SAA KETA
1 Ede Leta kiko- leta gbefe
Asa Awon owe ile Yoruba.
Lit Kika iwe litireso apileko ti ijoba yan
2 Ede Aayan ogbufo.
Asa itesiwaju lori awon owe ile Yoruba
Lit Kika iwe litireso apileko ti ijoba yan
3 Ede Aayan ogbufo.
Asa Awon akanlo ede Yoruba
Lit Kika iwe litireso apileko ti ijoba yan.
4 Ede Atunyewo iseda oro oruko- lilo afomo, apetunpe.
Asa Awon akanlo ede Yoruba.
Lit Kika iwe litireso apileko ti ijoba yan.
5 Ede: Atunyewo leta kiko.
Asa ipa tie sin ko ninu asa abinibi Yoruba
Lit Kika iwe litireso apileko ti ijoba yan.
- Ayewo finifini lori iseodun 1-3 lori ede, asa, ati litieso.
IWE ITOKASI
1 Èkó èdè àti àsà Yorùbá ìwé kìn-ín-ní lati owó egbé akómolédè àti àsà Yorùbá.
2 New simplified Yorùbá ìwé kìn-ín-ní [J S S 1 ] lati owó S. Y Adéwoyin
3 Èkó èdè Yorùbá titun(2009) lati owó Oyèbámjí Mustapha.
OSE KIN-IN-NI
AKOONU: Leta gbefe
Leta aigbefe
Adireesi
Deeti
Ikini ibere
Koko oro
Asokagba
Ikini ipari
Leta kiko ni ona ti a n gba ranse asiri si ara eni. Oun ni o duro fun aroko pipa ranse lode oni. A maa n ni anfaani lati fi ero eni han si ore, obi ibatan wa, ijoba, oga ile ise kan awon oniweroyin, ajo kan ati bee bee lo ninu leta kiko. Orisi meji ni leta pin si:
- Leta Gbefe
- Leta Aigbefe
Leta gbefe: leta gbefe ni leta si obi, ore, ibatan ati awon miiran ti o sun moni.
Leta aigbefe: leta aigbefe ni leta iwase, ifisun,igbaaye lenu ise tabi leta ti a n maa n ko si eni ti o wa ni ipo owo.
Igbese Kiko Leta Gbefe
- kiko adiresi akoleta
- kiko deeti (ojo, osu ati odun ti a ko leta)
- Ikini ibere leta
- Ipari ati oruko akoleta
Adiresi
3, Opopona Olowu,
Ibudo Adeyanka,
` Adugbo Abule Egba,
Eko.
Leta kiko ni ona ti a n gba ranse asiri si ara eni. Oun ni o duro fun aroko pipa ranse lode oni. A maa n fi ero ara eni han ninu iru leta (aroko) yii. Leta yii pin si orisii meji awon naa ni: leta gbefe ati leta aigbefe. Leta gbefe ni leta si obi,ore, ibatan ati awon miiran ti o sun moni.
Kiko adireesi: oke apa otun ni a maa n ko adireesi eni ti o n ko leta si. Adireesi yii le toka si nomba, adugbo,opopona, ipinle. Fun apeere:
3, Opopona Olowu,
Adugbo Bodija,
Ilu Ibadan.
Kiko deeti: leyin ti a ba ko leta tan, a o ko deeti ojo, osu ati odun ti a ko leta. Fun apeere: 22 : 3 : 2011. tabi 22 Erena, 2007.
Ikini ibere: apa owo osi lori ila ti o tele deeti ni a maa n ko eyi si. Fun apeere:
Omo mi owon, Omo mi tooto, Iya mi atata, Ore mi owon, Egbon mi tooto, Tunji mi atata,.
Koko oro: nibi ni a ti maa n ko ohun ti o mu wa ko leta gan-an. Ona meta ni abala yii pin si. Awon naa ni: ifaara (introduction) aarin (body of the leta) igunle (conclution). Ninu ifaara ni a ti maa ko idi ti a fi ko leta lerefe tabi ni soki, inu aarin leta ni a ti maa n se alaye lekunrere fun eni ti a ko leta si nigba ti igunle maa je ibi ti a ti maa se igunle leta wa. Ni ala yii,a le ki eniyan nibe.
Ipari ati oruko akoleta: apa owo osi ni isale ni eyi maa n wa.
Emi ni omo yin,
Babatunde.
