Share this:

FIRST TERM E-LEARNING NOTE

SUBJECT: YORUBA LANGUAGE CLASS: JSS3

1 Ede:    Atunyewo fonoloji ede Yoruba.

Asa :  Isinku nile Yoruba.

Litireso:  Awon ewi alohun ti o je mo esin abalaye iyere ifa, Sango pipe.  

2 Ede:    Aroko alalaye

Asa:    Ogun pinpin

Litireso:  Awon ewi alohun to je mo esin abalaye. Ijala, ewi egungun, Oya pipe.

3 Ede:  Atunyewo awon apola ninu gbolohun ede Yoruba. apola oruko ati apola ise

Asa :  Asa ti o suyo ninu awon ewi alohun to je mo esin abalaye

Litireso:  Kika iwe litireso apileko ti ijoba yan.

4 Ede:  Atunyewo awon eya gbolohun ti o wa ninu ede Yoruba.

Asa :  Atunyewo awon ere idaraya ile yoruba

Litireso:  Kika iwe litireso apileko

5 Ede:  Gbolohun ibeere – awon wuren ibeere ti a fin se ibeere – da, n ko, nje, ki

ecolebooks.com

Asa :  Atunyewo asa iranra – eni – lowo, owe, aaro, obese, esusu, ajo.

Litireso:  Kika iwe litireso ti ijoba yan.

6 Ede:  Aroko alariyanjiyan

Asa :  Atunyewo asa oge sise

Litireso:  Kika iwe litireso ti ijoba yan

7 Ede:  Ifaara lori ibasepo laarin awe gbolohun ati gbolohun ede Yoruba.

Asa :  Awon orisa ile Yoruba.

Litireso:  Kika iwe litireso ti ijoba yan.

8 Ede:  Ifaara lori orisirisi eya awe gbolohun

Asa :  Awon orisa ile Yoruba. Ogun.

Litireso:  Kika iwe litireso ti ijoba yan.

9 Ede:  Eya awe gbolohun

  a.  Olori awe gbolohn

  b.  Awe gbolohun afarahe

Asa :  Awon orisa ile Yoruba:- Sango.

10 Ede:  Eya awe gbolohun – awe gbolohun afarahe asodoruko, asapejuwe, asaponle

11 – 12    Atunyewo ise ateyinwa.

13    Idanrawo.

IWE ITOKAS

1  Eko ede ati asa Yoruba. Iwe keji lati owo Egbe akokolde ati asa Yoruba

 1. New simplified Yoruba L1 Book Two. Lati owo S.Y. Adewoyin
 2. Eko ede Yoruba titun iwe kejI lati Oyebanji Mustapha

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

OSE KIN-IN-NI

AKORI ISE (EDE):   IRO PIPAJE DEETI ……………………

AKOONU:-  Iro pipaje

Konsonanti pipaje


Faweeli pipaje

 Iro pipaje ni dindin iye iro ti a pe ku nigba ti a ba n soro. A le pa iro konsonanti je be e naa ni a le pa iro faweeli je. Iro knosonanti pipaje ni dindin iye iro knosonanti ku nigba ti a ba n soro nigba ti iro faweeli pipaje maa je dindin iye iro faweeli ku ti a ba n soro. Iro pipaje yii wopo ninu eka ede Oyo. Awon iro ti a sakiyesi pe won saba maa n paje ju ni: r, w,y,’h,l ati k.

 Apeere   iro  “r”

Akara – Akaa

Dire – Die

 Apeere iro  “w”

Jowo – Joo

Omoluwabi – Omoluabi

 Apeere iro  “y”

Adiye – Adie

Riyeriye – Rierie

 Apeere iro  “h”

Osugbohun – Osugboun

Olohun – Oloun

 Apeere iro  “l”

Metalelogbon – Metaleogbon

Tile – Tie

 Apeere iro  “k”

Adekiitan – Adeitan

FAWEELI PIPAJE:

 Ibaluwe – baluwe

 Iyanrin – yanrin

 Omotola – Motola

 Ka iwe – kawe

 Eti Odo – Etido

 Irun agbon – Irungbon

 Ewe Oko – eweko

 

NAME……………………………………………………….. CLASS………

A o ri wi pe bi o tile je pe a pa iro knosonanti ati awon iro faweeli won yii je, ko se akoba fun itumo okankan ninu won.

IGBELEWON

 1. Kni ni iro pipaje?
 2. Se ipaje awon oro won yii, (i) ibaluwe (ii) Adiye (iii) Akara (iv) iyara (v) jowo (vi) Olohun

  (vii) ewe oko (viii) Dire

IWE AKATILEWA

1  Eko ede ati asa Yoruba iwe keji oju iwe 78 – 81. iati owo Egbe akomolede ati asa Yoruba

 

AKORI: ASA ISINKU ATI EWI ATENUDENU TO JE MO AYEYE ISINKU

AKOONU:- DEETI…………………

 • ASA OKU SISIN
 • EWI TI A N LO NIBI AYEYE ISINKU
 • IREMOJE, OKU PIPE ATI IGBALA SINSIN

Awon Yoruba gba pe bi aye ba ti ye ni si, ni sisin oku eni ni ti n rii. Bi olowo ba ku, bi won yoo ti sin oku re yato gedegbe si bi won se n sin oku mekunnu. Iru iku to ba pa eniyan ni yoo se okunfa iru isinku ti won yoo se. Bi omode ba ku, oku ofo ni, iwonba ni a le se lori oku bee. Bi ijoye ba ku, oku gbogbo ilu ni, be ni bi otosi ba ku, kii fi be mile rara.

Leyin ti oku ba ti ku, itufo ni o kan ti won ba ti tufo re ni won n gbe ile oku. Laye atijo inu ile ni won maa n sin oku si. Oku wiwe, lohun to kan. Awon Yoruba gba pe eni won to ku ko ku gbe ati pe bi won ba sin-in pelu idoti, inu idoti ni yoo wa laelae, eyi lo mu ki won maa we foku. Leyin ti won ba we fun tan ni won yoo dii pelu aso olowo iyebiye bi o tile je pe aso funfun ni won saba maa n lo. Laye atijo ti won ba n gbe oku lo si ibi ti won fe sin-in si, akobi oku lo maa saaju ti yoo si maa tu adiye
irana rin.

Gege bi ewi atenudenu se wa fun ayeye igbeyawo ati ikomojade naa lo wa fun ayeye isinku agba. Lara awon ewi alohun ti a ya soto fun isinku ni oku-pipe, iremoje ati igbala sinsin. Yato si eyi orisi orin tun wa bakan naa ti awon eniyan maa n ko nigba ti oku ba ku, won a tun maa sun rara, akorin etiyeri ati pe won a tun maa da ege nibi oku agbalagba.

