-61 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.

 

ISE ASETILEWA

 1. Ki a ma tun oro kan so ju eekan lo ni ……. (a) afiwe taara (b) afiwe elelo (d)awitunwi.
 2. “Agbado te e si ri n ko ?” je apeere ……. (a) ibeere pesije (b) afiwe taara (d) afiwe elelo.
 3. ki ni ewi alohun Ogun? ……….. (a) ijala (b) orin ogun (d) ogun pipe.
 4. ………. ni o ran awon ara ile ife lowo lati segun awon ugbo (a) ogun (b) Moremi (d) ooni.
 5. Ta ni awon Yoruba gbabgo pe oni agbara lori irin (a) ogun (b) Moremi (d) Ooni.

APA KEJI

1  Salaye perete lori ogun gege bi orisa ile Yoruba

2  Salaye perete lori Moremi gege bi orisa ile Yoruba.

 

OSE KEJO

ATUNYEWO EYAN Date………………

Eyan ni awon oro ti a n lo lati yan oro oruko. Awon oro wonyi maa n bu kun itumo oro oruko ninu gbolohun ni gege bi oro aponle ti maan fi kun itumo oro ise. Ni opo igba won maa n tele oro oruko ti won n yan. A ni eyan ajoruko, eyan asapejuwe, eyan asonka, eyan asafihan, eyan atoka asafihan. Fun apeere:

1  Eyan Ajoruko:

Ile oba ni a wa

Owo Dupe ni mo na

Owo moto mi da?

2  Eyan Asapejuwe

Ilu kekere ni won lo

Eniyan rere ni o pe ara re

Eja dindin dara

3  Eyan Asonka

Eja meta ni ki o je

Baba ko ile meji

Awon ole ko ile ogun

4  Eyan Asafihan

Omo yii

Aja yen n je igbe

Ile ohun ni a n soro re

5  Eyan Atoka Asafihan

Ilu naa dara lati wo

Emi naa paapaa n bo

Ilu wa yii dara.

 

IGBELEWON

Fa ila si idi eyikeyi eyan ninu ayoka yii

Oro pataki kan ni mo fe ba gbogb yin so ni irole yii. Mo ti ri awon agbaagba ilu, mo si ti feti si imoran won ti e ni ki n beere. Ni ale ola gbogb odomokunrinalagbara ni a o pe.

 

AKATILEWA

Ayo Bamgbose (1990) Fonoloji ati girama Yoruba oju iwe 119-130

DEETI………………………………..

ETO IGBEYAWO ABINIBI

AKOONU

 • IFOJUSODE
 • ALARENA
 • IJOHEN/ISIHUN
 • ITOORO
 • IDANA
 • IGBEYAWO

Igbeyawo abinibi tumo si ona tabi awon ilana ti a n gba se igbeyawo ni aye atijo. Okan pataki ni asa igbeyawo je ninu awon asa Yoruba, asa to gbajumo, ti ko se e fowo yepere mu si ni.

IFOJUSODE:-

Ni aye atijo, bi omokunrin kan ba wa to si ti to iyawo fe, oun ti yoo se ni pe yoo bere si ni foju sode lati wa omobinrin to ba wu u, eyi ni a n pe ni ifojusode. Awon obi paapaa a maa foju sode lati wa iyawo fun omo won, iyen ni pe awon obi paapaa ma n fe iyawo fun omo won. Nigba ti omokunrin yii ba ti ri omobinrin to wu u yii, ki i se pe yoo kan ku giri lo ba a wi pe mo fe fe o. Ohun to maa se ni pe yoo wa enikan to ba sun mo omobinrin naa ti yoo maa ba a ba omobinrin naa soro. Iru eni bee ni a n pe ni alarena.

ALARENA:-

Okan pataki ninu ise alarena yii ni lati se iwadii finifini nipa omobinrin naa ati idile re. Eni to ba se e finu tan ni a maa n lo gege bii alarena nitori ise elege ni ise naa. Oun ni yo mo gbogbo ogbon ati ete ti yoo lo lati ri pe omobinrin naa je hoo. Ni kete ti awon mejeeji ba si ti pade ti won ti moju ara won ise alarena pari niyen. Eyi ni won fi maa n powe pe bi oko ba moju aya tan alarena a yeba.