Baba re,
Adewuyi.
Ore re,
Folake.
IGBELWON
- ko adireesi ile iwe re sile.
- Se alaye perete lori koko oro leta.
IWE AKATILEWA
Oyebamji Mustapha (2005)Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (S.S .S.1) oju iwe 16- 21 University Press Plc.
AWON OWE ILE YORUBA
Oro ti o fi ijinle ogbon awon agba atijo han nipa ohunkohun ti won ti ni iriri nipa re ni a n pe ni owe. Ohun ti awon agba ba se akiyesi pe o maa n je otito nigba gbogbo ni awon owe maa n dale lori. Fun apeere: a se akiyesi awon ohun ti Olorun da ni osupa ati irawo, a si kiyesi pe ko si irawo to mole to osupa ni won fi wi pe ko si irawo to mole to osupa. Won kiyesi pe bakana ni obinrin n loyun, eyi lo bi owe ibi ko ju ibi, bi a se beru la bomo. ti a ba woo daadaa a o ri wi pe ti a ko ba sunmo eniyan a o le mo iwa onitohun daadaa ni won fi n wi pe: sunmo eni la a mose eni, eniyan gbokeere niyi. Nisisiyii, e je ki a wo die lara awon owe ile Yoruba.
Owe to je mo iwa ati ise eda eniyan.
- Omo ti a fi ise wo ni I dagba, omo ti a fi oju ojo bi, ko to gege.
- Bi aisan ba n se iwofa, won a ni alakori gbe ise re de bi o ba se omo olowo won a ni ni ko roju fata senu.
- Bi aya ba mo oju oko tan, alarina a yeba.
- Eni rora peera , yoo ri ifun re
- Woso de mi ko le da bi oniso, n se bi iya ko le jo iya to bi ni
Owe to je mo ise agbe tabi ohun ogbin.
- Ila ki I ga ju onire lo.
- A ki I gbin alubosa ko hu efo.
- Egbe eni la gun iyan ewura de.
- Iti ogede ko to ohun a yo ada si.
- A n soro elegede, obinrin n da sii: a ni ko pa enu mo, bi a ba ko elegede jo, tanni yoo se?
Owe to je mo ise ode tabi eranko (eye ati
orisii nnkan miiran ti agbe n ri ninu oko.
- Okere n sunku agbada, eyi ti ajao da lesin-in nko, ki lo fi se?
- Kini kan lo ba ajao je, apa re gun ju itan lo.
- Mo ti fo eyi, mo ti fo tohun ni I mu ologbo ko sinu epo gbigbona
- Ode iba ro ise ko ro ro iya, ode ki ba peran , ki ba ti fun enikan je.
- Awodi oke ko mo pe ara ile n wo ohun
- Obo n je ogede, obo n yun idi, obo ko mo pe ohun to dun ni I pa ni.
Owe to je mo owo sise
- Kin ni iya laso n ta toyo egba dani, abi ewure n je leesi ni?
- Gba were, n o gba were ni oja se n ho.
- Ona kan ko woja.
- Eni ta n ba na oja ni a n wo, a ki I wo ariwo oja
- Ategun n daamu ologi, ki elelubo ma jafara
- Ojo n ku onigbure n palemo, ki ni ki elelubo se?
- Oja ki I kun titi, ki a ma mo ori eni.
IGBELEWON
Ko owe mejimeji ti o jemo:
- Iwa eda
- Ise agbe
- Ise ode
- Owo sise sile.
IWE AKATILEWA
Oyebamjji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba iwe keta (J.S.S.3) oju iwe 94-97 University Press Plc.
ISE ASETILEWA
- Leta …….ni leta iwase. (a) ore (b) gbefe (d) alaigbefe.
- Ibi ti adireesi eni ti a n ko leta si maa n wa ni….. (a) isale leta patapata ni apa osi (b) oke leta ni apa otun (d) oke leta ni apa osi
- Adireesi eni ti n ko leta maa n wa ni ….. (a) isale leta ni apa otum (b) oke leta ni apa osi (d) oke leta ni apa otun.
- Ohun ti a le pe ni owe ni…………… (a) oro repete (b) iriri edda (d) oro geere (e) oro soki.
- Pari owe yii pelu okan ninu oro wonyi: gba were, n ko gba were ni oja se n …………. (a) kun (b) tu (d) ho (e) wu
APA KEJI
- Ko ilapa ero lori leta yii: aroko si ijoba ibile re lori idagbasoke agbegbe yin.