OKU PIPE: Yoruba ka iku si ohun ibanuje pupo. Nigba ti iku ba de, ekun a gba ile kan. Awon eniyan yoo bere si ni pohun rere ekun, won yoo si maa so orisirisi ohun to ba bo si won lenu lati fi edun okan won han. Iru ekun bayii ti won fi maa n pe oku bi eni pe ko dide soro ni a n pe ni oku-pipe.

IGBALA SISUN: Ewi ti awon eniyan fi maa n daro eni to ku nile Egba ni a n pe ni igbala sinsin. Ohun aro gba a ni won fi maa n sin-in ti ori awon ebi oku a maa wu pupo, o si maa n mu eniyan lokan gan-an.

IREMOJE Ale patapata titi di oganjo oru ni won maa n sun iremoje, ko dabi ijala ti won le sun nigba kugba. Ohun ti won fi n sun ijala naa ni won fi n sun iremoje. Awon ologun-un ati awon ode ni o maa n sun iremoje, ibi ayeye isinku akikanju ode ni o si ti maa n waye nitori orin idaro fun asekagba oku ode ni.

IGBELEWON

 1. Salaye soki lori awon ewi wonyi

 

 

NAME………………………………………………………..CLASS…………………………………

 

 (a)  Oku-pipe  (b)  iremoje  (d)  igbala-sisun

2.  Salaye bi a se n se eto isinku ni ile Yoruba

3.  Awon ewi alohun wo ni a le lo nibi ayeye isinku

.

 

AKORI ISE (LIT): AWON EWI ALOHUN TO JE MO ESIN ABALAYE DEETI …………………

Akoonu :-

– Iyere Ifa

– Esa egungun / Iwi

– Sango pipe

Ni aye atijo ki awon alawo funfun to mu awon esin igbalode wa saarin awon Yoruba, Orisirisi esin ni awon baba nla wa n sin ti awa si jogun ba lowo won. Bi orisii awon esin yii se wa naa ni a ni awon ewi alohun tabi ewi atenudenu ti a n lo fun okookan won. Iyen ni pe oni irufe ewi ti a fi maa n ki awon orisa kookan ti a n sin ni ile Yoruba.

 Iyere ifa: ni orin awon babalawo ti won saba maa n ko ni asiko ti won ba n se odun ifa, sugbon iyere sisun le waye nigba ti babalawo ba n ki ifa lowo tabi ti won ba n se ayeye kan bii etutu ati igba ti won ba fe bo ifa.

 Esa egungun/iwi: ni ewi alohun ti awon olusin egungun maa n lo nigba ti won ba n se odun egungun. Awon lo maa n je oruko mo oje, awon oruko bii Ojekunle Ojeniyi Ojedele ati bee bee lo. TakoTabo idile oloje lo le pe esa.

 Sango pipe: ni ewi awon adosu sango awon ni olusin sango, o le je okunrin tabi obinrin, ko si eni ti ko le ki oriki sango. Asiko ti won ba n bo sango tabi se odun sango ni sango pipe ti maa n waye ju.

IGBELEWON

 1. Daruko ewi atenudenu merin to je mo esin abalaye pelu awon orisa ti won n fi awon ewi naa bo

IWE AKATILEWA

 1. Eko ede ati asa Yoruba iwe keta lati owo Egbe akomolede ati asa Yoruba oju iwe 14 – 16.

ISE ASETILEWA

 1. Jowo yoo di ________ ninu ipaje/isunki (a) Jaa (b) Joo (d) Jowoo
 2. Ewo ni a ko le lo nibi ayeye isinku (a) Oku pipe (b) Igbala sisun (d) ekun iyawo.
 3. ________ ni o maa n tu adie irana (a) akobi oku (b)abigbeyin oku (d) egbon oku
 4. Esa egungun ni a mo si _________ (a) iwi kike (b) owe kike (d) iwi siso
 5. ________ ni won n fi iyere sisun bo (a) Ifa (b) Esu (d) Babalawo

 

NAME………………………………………………………..CLASS……………………………

APA KEJI

 • Awon ewi alohun wo ni a le ba nibi isinku.
 • Ko ewi alohunmarun ti a le ba nibi esin abalaye sile.
 • Se isunki/ipaje awon oro wonyi
  • Jowo
  • Omolara
  • Omoluabi
  • Adiye

 

 

OSE KEJI

AROKO ALALAYE

AKOONU: Aroko Alalaye DEETI ………………..

Ilapa ero

Aroko alalaye ni a fi n se ekunrere alaye lori ori-oro kan ti eni ti o ba ka aroko bee kofi ni ni isoro lati mo ohun ti alaye wa da le lori.Apeere ori oro aroko alalaye ni :

 Ise ti mo fe se lojo iwaju

 Igba erun

 Eba tite

 Ise tisa

 Eran osin

ILAPA ERO ( Ise ti mo fe se lojo iwaju}

 Iru ise wo ni o fe lojo iwaju

 Alaye lekun-un rere lori ise naa

 Idi ti ise naa fi wu o

 Iru ipo wo ni ise yii le gbe o de

 Ero re lori ise yii.

IGBELEWON

 1. Kin-in-ni aroko alalaye?
 2. Ko ori meta ti aroko alalaye
 3. Ko ilapa ero lori Igba erun
 4. Ko aroko lori eba tite

IWE AKATILEWA

1 New simplified Yoruba L1 iwe keta oju iwe 80-83 lati owo S Y Adewoyin.

 

 

AKORI ISE (ASA): OGUN PINPIN DEETI………………………..

AKOONU:  Ogun pinpin

Ilana ogun pinpin.

Ohun ti a le pin gege bi ogun

Ona ti a n gba pin ogun.

 

 Leyin osu meta ti okunrin ba ku ni a to le pin ogun re, leyin ti obinrin ba jade opo. Nile Yoruba, egbon ki I jogun aburo afi ti koba si elomiran mo sugbon apeere ori buruku ni ki egbon o jogun aburo re.

 Ki won to pin ogun, won yoo difa tabi ki won pe awon agbagba lati jiroro laarin awon omo oku. Iru ipade bayi je ipade asiri. Won a kiyesi ohun ti awon omo naa fe ati ohun ti o le te oku lorun. Aaro kutukutu ni a maa n jokoo ni odede bale lati se eto ogun pinpin. Awon nnkan ti a n pin ni ogun ni: Aso, owo, ohun eso, ohun osin, orisa re, oko, iyawo ati gbese.

 

 

NAME………………………………………………………..CLASS………………………………

 Ona meji ni a n gba pin ogun ni ile Yoruba awon naa ni: ori – ko – ju – ori ati idi – igi – si – idigi. Ori ko – ju ori – ni pinpin ogun si iye omo oku sugbon idi si idi igi ni pinpin ogun si iye iyawo ti o bimo fun oko naa.

IGBELEWON

 1. Ko awon nnkan marun – un ti a le pin gege bi ogun nile Yoruba.
 2. Awon ona wo ni a le gba pin ogun?

IWE AKATILEWA

 1. Eko ede Yoruba titun SSS iwe keji oju iwe 76 – 79. Lati owo Oyebamiji Mustapha.

 

 

ORI ORO:- Awon ewi atenudenu to je mo esin abalaye.