IJOHEN/ISIHUN

Orisiirisii iwadii ni awon idile omobinrin naa maa n se lati mo iru idile ti omokunrin to fe fe omo won ti wa. Boya won ni aisan kan to n ja won tabi idile onigbese ni won. Ti ko ba ti si iwa abuku kankan ni idile naa, ti o si dun mo omobinrin lati fe okunrin naa ni omobinrin naa yoo to wa dahun pe oun gba. Gbigba ti omobinrin yii gba lati fe omokunrin naa ni a n pe ni ijohen tabi isihun.

ITORO

Gege bi asa Yoruba, ni kete ti omobinrin ba ti johen fun omokunrin oun ti o kan ni ki awon obi omokunrin naa lo se itoro lodo awon obi omokunrin naa. Ibi ni gbogbo eniyan yoo ti mo won gege bi afesona ti won yoo si da ojo idana

IDANA

Ojo idana ni ojo ti awon ebi omokunrin naa yoo wa san gbogbo ohun ti awon ebi iyawo ba fe gba patapata laiku eyokan. Ariya ranpe le waye ni iru ojo yii, igba yii ni won to sese ma mo awon mejeeji gege bi oko ati iyawo, won a si da ojo igbeyawo.

IGBEYAWO

Bi idile oko tabi idile iyawo ba se lowo to, bee naa ni ayeye igbeyawo won yoo se larinrin to, yato si pe to ba je won ko gbodo se igbeyawo alariwo gege bi iwadii ti won base.

Gege bi asa igbeyawo ni ile Yoruba owo irole ni iyawo maa n lo ile oko re nitori ero ni won ka asiko yii si. Ki o to di asiko yii ni yoo ma a kaakiri lati gba adura lenu awon obi ati ebi re ti won yoo si maa fun ni amoran lorisiirisii. Ni ale ojo keta, o di dandan ki oko to sunmo iyawo re lati mo boya o ti mo okunrin ri tele. Abuku gba a ni o maa n je fun iyawo ati awon ebi re to ba ti mo okunrin tele. Sugbon ti ko ba ti i mo okunrin kan tele, oriire n la ni fun won.

 

IGBELEWON

1.  Ki ni a n pe ni ifojusode ninu eto igbeyawo abinibi

2.  Se alaye ise alarena

3.  Kini ijohen tabi isihun tumo si

4.  Kini iyato laarin itoro ati idana

 

APAPO IGBELEWON

 1. Ki ni a n pe ni ifojusode ninu eto igbeyawo abinibi
 2. Se alaye ise alarena
 3. Kini ijohen tabi isihun tumo si
 4. Kini iyato laarin itoro ati idana
 5. Se alaye die lori eyan.

ATUNYEWO ISE

 1. ki ni oro-apejuwe?
 2. Ko apeere oro-apejuwe marun-un ki o lo o ni gbolohun.

AKATILEWA

Oyebamiji Mustapha (2002) Eko ede Yoruba titun Iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 114-118 University Press Plc.

Oyebamiji Mustapha (2002) Eko ede Yoruba titun Iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 85-92 University Press Plc.

 

OSE KESAN-AN

DEETI………………………

ORO APONLE

Oro aponle (adverb): Oro aponle ni a fi n pon oro-ise le ninu gbolohun. Ni opo igba a maa n ba won ni iwaju oro ise ninu gbolohun ni. Bi apeere:

 Igi ope naa ga fiofio

 Oko naa run womuwomu

Ata naa pon wee

Olu sare tete

IGBELEWON

 1. fa ila si idi oro aponle ninu awon gbolohun wonyi

Omo naa fo feere

Ise yii le jojo

O n jeun waduwadu

Iwe naa ya perepere.

AKATILEWA

 1. Oyebamiji Mustapha (2002) Eko ede Yoruba titun Iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 1-4 University Press Plc.
 2. S.Y Adewoyin (2004) New simplified Yiruba L1 iwe keta oju ewe 1-5 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.

 

 

 

 

 

 

 

 

 


 
Share this:


EcoleBooks | 2ND TERM JSS3 YORUBA Scheme of Work and Note

subscriber

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Accept Our Privacy Terms.*