- Pa owe ile Yoruba meta sile.
OSE KEJI
AAYAN OGBUFO
Itumo ni I se pelu titumo ede si omiran. Ni orile-ede ti awon eya won je oniruuru, ti eya kan ko si gbo ede keji, itumo ede se Pataki. Igbora eni ye yoo wa, katakara yoo lo deede. Aayan ogbifo ni titumo ede kan si omiran. Eleyi je mo oro siso lenu. Iru eleyi maa n waye ninu soosi ti a ti ri oniwaasu ati ogbifo. E je ki a wo die lara awon ede geesi si ede Yoruba ni:
Abdomen ikun
Acculturation ifaramole
Adjective oro apejuwe
Analog akawe
Beginning ibere
Communication ibanisoro
Example apeere
Joke apara.
ITUMO OWE
Ilera loro health is wealth
Ba o ku ise o se tan when there is life , there is hope.
Oro to ba gba aaro a ki I so lale there is time for everything.
Kiko ni mimo practice makes perfect.
Ile ni a ti n ko eso rode charity begins at home.
Ina esisi ki I joni leemeji once bitten twice shy.
IGBELEWON
Tumo awon oro wonyi:
- Charity begins at home
- Health is wealth.
- Hospitality.
- Make hay why the shine
- Example.
IWE AKATILEWA
OWE ILE YORUBA
Owe Yoruba po suabada. O po de ibi wi pe o fe ma ni iye. Kaka ki o mo niwon n se lo n po si lojoojumo. Iwulo owe ile Yoruba po. Omo Yoruba gbodo gbo owe to yanranti ti ki I se adamondi owe. E je ki a se ayewo die lara owe ile Yoruba.
Owe ti a fi maa n kan saara si eniyan.
- Omo ajanaku ki I ya ira, omo ti erin bi erin yoo jo.
- Ironu ikooko ni yoo pa aja.
- Awodi oke so olowo adiye di asiwere
- Kikere labere kere ki I se mimi fun adiye.
Owe ti a n fi gba eniyan ni imoran.
- Agba ti ko binu ni lomo re po
- Agba to ni suuru, ohun gbogbo loni
- Agba ti ko mo iwon ara re lodo n gbe lo.
Owe ti o n fi didara ifowosowopo han
- Ka fi owo we owo ni owo se mo
- Ogbon ologbon ko n je ka pe agba ni were
- Kokunrin rejo, kobinrin pa a, ani ki ejo sa ti ma lo.
Owe ti a fi n bu ate lu imele ati ole.
- Orisa ti I gbe ole ko si apa eni ni n gbe ni nija
- Orisa ki I gba meji lowo imele, bi o ba gba apa, a si fun ni enu.
- Agbatan laa gbole bi a da aso fun ole, a pa a laro. Bi a la a nija, a sin-in dele.
Owe to n fi han pe ko da ki a maa fi oju oloore gungi
- Eni ti a se loore ti ko dupe dabi olosa ko eru eni lo.
- Eni to ya ebgefa ti ko san lo begi dina egbeje
- Eni ti ko san gbese ogofa, ko ni ri okoo ya.
IGBELEWON
- Kin ni itumo: health is wealth
When there is life, there is hope
Pa/ko owe marun-un sile.
IWE AKATILEWA
Oyeamjji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba iwe keta (J.S.S.3) oju iwe 103-110 University Press Plc.
ISE ASETILEWA
- Asa Yoruba ko se pare fun awon Oyinbo nitori pe Yoruba je ede………….(a) to gba iyi (b) to dun pupo (d) to n dagba.
- Omode gbon agba gbon lafi da ile ife. Owe yii je apeere………..(a) ifowosowopo (b) agbara (d) ibawi (e) suuru.
- Owe: agba ti ko mo iwon ara rre lodo gbe lo je apeere………… (a) eebu (b) imoran (d) irisi (e) ibawi.
- Awon oro ti itumo won farasin ni………… (a) owe (b) akanlo ede (d) orin (e) oro
APA KEJI
Tumo awon oro wonyi:
- Democracy.
- Health is wealth.
- Hospitality.
Pari awon owe yii
- Opo oro ko kun agbon………
- Gbe omo wa ki ni…………..