AKOONU:-

 _  Ijala

 _  Iwi/Esa

_  Oya pipe

IJALA:– Sisun naa ni won maa n sun ijala, orisa ogun si ni won fi n bo.

Awon olusin ogun ni awon ode, agbe, awon alagbede ati gbogbo awon to n sise irin. Ti won ba n se odun ogun ni ijala sisun saba maa n waye. Ounje ti ogun feran ni aja, iyan, obi, esun isu ati emu. Ogun korira gbigbe ofifo agbe emu duro.

IWI/ESA;-Awon idile eleegun tabi Oje ni won maa n ki iwi tabi pe esa egungun ni akoko ti won ba n sodun egungun. Ounje egungun ni emu, Olele, obi ati agbo. Eewo ni, egungun ko gbodo subu..

OYA PIPE:- Orisa oya ni won maa n fi oya pipe bo. Pipe ni won maa n pee ni akoko odun oya. Awon olusin re ni won n pe ni oloya sugbon awon obinrin lo maa n po ju ninu won nitori oya je orisa obinrin.

IGBELEWON:-

1.  Daruko meta ninu awon ewi atenudenu to je mo esin abalaye.

2 Di awon alafo wonyi

EWI ESIN AWON TO N KEE

Sango pipe sango …………………..

Oya pipe ……………. ………………….

…………….. egungun …………………….

 1. Igba wo ni won maa n sun iyere ifa?

 

NAME………………………………………………………..CLASS……………………………………

IWE AKATILEWA

1.  Eko ede Yoruba titun iwe keji. Oju iwe 10-16 lati owo Oyebamiji Mustapha:

2.  New simplified Yoruba L1 by S.Y Adewoyin book three. Oju iwe 17-19

3.  . Eko ede ati asa Yoruba iwe keji. Oju iwe 14-18 lati owo Egbe akomolede ati asa Yoruba

ISE ASETILEWA

 1. Ohun ti a gbodo koko se ti a ba fe ko aroko ni ………..(a) yiyan ori oro (b) sise ilapa ero (d) sise ifaara
 2. Ewo lo yato ninu awon wonyi (a) alalaaye (b) apejuwe (d) itakuroso
 3. Ona melo ni awon Yoruba maa n gba pin ogun (a) meji (b) meta (d) merin
 4. Ohun ini ti oku fi sile ki o to ku ni won pe ni ………. (a) eru (b) dukia (d) ogun
 5. Iwi ni won maa n lo nibi esin ………… (a) oya (b) ogun (d) egungun

APA KEJI

 1. Ko ona ti awon Yoruba n gba pin ogun pelu alaye perete.
 2. Ko ewi alohun meta sile pelu ibi esin ti a ti maa n lo won.

 

OSE KETA

APOLA

AKOONU: – DEETI ……………………

 • Ki ni a n pe ni apola
 • Ki ni apola oro oruko
 • Ise ti apola oro oruko n se ninu gbolohun
 • Ki ni a n pe ni apola ise
 • Ise ti apola ise n se ninu gbolohun

 

Apola ni akojopo oro ti o n di apa kan gbolohun. Apola le je eyo oro kan, o si le je meji tabi ju bee lo. Orisiri apola lo maa n di apa kan tabi odidi gbolohun.

Apola oro oruko ni eyo oro oruko kan tabi meji tabi ju bee lo ti o di apa kan odindi. O si le je apapo oro oruko ati oro oruko eyan ninu gbolohun Yoruba. Apola oro oruko le je oro oruko, oro aropo oruko, tabi aropo afara joruko.

Apeere apola to je eyo oro oruko kan

Iwe

Moto

Aso

Ileke

Apola le je eyo oro oruko meji tabi ju bee lo

Oju titi

Omi ojo

 

NAME……………………………………………………….. CLASS………………………

Baba agbe

Igi oko

Awa omo baba olowo ilu yii niyi.


oko ayokele oloye ni mo ra

Apola oro oruko ati eyan

Ewu tuntun meji ni mo ra

Ile tI mo ko ga fiofio

Ise yi ma le o

Iwo gan-an lo mu owo mi

ISE TI APOLA ORO ORUKO N SE

1.  Apola oruko maa n duro gege bii oluwa ninu gbolohun. Apeere:-

 Mo je eba

 Iwo ri olopaa

 Ade pa aja

2.  Apola oro oruko tun le duro ni ipo abo ninu gbolohun. Ohun ni ohun ti oro ise maa n fi abo le lori ninu gbolohun. Apeere:-

 Ife ra fila

Tisa na omo naa

Mo pe won

3.  Apola oro oruko le duro ni ipo eyan ninu gbolohun. Apeere:-

 Ise akowe dara

Ounje Jumoke ni mo fe je

 Ere ipa ko dara

 Oro ise ni opomulero ti o n toka si isele tabi koko
inu gbolohun. Oro ise maan ko ipa Pataki ninu gbolohun ede Yoruba.

 Apeere Oro ise:-

 Mo ta oja

 

NAME………………………………………………………..  CLASS…………………………

Ade jeun

Omo naa n sunkun.

Apola oro ise le je eyo oro ise kan tabi oro ise meji tabi ju bee lo. Osi le je apapo oro ise pelu isori oro miiran ninu gbolohun Yoruba.

Apeere:-
apola eyo oro ise kan.

Anike sun

Sangba fo

Ile jo

Oko danu

Apeere Apola Oro Ise Meji Tabi Ju bee Lo.

 MO sare
lo sun

 Bola ti jise ti mo ran-an

 Tade je isu ti ko jina

 Apeere apola oro ise pelu isori oro miiran le je oro oruko, aponle, asapejuwe ati bee be lo.

 Omo pupa kekere kan n wa iya re

 Mo tete de si ipade lonii

 O sun fonfon leyin ounje ale

 ISE APOLA ORO ISE NINU GBOLOHUN

1.  Oro Ise Agbabo:- Awon oro ise kan wa ti won maa n ni oro oruko ti o tele won ninu gbolohun, iru awon oro ise bee ni a maa n pe ni oro ise agbabo. Iyen nipe won maa n ni abo ninu. Apeere:-

 Tafa ta ofa

 Jide ra keke kan

 Mo ja ijakadi

2.  Oro Ise Alaigbabo:- Eyi ni awon oro ise ti kii ni oro oruko kankan ninu to duro gege bi abo ninu gbolohun. Apeere:-

 Isu naa jina

 Agbado hu

 Tata n fo

 

NAME………………………………………………………..  CLASS……………………………

3.  Oro Ise Amugbalegbee:- Oun naa ni a mo si oro aponle. O maa n fun oro ise ni itumo kikun to si ja gaara. Apeere:-

 Mo tete de

Ade sise gidi

Alejo mi sese de

IGBELEWON

 1. KI NI apola
 2. Ki ni aplo oruko
 3. Ki ni apola ise
 4. Toka si apola oruko ni ipo oluwa nihihin

Ode pa eran

Sola ge igi

Baba wo oko ayokele

 1. Iru apola wo ni won fala si nidi yii

Tafa ta ofa

Agbado hu

IWE AKATILEWA

 1. Eko ede ati asa Yoruba iwe keji oju Iwe 8-10 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba
 2. Eko ede Yoruba tItun iwe keji oju Iwe 17-18 lati owo Oyebamiji Mustapha
 3. Eko ede ati asa Yoruba iwe keji oju iwe 20-22 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba
 4. Eko ede Yoruba tunutun iwe keji oju iwe 102-103 lati owo Oyebamiji Mustapha

LIT: ASA TO SUYO NINU AWON EWI ALOHUN ESIN ABALAYE DEETI……………….