- Adiye n joka, o n mu omi………….
- Agbatan la a gbole……………..
OSE KETA
AAYAN OGBUFO
ITUMO AYOKA ELEWI
Bi ibanuje ba de,
Diju, ma se fun laaye
Opo lo n ku laitojo
Won gba ibanuje laaye ni
Bi idaamu ba de.
Mura, mase fun laaye
Iji idaamu lagbara
Sugbon ko le gbe o mi
Bi ohun ayo ba de
Sora, mase yo ayoju
Ayoju lo n pa akere
Ayo abara bintin
DON’T GIVE IT A CHANCE
When sorrow comes,
Try not to give it a chance,
Many have died an untimely death
Because hthey gave sorrow a chance
When trouble comes
Try not to give it a chance
The storm of trouble may be strong
But it can not swallow you
When something joyous happens
Take caution as you rejoice
The frog was killed by lack of caution
Joy is a fragile thing.
ITUMO AYOKA OLORO GEERE
I got to village at about seven p.m the journey was a very long and tasking one because I had to trek for sixteen kilometres along a very thick forest.
Initially, I had thouth that it would not take time to get my destination and I assured myself of a safe journey to the village but before long, the load had on my head became very heavy load. The thick forest I had to walk through was equally a great threat because of the fear of wild animals.
Inside the bush, I saw various animals like rats, squirrels, monkeys, big rats, and hares. They were all darting in search of prey. I saw some birds as well. While some flying, others were singing in there nest, some of the birds I saw were bats, owls and hawks. I saw reptiles like snake and lizards.
To my delight, I reached my destination safely despite all the hazards I went through.
ITUMO
Ni nnkan bi aago meje ale ni mo de abule naa. Irin-ajo naa gun, o si gbomi mu nitori kilomita merindinlogun ni mo rin laarin igbo kijikiji.
Ni ibere irin-ajo naa, mo ro pe n ko ni pe de abule naa. Mo si n ki ara mi laya pe irin-ajo naa yoo lo daadaa. Sugbon laipe, eru ti mo ru bere si wo mi lorun. Irora mi wa di meji ti eru ati ti ona to jin. Igbo kijikiji ti n o la koja tun je ipaya fun mi nitori eru awon eranko buburu.
Oniruuru eranko ni mo ri ninu igbo naa bi eku, okere, obo, okete, ati emo. Gbogbo won sare kaakiri lati wa ohun ti won o je.
Mo ri awon eye naa pelu. Awon kan n fo, awon kan si n korin ninu ite won. Die lara awon eye ti mo ri ni adan, owiwi ati asa. Mo tun ri awon eranko afaya fa bi ejo ati alangba.
O je ohun ayo fun mi pe, pelu gbogbo isoro yii ti mo daya ko wonyi, sibe, mo de ibi ti mo n lo pelu alaafia.
AKANLO EDE
Akanlo ede ni awon ipede ti itumo won farasin. Won ki I ni itumo lerefee. Fun apeere: ti a ba so pe “eja n bakan” ti eniyan ba dahun pe “akan” iyen ni pe o dara. Itumo eja ni pe ko dara. E je ki a wo awon apeere miiran ti o je akanlo ede.
AKANLO EDE ITUMO
Iyawo su sile iyawo bimo sile
Fabara kekere gba nla fi iya je ara eni
Ta lolobo sofofo fun eniyan
Teri gbaso ku
Oba waja oba ku
Fi aake kori ko jale
Reju sun
Fese fe e salo
Kan oju abe niko so okodoro oro
Iseju akan kiakia.
Je iyan nisu gba ijiya ti o to
Na papa bora salo
Fi owo meweewa jeun ya apa, ma ni ajeseku
Je ori ahun daju, salailomi loju
Ya agbadado enu rerin-in
Gbe igunnu go
Ijimere re gun igi aladi o se ohun ti o ko abuku ba a.
Fori ja ile agbon bo sinu inira/ ko sinu wahala.
Ru igi oyin daran/ kan ijangbon
De oyin mo fila toju ohun oloro to le se ni lese si sakari eni.
IGBELEWON
So itumo awon akanlo ede wonyi
- Gbewiri.
- Oba waja.
- Reju.
- Fi aake kori.
- Iseju akan.
AKATILEWA
Egbe akomolede ati asa Yoruba(2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keta (J.S.S.3) oju iwe 69-71 Longman Nig Plc.