Ijala awon ologun ni won ni ijala paapaa julo awon to n lo irin. Awon asa to suyo ninu ijala ni ijuba, oriki igi oriki eye, oriki eeyan, itu ti eeyan le pa ni oko ode.Ninu oya pipe, a le ri orin, eewo oya, ife oko.Awon eleegun ni won ni esa/iwi, awon asa ibe ni orin, ijuba,ita. Agbara sango ati iwa ati isesi re ni o maa wopo ninu ti sango. Ti a ba ti n ri awon oro bi Adia fun eyi toka si iyere ifa. Ale ri orin ati egbe ninu ese ifa, ebo riru, itan,yemiwo,emi airi, awitunwi ninu iyere ifa pelu.

 

 

NAME………………………………………………………..CLASS……………………………………

IGBELEWON

1Awon asa wo lo suyo ninu awon ewi yii

 • Iwi
 • Ijala
 • Ese ifa

IWE AKATILEWA

Eko ede ati asa Yoruba iwe keji oju iwe 54-56 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba

ISE ASETILEWA

1.  Apola oro oruko le wa ni ipo oluwa, abo ati _____(a) Ise (b) Eyan

(d) Apejuwe

2.  Oro wo ni o n sise oluwa ninu gbolohun yii “Ayo ba Tunde ja” (a) Tunde

(b) Ba (d) Ayo

3.  ______ ni opomulero gbolohun (a) Oro oruko (b) Oro ise (d) Oro aponle

4.  Isori oro wo ni a ko le ba pade ninu apola oro ise (a) Ko si (b) Oro oruko (d) oro aponle

5.  Oro ise alaigbabo maa n ni_______ (a) Ni oro ise (b) Ni oro oruko

(d) Kii ni oro oruko

OSE KERIN

 

AKORI ORO: – EYA GBOLOHUN EDE YORUBA DEETI …………………………..

AKOONU: — Gbolohun eleyo oro ise

– Gbolohun olopo oro ise

– Gbolohun alakanpo

– Gbolohun ase

– Gbolohun ibeere


Gbolohun ni ipede ti o kun. Ninu gbolohun, a maa n ri orisirisi isori oro paapaa julo oro ise gege bi opomulero gbolohun.
Orisirisi ona ni a le pin gbolohun ede Yoruba si, Awon ni: gbolohun eleyo oro ise, olopo oro ise, gbolohun alakanpo,gbolohunase, gbolohun ibeere abbl.

Gbolohun eleyo oro – ise: – Oro ise kan ni iru gbolohun bayii maa n ni, iyen ni pe ise kan soso ni iru gbolohun bee maa n je. Apeere: –

 

NAME……………………………………………………….. CLASS………………………

Moni sade je dundu

 Ojo ro lanaa

 Ade ki baba re

 Ayo se obe

Gbolohun olopo oro ise: – Gbolohun olopo oro ise maa n ni ju eyo oro ise kan lo ise to o n je maa n ju eyo kan lo Apeere: –

 Tola gba eko lo si ibadan

 Mo sun isu je

 Iyabo ru igba lo
ta ni oyingbo

 Won ji isu mi ko
lo

Gbolohun alakanpo: – Irufe gbolohun yii ni awon gbolohun ti a n lo oro asopo lati so gbolohun meji tabi ju bee lo po di gbolohun kan soso. Apeere: –

 Ade gbo amo ko dahun

 Mo fe moto amo nko lowo

 Olu wa sugbo n ko rii

 Sade lewa sugbon ko mowe

Gbolohun ase: –
Gbolohun ase ni a maa n lo ni opo igba lati je ki eni ti a n ba soro le mu ero inu wa se tabi ki eniyan se nnkan ti a fe. Apeere: –

 Dide duro

 Wa ri mi

 Lo mu abo wa

 E dake jee

Gbolohun Ibeere: – Eyi ni gbolohun ti a fi n se ibeere. Ami ibeere /?/ maa n wa ni opin gbolohun bee. Awon wunren ibeere ni nje, se, sebi, abi, ngbo, bawo, meloo, nko, Apeere:

 Ade nko?

 Se o ti tan?

 Nje awon ara ibi wa?

 Nibo lo lo?

NAME……………………………………………………….. CLASS………………………

Gbolohun ebe: – A n lo gbolohun yii lati fi bebe fun ohun kan ni.Oro bii ‘jowo’ le wa ninu gbolohun ebe nigba miiran.Bi apeere –

 1. Fun mi ni omi mu.
 2. Jowo maa bu mi mo.
 3. Ba mi toju re daadaa.

 

 

IGBELEWON: –

1.  Salaye awon gbolohun wonyi

Gbolohun alakanpo

Gbolohun olopo oro ise

Gbolohun eleyo oro ise

Gbolohun ibeere

IWE AKATILEWA

1. Eko ede ati asa Yoruba. Iwe keta oju iwe 12-13 lati owo Egbe akomolede ati asa Yoruba.  

2. New simplified Yoruba L1 book three.oju iwe 11-12] Lati owo S.Y Adewoyin.

AKORI ISE (EDE):   ERE IDARAYA DEETI…………………………

AKOONU:    Itumo ere idaraya

Bojuboju

Ekun meran

 Ere idaraya ni ere ti awon omode tabi agbalagba maa n se lati je ki ara won ji pepe. Ni ale ni igba osupa ni awon omode maa n sere ti won idi niyi ti a fi n pe ni ere osupa. Apeere iru ere bee ni bojuboju, ekun meran, booko – booko, moni ni – monini, onilede, woru oko, “Aalo apamo ati aalo apagbe.

EKUN MERAN

 Lile: Egbe:

 Ekun meran Mee

 O tori bogbo Mee

 O torun bogba Mee

 Oju Ekun n pon Mee

 Iru Ekun n le Mee

 O fe mu un o Mee

 Ko ma le mu un o  Mee

NAME………………………………………………………..CLASS………………………………………………………………

 Ekun meran Mere

BOJUBOJU

 Lile: Egba:

 Bojuboju Hee

 Oloro n bo Hee

 E paramo Hee

 Se ki n si? Si

 Sisi sisi

Eni toloro bamu yoo pa a je o

IGBELEWON

 1. Igba wo ni won maa n se ere idaraya nile Yoruba
 2. Ko orin ere idaraya meta.

IWE AKATILEWA

 1. Eko Ede ati asa Yoruba iwe kin – ni – ni SS 1 oju iwe 232 – 237 lati owo oyebamiji Mustapha

ISE ASETILEWA

 1. ________ ni gbolohun ti o maa n ni eyo oro ise kan soso. (a) eleyo oro ise (b) olopa oro ise (d) alakanpo.
 2. Gbolohun ________ ni a maa n se amulo oro asopo ninu re. (a) eleyo oro ise (b) olopo oro ise (d) alakanpo.
 3. Bade sare tete pon omi wa. Irufe gbolohun yi ni a pe ni gbolohun ________ (a) eleyo oro ise (b) olopo oro ise (d) alakanpo.
 4. ________ ni a maa n se lati je ki ara wa ji pepe. (a) ere idaraya (b) ariwo (d) ija igboro .
 5. Nigba wo ni won maa n pa aalo nile Yoruba? (a) aaro (b) osan (d) ale.

APA KEJI

 1. Fun awon gbolohun won yii ni apeere kookan
  1. Gbolohun eleyo oro ise
  2. Gbolohun olopo oro ise
  3. Gbolohun alakanpo
 2. Ko ere idaraya meji sile

 

 

OSE KARUN-UN DEETI………

GBOLOHUN IBEERE:-   Gbolohun ibeere ni gbolohun ti a fi maa n se iwadi nnkan. Wuren gbolohun ibeere ni: da, nko, n je, ta, tai ni, Bawo, se, ki Apeere.

 

Ki ni oruko re?

Iwe yen da?

 

NAME……………………………………………………….. CLASS……………………

Nje e ti gbo?

Ta ni o n bo? Ta ni o kan ilekun?

Bawo ni ara re ?

Se o ti jeun?

IGBELEWON:

 1. Ko marun sile ninu wuren ibeere
 2. Lo awon wuren ibeere naa ni gbolohun.

IWE AKATILEWA

Eko ede ati asa Yoruba. iwe keta oju iwe 18 – 21 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

 

AKORI ISE (ASA):   ASA IRANRA – ENI – LOWO.

Asa iranra – eni – lowo ni ona ti awon yoruba maa n gba ran ara won lowo tabi ki a so pe asa iranra eni – lowo ni ona ti awon Yoruba maa n gba soore fun eniyan. ona ti awon yoruba maa n gba ran ara won lowo ni: (i) Aaro (ii) Ebese (iii) Esusu


Aaro:- Awon odomokunrin ti won je bi ojo ori kan naa ni won maa n ko ara won jo lati se aaro. Won le je merin mefa tabi meje. Won a sise ninu oko enikan lonii, won yoo lo sise ninu oko elomiran lola titi ti won yoo fi sise ninu oko arawon yika. Won maa n se eleyi lati ran ara won lowo.

Ebese:- Ebese ni ise ti ko fi ko bee po pupo ti a be awon eniyan lati se fun imurasile fun inawo repete ti o n bo miwaju. Inawo pupo bi igbeyawo, oku sise oye jije ati bee bee lo.

Esusu:-  Eleyi ni I se pelu owo. won maa n da ni. Eni ti o n gba a yoo maa gba owo naa kaakiri lodo awon eniyan. Bi won ba ti n da owo yii ni won maa ko si ara igannal ogiri (wall) won o maa fa igi kookan si ara iganna igi yii ni iye ti o duro fun.

Ajo:- Ajo naa dabi esusu ni. won maa n da owo fun olori alajo. O ni iye owo ti yoo maa da bi agbara re se to. Iyato to wa laarin esusu ati ajo ni wi pe gbogbo iye ti o ba da ni o ko nibi esusu sugbon nibi ajo eeyan o ko ida kan sile fun olori alajo.

IGBELEWON

 1. Ko ona meta ti awon yoruba maa n gba ran ara won lowo.
 2. Salaye iyato laarin esusu ati ajo .

 

IWE AKATILEWA

1  Eko ede ati asa yoruba iwe kin – in – ni SSS 1 oju iwe 102 – 109. Lati owo Oyebamiji Mustapha.

2  Eko ede ati asa yoruba iwe keji JSS 2 oju iwe 136-146 Lati owo Oyebamiji Mustapha.

ISE ASETILEWA

 1. Nje je okan lara wuren gbolohun _________. (a) asopo/ alakanpo (b) eleyo oro ise (d) ibeere.
 2. Irufe gbolohun wo ni a ti maa n se iwadi nnkan? Gbolohun _______ (a) ibeere (b) alakanpo / asopo (d) eleyo oro Ise
 3. Dide duro. Je apeere gbolohun _________ (a) ibeere (b) olopo oro ise (d) ase.
 4. Ninu asa iranra enilowo ewo ni o da bi adire irana ti eniyan gbodo san pada? (a) aaro (b) ajo (d) ebese.

5  Awon odomokunrin ti won je ojo ori kan naa ni won maa n saba se _________ (a) ajo (b) aaro (d) esusu.

NAME………………………………………………………..CLASS……………………………………………………………

APA KEJI

 1. Lo awon wuren yii ni gbolohun
  1. Bawo
  2. Se
 2. Ko ona meta ti a n gba se iranra eni – lowo nile Yoruba.

 

OSE KEFA

 

AKORI ISE (EDE):  AROKO ALARIYANJIYAN DEETI……………………..

AKOONU:  Itumo aroko alariyanjiyan.

Apeere aroko alarinyanjiyan.

 Aroko alariyanjiyan je aroko ti a ti maa n jiyan lori nnkan kan. Ninu aroko yii alaroko gbodo maa ko si otun ati osi. Iyen ni pe alaroko gbodo maa ko aroko lori ero meji. Fun apeere aroko lori obinrin dara ninu ise ile ju okunrin lo. Ti a ba fe ko aroko bayi, a gbodo ko lori idi ti obinrin fi dara ninu ise ile bakan naa ni a gbodo ko lori pe okunrin naa dara ninu ise ile. A o ko aroko yii ti eni ti o n ka aroko naa o ni mo ero wa denudenu. Ayafi ti o ba kaa de igunle /ipari aroko naa.