ISE ASETILEWA
- Ya agbado enu tumo si…………… (a) pa ariwo (b) rein-in (d) soro.
- ba ode pade tumo si……………… (a) lo ibi ti ariya wa (b) pade ode lona (d) se owo jeer.
- Itumo fese fe e ni ………….. (a) salo (b) fe ategun si ese (d) ki a ma fo (e) ki a fi ese fe ategun.
OSE KERIN
ISEDA ORO ORUKO
Orisii ona ni a le gba seda oro oruko. Lara won ni:
- Lilo afomo ibere
- Lilo afomo aarin
- Lilo apetunpe
- Sise akanpo-oro.
Lilo afomo-ibere
a le seda oro oruko titun nipa lilo ibere, awon wuren afomo ibere ni:
a e e e I o o
a e e I o o u.
afomo ibere oro ise oro oruko ti a seda
e se ese
o gbon ogbon
o ku oku
i je ije
ati je atije
on ka onka
oni bata onibata
ai sun aisun.
Afomo ibere oro-ise oro-ise oro oruko ti a seda
a wo ko awoko
a pe je apeje
ai gba gbo aigbagbo
afomo ibere oro-ise oro-oruko oro oruko ti a seda
i gba ile igbale
ati ko ile atikole
a ko ope akope
lilo apetunpe
oro-ise apetunpe oro oruko ti a seda
so soso siso
gbe gbegbe gbigbe
pe pepe pipe
oro-ise oro-oruko oro oruko ti a seda
ja ogun jagunjagun
wo ile wolewole
gbe omo gbomogbomo
ko orin korinkorin
pa ina panapana.
IGBELEWON
Fa ila si iidi oro ti a seda ninu awon oro wonyi
- Ayo ni o se iku pa a
- Wolewole gbe oku okunrin naa
- Adajo ran odaran naa lo sewon.
IWE AKATILEWA
Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba iwe keta (J.S.S.3) oju iwe 4-10 University Press Plc.
AKANLO EDE
Akanlo ede je okan ninu awon ona ede ti awon Yoruba maa n lo lati mu ki ohun ti won n so loorin ki o si ni itumo ijinle ti won n fe. O fara pe owe sugbon ki I se owe. Akanlo ede ni awon oro ti itumo won farasin. Kanako ni idi ni wi pe bi gbolohun yii se kuru to itumo won po to bee gidigidi. Fun apeere:
AKANLO EDE ITUMO
Fi enu ko so oro odi si eni ti o julo t o si le ba teni je.
Ba ode pade se owo jeer.
Je iyan ni isu gba ijiya to buru.
Ejo lowo ninu eniyan kan wa nidi oro naa
Fowo meweewa jeun ya apa, ma ni ajeseku.
Ile n mi asiri fee tu.
Na papa bora sa lo bamubamu si ibi ti won ko ti le ri.
IGBELEWON
Se alaye itumo awon oro wonyi:
- Na papa bora
- Fi ori oka homu
- Fi aake kori
- Ile n mi
- Je iyan ni isu
IWE AKATILEWA
Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba iwe keta (J.S.S.3) oju iwe 85-87 University Press Plc.
ISE ASETILEWA
- Lilo…….. ko si lara ilana ti a n gba seda oro-oruko ninu ede Yoruba. (a) afomo ibere (b) afomo eyin (d) afomo aarin.
- a seda onikeke
pelu…………. (a) afomo ibere oni pelu oro oruko (b) afomo ibere oni pelu oro ise (d) afomo ibere pelu oro ise. - ewo ni ona ti a gba seda re yato ninu awon wonyi? (a) ojokojo (b) aisun (d) ayije.
- Ru eti omolangidi tumo si……………. (a) gbe eti omolangidi ru (b) ko jale (d) se aigboran.
- Akanlo ede ti mo le lo ti yoo tumo si ‘koja atunse ni………… (a) sangba fo (b) kutupu hu (d) epa ko boro mo.
APA KEJI
Ki ni awon akanlo ede wonyi tumo si
- Towo omo boso
- Se e bi ose se oju
- Fi ori oka homu
Lo awon oro wonyi pelu oro ise lati seda oro oruko
i, e.
OSE KARUN-UN
ATUNYEWO LETA KIKO
Akoonu: Leta gbefe
Leta aigbefe
Awo ilana leta gbefe.
Leta kiko je ona kan pataki ti a n lo lati ranse si ara eni. Kiko ni a maa n ko o. Ko si ohun ti a o le ko si eniyan afi eyi ti a ko fee ko. A le pin leta kiko si orisii ona meji pataki. Akoko ni leta gbefe (informal letter) nigba ti ekeji je leta aigbefe (formal letter).
Leta gbefe ni leta ti a n ko si eni ti o sunmo ni bi baba, iya, aburo, egbon.
ILANA LETA GBEFE
- Adireesi
- Ikini ibere
- Ifaara
- Ilapa ero
- Koko Leta
- Igunle
Alaye Pataki ti o ye ki o ye wa ni wi pe iyato diedie wa laarin leta gbefe ati leta aigbefe gege bi a ti ko seyin. Adireesi eyo ka n pere lo maaa wa ni leta gbefe iyen adireesi eni ti n ko leta ti o maa n wa ni oke apa otun leta. Ikini ibere le je Baba mi owon, Egbon Tunde, Iya mi atata, Ore mi Jumoke abbl. Ibi ifaara ni a ti maa n se alaye idi ti a fi n ko leta lerefee. Eyi tumo si oro ni soki si eni ti a n ko leta si. E je ki a wo ohun ti a n pe ni ilapa ero. Ilapa ero yii ni a ti maa n ko awon koko ti a fe ko aroko le lori ninu aroko. Fun apeere, aroko ti a fe ko ni: IDI TI ILE IWE MI FI DARA YATO SI ILE IWE MIIRAN. awon ti o le je ilapa ero re ni: bi ile iwe re se ri, bi aso ile iwe se ri, awon oluko to gbamuse, oga ile iwe re, awon ohun elo ikoni, bi awon oluko se n koni ni ile iwe naa. Gbogbo awon wonyi ni a ko si egbe kan. A o maa mu won ni eyo kookan si igbese ninu aroko wa. Ibi igunle ni a ti maa n ri awon oro bi: emi ni tiyin tooto ati oruko eni ti n ko leta. A ki n bu owo lu eleyi bi I ti leta aigbefe.
Leta aigbefe/ alaigbefe ni eyi ti ofin de pe o gbodo tele eto tabi ilana kan pato ti ijoba fowo si. Irufe leta yii ni leta ti a n ko si ile ise ijoba, eyi ti a n ko si ile ise nlanla, leta si ijoba ibile, leta iwase, leta igbaaye lenu ise abbl.
ETO IGBEKALE LETA AIGBEFE
- Adireesi
- Ibere
- ikini
- Ori
- Ifaara
- Ilapa ero
- Koko oro
- Ipari/igunle.
Adireesi leta aigbefe pin si orisii meji. Adireesi eni ti o n ko leta ati adiresi ibi ti leta nlo (eni ti a n ko leta si). Fun apeere:
12, Opopona Ayedaade,
Ibudoko U-Turn,
Abule Egba
Eko.
10-08-2010.
Oga ile iwe,
Good Shepherd School,
3, Opopona Olayinka, Moroga
Meiran.
Oga wa,
Adireesi eni ti o n ko leta yoo wa ni oke apa otun nigba ti adireesi eni ti a n ko leta si yoo wa ni oke apa osi. Leyin eyi ni ibere ati ori pelu awon igbese to ku. Ki I se dandan ni ki a ki eniyan ninu leta aigbefe bakan naa ni a gbodo kiyesi awon oro awada/ alufasansi ninu leta yii.
IGBELEWON
- Ko adireesi ile re sile.
- Ko adireesi ijoba ibile re sile.
- Ko iyato meta ti o wwa laarin leta gbefe ati leta aigbefe sile.
AKATILEWA
Oyebamji Mustapha (2005)Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (S.S .S.1) oju iwe 16- 21 University Press Plc.
IPA TI ESIN AJEJI KO NIINU ASA ABINIBI
ISE ASETILEWA
- Leta …….ni leta iwase. (a) ore (b) gbefe (d) alaigbefe.
- Ibi ti adireesi eni ti a n ko leta si maa n wa ni….. (a) isale leta patapata ni apa osi (b) oke leta ni apa otun (d) oke leta ni apa osi
- Adireesi eni ti n ko leta maa n wa ni ….. (a) isale leta ni apa otum (b) oke leta ni apa osi (d) oke leta ni apa otun