 Apeere aroko alariyanjiyan

 1. Omo ju owo lo
 2. Ohun ti okunmi le se obinrin ko le se
 3. Ise oluko wulo/ dara ju ise Dokita lo
 4. Ede abinibi dara ju ede geesi lo
 5. Baba wulo ju iya lo

Omo ju owo

Ifaara: Itumo omo ati owo

Egbe kin – in – ni

 1. Awon iwulo omo leseese
 2. Awon ohun ti omo lese ti owo ko le se

Egbe keji

 1. Iwulo owo ati aleebu owo
 2. Awon ohun ti owo lese ti omo ko le se

Ikadi:

Ifaramo idi ti omo fi ju owo lo

IGBELEWON

 1. Ko ilapa ero lori ” ohun ti okunrin le se obinrin o le se

IWE AKATILEWA

1  Eko ede ati asa Yoruba iwe kin – in – ni SSS 1 lati owo Oyebamiji Mustapha Oju iwe 149 – 154

 

 

 

AKORI ISE (ASA):   OGE SISE. DEETI……………

Oge sise ni ona ti awon Yoruba maa n gba se ara won loso. Eni ti kii ba se ara re loso ni won n pe ni obun. Ki a we, ki a fo eyin/ enu, ki a ge eekana, ki a ge irun, ki a fo aso oge sise bere lati ibi won yii. A maa n se eyi lati bu kun ewa ati lati dena arun ni won fi maa n so pe imototo bori arun mole.

Ona ti a n gba se ara loge ni: (i) Iwe wiwe (ii) Arajija (iii) Osun kikun (iv) Ese tito (v) Tiroo lile (vi) Laali lile: Apeere

Iwe wiwe

Ara jija

NAME……………………………………………………….. CLASS………………………

 

Osun. Kikun

Ese tito

 

Tiroo lile

Ara jija

Laali lile

Eti lilu

Ara finfin

Ila omo

Ileke lilo

IGBELEWON

 1. ko ona marun ti a n gba se ara loge sile
 2. ko meta sile ninu awon aso okunrin nile Yoruba

IWE AKATILEWA

 1. Eko ede Yoruba titun iwe kin – in – ni (SS 1) Oju iwe 87 – 97 lati owo Oyebamji Mustapha
 2. Eko ede Yoruba titun iwe keji oju iwe 153-170 lati owo Oyebamji Mustapha

ISE ASETILEWA

 1. _________ ni aroko ti a fi maa n jiyan lori nnkankan. (a) alariyanjiyan (b) oniroyin (d) asapejuwe (e) oniroyin.
 2. Okunrin wulo ju obinrin lo. Je mo aroko _________ (a) alariyanjiyan (b) oniroyin (d) asapejuwe (e) alalaye.
 3. Idakeji imoto ni __________ (a) afinju (b) obun (d) abuke (e) onijongbon.
 4. Awon ___________ lo maa n wo kenbe (a) eni giga (b) eniyan dudu (d) okunrin (e) obinrin.
 5. Awon wo lo maa n kun osun? (a) eni giga (b) eniyan dudu (d) okunrin (e) obinri

APA KEJI

 1. Salaye itumo aroko alariyanjiyan.
 2. Ko ona merin ti a le gba se ara loge mile Yoruba.

 

OSE KEJE DEETI………………………..

IBASEPO LAARIN AWE GBOLOHUN ATI ODINDI GBOLOHUN

Gbolohun ni ipede ti o kun pelu ituno nigba ti awe gbolohun je apa kan odindi gbolhun Ara odindi gbolhun ni a ti fa awe gbolohun yo. Awe gbolohun pin si ona meji. Olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe

Gbolohun ni ipede ti o kun ti o si loorin. Ero ati itumo gbolohun maa n kun Fun apeere

 Mo gbo pe o ti wa mi wale

Apa kan odindi gbolohun ni awe gbolohun. Fun apeere:

 Mo gbo pe o ti wa mi wale Eyi ti a fala si nidi ni a pe ni awe gbolohun afarahe. Nitori naa a maa n fa awe gbolohun yo ninu odindi gbolohun.

Nigba miiran, awe gbolohun le da duro bi odindi gbolohn. Ti o ba ri bayi olori awe gbolhun ni a n toka si. Fun apeere.

Mo sa lenu ise nitori pe o re mi

Mo ra ile ti o tobi

Awon oro ti won fa ila si nidi le da duro pelu itumo kikun. Ibasepo miiran laarin awe gbolohun ati gbolohun odindi ni pe awe gbolohun maa n wa ni ipo abo paapaa julo awe gbolohun afarahe asodoruko

Fun apeere:  

 Mo se bi oluko mi ti wi

 

NAME……………………………………………………….. CLASS…………………

 

Mo gbo pe o ti wa mi wale Ko tan sibe,awe gblohun le je eyan ninu gbolohun. Fun apeere.

Ile ti mo ko ko I pari

Ere ti e n se ti poju

Baba Tunde ti o wole gomina ti de lanaa

IGBELEWON

 1. KI ni gbolohn
 2. Ki ni awe gbolohun
 3. Ko ibasepo laarin awe gbolohun ati odindi gbolohun merin sile.

 

IWE AKATILEWA

Eko ede ati asa Yoruba iwe keta oju iwe 44-47 lati wo egbe akomolede ati asa Yoruba.

DEETI……………………..

OBATALA

Ona meji ni a le pin awon orisa ile Yora si. Awon orisa lati orun wa ati awon orisa nipa agbara . Lara awon orisa lati orun ni obatala.Awon Yoruba gbagbo pe ohun ni ipo re ga ju laarin awon orisa yoku. Oun naa ni o maa n se oju, enu, imu ati eya yoku miiran. Awon aro, amukun,abuke ati awon miiran la n pe ni Eni

Awon aborisa obatala ni awon to maa n wo aso funfun, bata funfun, funfun ni gbogbo nnkan ti won n lo. Bi awon olorisa ba ti n lo nnkan funfun yii bee naa ni won gbodo maa lo inu funfun. Odoodun ni won maa n se odun. Iyan,igbin, osiki (obe egusi), ti ko si iyo nibe. Igbin ni ilu obatala

IGBELEWON

 1. Ki ni awon nnkan ti won maa n ri ni ojubo orisaala/obatala
 2. Awon iru ounje wo ni o maa n wa nibi odun obatala
 3. Salaye irisi aborisa obatala
 4. Igbagbo wo ni o ro mo irisi yii.

IWE AKATILEWA

 1. Awon asa ati orisa ile Yoruba oju iwe 242-245 lati owo Olu Daramola.
 2. Eko ede Yoruba titun iwe keji J S S 2 oju iwe 205-209 lati owo Oyebamji Mustapha

ISE ASETILEWA

 1. Oro ise melo ni a le ba ninu gbolohun eleyo oro ise (a) meji (b) meta (d) okan (e) mefa
 2. Bi awe gbolohun ba da duro bi odindi gbolohun, a je pe (a) olori awe gbolohun ni (b) awe gbolohun afarahe ni (d) awe gbolohunasodoruko ni (e) awe gbolohun asaponle.
 3. Mo fe ri o bi mo ba de. Iru gbolohun ni wo ni a fala si nidi yii (a) olori awe gbolohun (b) odindi gbolohun (d) awe gbolohun afarahe (e) awe gbolohun afarahe assaponle
 4. Orisa wo ni awon Yoruba gba pe o se oju, imu, enu (a) sango (b) ogun (d) esu (e) obatala
 5. Omi ti won maa n lo ni ojubo orisaala ni won maa n pe ni ……… (a) omi tutu (b) omi gbigbona (d) omi orisa (e) omi ajifowuropon

APA KEJI

 1. (a) ko iyato meji laarin awe gbolohun ati odindi gbolohun
  1. ko ijora kan laarin awe gbolohun ati odindi gbolohun
 2. salaye perete lori obatala.

 

 

 

 

OSE KEJO

AKORI ISE: – Eya awe gbolohun Yoruba DEETI………………………….

AKOONU: –

 • Olori awe gbolohun
 • Awe gbolohun afara he

 

 

NAME………………………………………………………..  CLASS…………………………

 

Gbolohun Yoruba to kun maa n ni itumo kan, o si maa n ni ise kan pato to n je. Ohun ti a mo si awe gbolohun ni tire je apa kan odidi gbolohun. Ara odidi gbolohun ni a ti fa awe gbolohun yo. Orisi awe gbolohun meji Pataki ni a le fa yo ninu ihun gbolohun . Yoruba awon olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe.

1.  OLORI AWE GBOLOHUN

 Oun ni abala gbolohun to le da duro funra re ki o si in itumo ti a ba yo afi kun re kuro. Apeere.

 Mo ti lo ki ore mi to de

Gbogbo ilu gbo pe oba ti waja

 Ode wa mu oti yo ni oru ana

2.  AWE GBOLOHUN AFARAHE

Eyi ni apa keji odidi gbolohun ti ko le da duro funra re,o fi ara he olori awe gbolohun ni Apeere: –

 Ode wa mu oti yo ni oru ana

 Gbogbo ilu gbo pe oba ti waja

Mo ti lo ki ore mi to de

IGBELEWON

1.  KI ni a npe ni awe gbolohun

2.  Iyato wo lo wa laarin olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe

3.  Ona meloo ni ale pin gbolohun afarahe pin si, daruko won.

4  Fa ila si idi olori awe gbolohun ninu awon gbolohun wonyi

Gbogbo ilu gbo pe oba waja

Mo ti lo ki ore mi to de

Ade nkorin bi eye tintin

IWE AKATILEWA

1.  New simplified Yoruba L1 by S.Y Adewonyin book three. Oju iwe 15-16. Ka nipa

 eya awe gbolohun ede Yoruba.

2  .Egbe akomolede ati asa Yoruba. Eko ede ati asa Yoruba. Iwe keta. Oju iwe 25-

26, 40-41.


DEETI………………..

OGUN

Ijala ni ewi atenudenu ogun. Ogun ni awon Yoruba gbagbo pe o ni irin oun ni won fi maa n pe ni alada meji o fi okan sanko o fi okan yena. Gege bi igbagbo awon Yoruba awon ode,agbe, alagbede gbogbo eni

 

NAME……………………………………………………….. CLASS…………………

 

to ba ti n lo irin ni won gba pe o je olusin ogun. Ounje ti ogun feran ni aja, iyan, obi, esun isu ati emu..Ogun korira gbigbe ofifo agbe emu duro. Die lara ijala ewi alohun/atenudenu ni:

 Ogu lakaaye, osin mole

 Ogun alada meji

 O fi okan san oko

 O fi okan yena

 Ogun onile kangunkangun orun

 O pon omi sile feje we

 O laso nile fimokimo bora

 Ogun meje logun mi

 Ogun alara ni n gbaja

 Ogun onire a gbagbo

 Ogun ikola a gbagbin

 Ogun elemona ni I gba esun isu

 Ogun akirun a gba iwo agbo

 Ogun gbengben eran awun ni I je ……….

IGBELEWON

 1. Awon ounje wo ni ogun feran
 2. Ki ni nnkan ti ogun korira
 3. Ogun alada meji. Salaye

IWE AKATILEWA

Eko ede ati asa Yoruba iwe keji oju iwe 14-19 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba

ISE ASETILEWA

 1. Orisi melo ni awe gbolohun pin si (a) meji (b) meta (d) merin (e) marun-un
 2. Oluko gba pe ise yi dara gbolohun ti a fala si nidi je …….. (a) awe gbolohun afarahe (b) olori awe gbolohun (d) oddidi gbolohum (e) asaponle
 3. Iru gbolohun awe gbolohun wo ni o le sise bi odindi gbolohun (a) olori awe gbolohun (b) awe gbolohun afarahe (d) awe gbolohun asaponle (e) odindi gbolohun
 4. …… je orisa ti o lagbara lori irin (a) ogun (b) obatala (d) oranmiyan (e) oduduwa
 5. Nibo ni ojubo ogun (a) orita (b) aarin oko (d) inu ile (d) oju ona

APA KEJI

1 Salaye olori awe gbolohun

awe gbolohun afarahe

 1. salaye perete lori ogun.

 

 

OSE KESAN-AN

EYA AWE GBOLOHUN DEETI…………………..

Gege bi a so saaju pe awe gbolohun pin si meji: olori awe gbolohun ati awe gbolohun afahe.

1 OLORI AWE GBOLOHUN Olori awe gbolohun ni gbolohun to le da duro pelu itumo.Fun apeere.

 Bola jeun ni ori tabili

 Sade ra aso ti ko ni iho lara

 Ojo gbodo jeun ki o to lo oogun re. Gbogbo awon ti a fala si nidi yii ni a pe ni olori awe gbolohun. Sade ra aso, Bola jeun, Ojo gbodo jeun.awon wonyi ni itumo ju ni ori tabili,ti ko ni iho lara,ki o to lo oogun.

2.  AWE GBOLOHUN AFARAHE

Eyi ni apa keji odidi gbolohun ti ko le da duro funra re,o fi ara he olori awe gbolohun ni Apeere: –

Ode wa mu oti yo ni oru ana

 

NAME………………………………………………………..  CLASS…………………………

 Gbogbo ilu gbo pe oba ti waja

  Mo ti lo ki ore mi to de

IGBELEWON

 1. Iyato wo lo wa laarin olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe
 2. Fa ila si idi awe gbolohun afarahe ninu awon gbolohun wonyi

a  Inu mi dun pe n ko subu

b  Bade n korin bi eye

d  Oga so pe ki a tete de

e  Oga olopaa de ni oru ana

IWE AKATILEWA

1.  New simplified Yoruba L1 by S.Y Adewonyin book three. Oju iwe 15-16. Ka nipa

 eya awe gbolohun ede Yoruba.

 1. . Eko ede ati asa Yoruba. Iwe keta. Oju iwe 25- 26, 40-41 lati owo Egbe akomolede ati asa Yoruba.

 

AKORI ISE: – Sango Pipe  

AKOONU: –   DEETI……………………

*  Ohun ti oro inu re da le lori

*  Agbara Sango

*  Awon aya Sango

*  Eewo Sango

 NOOTI

 Sango olukoso oko oya

 Oloju orogbo, elereke obi

 Ina loju, ina lenu

 Ajagajigi, ewelere ajija

 Ayan ran ina

 Ina gori ile feju

 Iku tii pa ni tenikan o le mu

 Sango ma ba mi ja

 N o lowo ebo ni le

 

NAME……………………………………………………….. CLASS…………………

 

 Ibinu olukoso o see so

 Ija re gan-an oran

 A fose yo ni loju

 A fedun yo fun

 A feefin se ni ni pele

 A fina fahun bi o soro

 O benikan ja fowo gun gbogbo ile loju

 Oro gon oparun jokoo

 Ako olongo ti n wewu ododo

Sango je okan lara awon oba to ti je ni Oyo ile laye atijo gege bi oba, sango ni agbara, oogun ati igboya, ina si maa n jade lenu re bulabula to ba n soro, Nigbati ilu dite mo nitori asilo agbara re lo lo pokun so nidi igi ayan ni ibi ti won n pe ni koso.

 Oriki sango lo maa n poju ninu sango pipe won maa nlo lati yin-in lati dupe lowo re bi oba se won lore ati lati be e fun idaabobo, bibo asiri won ati lati beere fun awon nnkan ti won se alainu. Awon nnkan ti sango n lo gege bi agbara ni ose sango, edun ara ati ina to maa n yo lenu re.

 Iyawo meta ni sango ni nigba aye re, oya, osun ati oba, oya wole ni Ira o si di odo ti a mo si odo oya di oni olori. Sango korira siga mimu, obi, ewa ati eku ago jije.

IGBELEWON

1.  Ki ni awon oro inu sango pipe maa n da le lori

2.  Awon nnkan wo ni sango maa ri fi se agbara

3.  Iyawo meloo ni sango ni, Daruko won

4.  Ki ni awon nnkan to je eewo fun sango

IWE AKATILEWA

1.  Now simplied Yoruba L1 and S.U Ade wonyi book three oju iwe 43 – 44, Ka nipa Sango pipe.

2.  Eko ede Yoruba titun. Iwe keji oju iwe 11, 12 lati owo Oyebanji Mustapha

3.  Eko ede ati asa Yoruba. Iwe keta oju iwe 22- 23 lati owo Egbe akomolede ati asa Yoruba.

 

 

NAME……………………………………………………….. CLASS…………………

 

ISE AMURELE

1.  _______ ni apa kan odidi gbolohun. (a) Awe gbolohun (b) Gbolohun ede Yoruba (d) Odidi gbolohun (e) Eyo oro kan

2.  Ara ______ ni a ti fa awe gbolohun yo (a) Gbolohun afarahe (b) Odidi gbolohun (d) Olori awe gbolohun (e) Gbolohun asaponle

3.  Orisii awe gbolohun ______ ni o wa (a) Merin (b) Meta (d) meji (e) Mefa

4.  ____ lo wole ni Ira (a) Oya (b) Osun (d) Oba (e) Sango

5.  Okan ninu agbara sango ni _____ (a) Edu ara (b) Ijakadi (d) Omi [e] ado.

 

 

OSE KEWAA

ORISIi EYA AWE GBOLOHUN AFARAHE ASAPONLE DEEETI…………………..

(a)  Awe gbolohun afarahe asaponle alafiwe gbolohun yii maa n se afiwe nnkan meji wunren “bi” tabi “bi” ni atoka re

Ade nkorin bi eye se nkorin

Omo naa kigbe bi eni ti agbon ta

(b)  Awe gbolohun afarahe asaponle alasiko eyi maa n toka asiko ti nnkan sele ninu gbolohun tabi igba. Apeere: –

Baba maa wa nigba ti o ba de

Mo ri tade ni ale ana

Bo se n bo lati ile lo ti raa dani

(d)  Awe gbolohun afarahe asaponle onibi: –

 A maa n fi eleyi toka ibi ti isele inu gbolohun ti waye. Apeere:

Mo ba ore mi nibi ti o ti n mu oti

To mi pade okore ni ile ijo ti o lo

Oluko gba mi ni ori

(e)  Awe gbolohun afarahe asaponle onidii abajo: – eyi ni a fi maa nsalaye okunfa isele kan ninu gbolohun. Apeere

Mo n jiya nitori ki n le joro

Baba tete jii ko le sin ore re de idiko

 

NAME………………………………………………………..  CLASS……………………

Akeko naa tera mose ko le gbebun

(e)  Awe gbolohun afarahe asaponle onikan: – eyi maa n so ohun ti iba sele bi nnkan miran ba sele saaju ninu gbolohun Apeere: –

Nba tele yin lo, kani mo tete ji

Kani mojisola wa ni, oju iba tii

N ba ra moto kani mo lowo

(f)  Awe gbolohun afarahe asaponle oniba irufe gbolohun yii maa n so iru ona ti nnkan gba sele ninu gbolohun. Apeere:- Ojo naa ro bi eni pe ile yoo ru

 Ounje yii dun bi eni pe ki n ma siwo

 Oluko na akekoo naa ni ana daju bole

IGBELEWON

1.  KI ni a npe ni awe gbolohun

2.  Iyato wo lo wa laarin olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe

3.  Ona meloo ni ale pin gbolohun afarahe pin si, daruko won.

4.  Ona meloo ni awe gbolohun afarahe asaponle pin si, da

IWE AKATIELWA

1.  New simplied Yoruba L1 and S.U Ade wonyi book three oju iwe 43 – 44, Ka nipa Sango pipe.

2.  Eko ede Yoruba titun. Iwe keji oju iwe 11, 12 lati owo Oyebanji Mustapha

3.  Eko ede ati asa Yoruba. Iwe keta oju iwe 22- 23 lati owo Egbe akomolede ati asa Yoruba.

ISE ASETILEWA

 1. Mo ri e ni oru ana ni oru ana je awe gbolohun afarahe ……… (asaponle(b) asapejuwe (d) asodoruko (e) alasiko
 2. Iwe ti ra mo ti faya ti mo ra je awe gbolohun aafarahe …… (a) asaponle (b) asapejuwe (d) asodoruko (e) alasiko
 3. Apeere awe gbolohun afarahe asodoruko ni (a) O yo bi ojo (b) Nba wa ka ni e wi fun mi (d) Pe mo de dun mo won (e) Ile ti mo ko ga
 4. Nba wa ka ni e wi fun mi ka ni e wi fun mi je apeere awe gbolohum afarahe… (a) asodoruko (b) onikani (d) asapejuwe (e) alasiko
 5. Olori awe gbolohun ni wonyi AYAFI (a) Ode pa etu (b) Ojo ro (d) ni abule oja (e) Bola ra aso.

APA KEJI

Salaye:

 1. Awe gbolohun afarahe alasiko
 2. Awe gbolohun afarahe asapejuwe
 3. Awe gbolohun afarahe asaponle
 4. Awe gbolohun afarahe asaponle onibi
 5. Awe gbolohun afarahe onikani.


 
Share this:


EcoleBooks | 1ST TERM JSS3 YORUBA Scheme of Work and Note

subscriber

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Accept Our Privacy Terms.*