Share this:

ILANA ISE SAA KIN-IN-NI

 

ISE: EDE YORUBA   KILAASI: S. S.3

 

Ose Kinni – Ede  –  Isori – Oro

Oro – Ise

Oriki –  Orisii

Ati ilo re.

asa –   Afiwe, asa isinku abinibi, omo leyin Kiristi ati musulumi

Litireso: Ogbon itopinpin litireso.

Oriki iwe, onkowe, Ibudo itan, itan ni soki abbl.

 

Ose keji –  Isori gbolohun gege bi ihun won.

 

asa  –  Eto ogun jija, awon iran ti o maa n ja ogun.

ecolebooks.com

Kin ni ogun, orisii ogun.

 

Litireso –  Itupale iwe Asayan ti ijoba yan (Awon eda itan).

Ose keta –  Dida oro – oruko ti a seda mo.

 

asa  –  Egbe Awo

Oriki orisii

Ipa ti won n ko ninu eto iselu

 

Litireso –  Kika iwe litireso ti ijoba yan.

Ose Kerin –  Iba – isele

Oriki, orisii awon wunren ti o toka iba – isele

asa  –  Igbagbo ati ero Yoruba nipa oso ati aje.

Litireso –  Kika iwe litireso.

Ose Karun-un –  Oro agbaso

asa –  Eko ile: eko imototo, itoju ara, bi a se n kini, awo fifo, ounje sise

abbl.

Litireso –  Kika iwe ti ajo WAEKI/WAEC yan.

Ose Kefa –  Itesiwaju lori aroko oniroyin.

asa  –  Ojuse eni ni awujo

Litireso –  Kika iwe litireso.

Ose Keje –  Iyato to wa laarin oro aponle ati apola aponle.

asa  –  Oran dida ati ijiya ti o to.

Litireso –  Ayewo finnifinni lori itandowe

 

Ose Kejo –  Aayan ogbufo

asa  –  Igbagbo awon Yoruba nipa aseyinwaye ati abami eda.

Ose Kesan-an –  Ayoka lorisiirisii

asa  –  Eewo aisan

Anfaani eewo aisan..

Kika iwe litireso.

 

Ose Kewaa –  Isori – oro

Oro – oruko

Oro aropo – oruko

Oro – ise

asa  –  Oruko ile Yoruba

Oruko amutorunwa

Oruko abiso

Inagije abbl.

Kika iwe litireso

Ose Kokanla –  Atunyewo eko lori ise saa yii.

 

IWE ITOKASI

 • Imo, Ede, asa Ati Litireso. S.Y Adewoyin
 • Eto Iro ati Girama fun Sekondiri Agba. Folarin Olatubosun.
 • Akojopo Alo Apagbe: Amoo A. (WAEC).
 • Oriki Orile Metadinlogbon: Babalola, A (WAEC).
 • Iremoje Ere Isipa Ode: Ajuwon B. (WAEC).
 • Igbeyin Lalayonta: Ajewole O. (WAEC).
 • Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).
 • Oremi Mi: Aderibigbe, M. (WAEC).
 • Egun Ori Ikunle: Lasunkanmi Tela. (NECO)
 • Omo Ti A Fise Wo: Ojukorola Oluwadamilare. (NECO).
 • Ewi Igbalode: Taiwo Olunlade. (NECO).

 

 

 

OSE KIN-IN-NI

ORO – ISE

Oro – ise ni oro tabi akojopo oro ti o n toka si isele tabi nnkan ti Oluwa se ninu gbolohun.

Oro–ise je opomulero fun gbolohun laisi oro–ise ninu gbolohun ko le ni itumo.

Apeere

Ade ra iwe Yoruba

Bolu fo aso

Ra ati fo lo je oro–ise ti a fi mo nnkan ti oluwa se.

EYA / ORISII ORO – ISE

i.  Oro – Ise kikun-: ni oro–ise to le da duro ti o si ni itumo kikun laisi pe a fi oro – ise miiran kun-un.

Apeere

 Sade ra dundu

 Bisi gba iwe kan

 

ii.  Oro – Ise agbabo-: ni awon oro – ise ti won ko le ma gba abo ninu gbólóhùn.

Apeere

 Kike je eja

 Bisi ra epa

 Awon abo inu gbolohun yii ni eja ati epa.

 

iii.  Oro – Ise alaigbabo-: ni oro – ise ti a kii lo abo pelu re ninu gbólóhùn.

Apeere

Ojo ro

Moji sun

Bolu ga

Bola jo.

 

iv.  Oro – Ise elela

Eyi ni awon oro – ise onisilebu meji ti a le la si meji gege bi oruko re lati fi oro miiran bo o ni aarin.

Apeere pamo, bawi, baje, reje, pade

 Bola pa ile mo (pamo)

 Mo ba Bola wi (bawi)

 Olu ba aga je (baje)

 

v.  Oro–Ise ASApejuwe

 ni awon oro – ise ti a maa ri lo lati se irisi nnkan

Apeere

 Obinrin naa pupa

 Tope ga

 Eja naa tobi

 

vi.  Oro – Ise alapepada -: ni oro – ise ti a maa n se apetunpe re ninu gbólóhùn

Apeere

 O ku o ku iwa re

 Ma da mi da bukaata mi.

 Aye o fe ni fe oro.

 

vii.  Oro – Ise Asokunfa-: ni o maa n fa nnkan tabi to mu ki nnkan kan sele. Awon oro – ise asokunfa ni fi, da, se, mu, ko .

Apeere

 O fi igi gba mi.

 O da oorun mo mi loju.

 O se iku pa awako re.

 O ko mi si wahala.

 

viii. Oro – Ise asoluwadabo-: ni iru gbólóhùn ti Oluwa ati abo ti le gba ipo ara won ninu iso.

Apeere

 Mo kanju ( kan oju ) – oju kan mi

 Mo jaya ( ja aya ) – Aya ja mi

 Sade jiya ( je iya ) – iya je sade

 

xi.  Oro – Ise asebeere -: ni a maa n lo lati gbe ibeere kale. Meji pere ni o wa ninu ede Yoruba, awon naa ni da ati nko

Apeere

 Awon omo nko?

 Ile yIn da?

 

IGBELEWON

 1. Kin ni oro – Ise?
 2. Daruko isori oro-ise marun-un

   

  IWE ITOKASI

  Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 137-147

   

  ASA

  AFIWE ASA ISINKU ABINIBI, OMO LEYIN KRISTI ATI MUSULUMI

Afiwe asa isinku abinibi ati eto isinku ti awon omo leyin Kristi ati ti musulumi. Ninu isinku abinibi, won kii gbe oku kale. Ojo ti oku ba ku ni o maa n wole afi ti o ba je pe ilu odikeji ni o ku si ti won fe gbe e wa si ile bakan naa ni eyi ninu isinku awon musulumi bi o ti wule ki o ri ojo ti oku musulumi ba ku ni o maa n wole sugbon fun ti awon omo leyin krisit kii se dandan ki oku won wole kiakia awon maa n fi oku sinu yinyin di igbakuugba ti won ba fe.

 

Ninu isinku ti abinibi ati ti omo leyin Kristi, won maa n lo posi (ile ikeyin) sugbon awon musulumi kii lo posi.

 

Bi awon abinibi ba fe sinku won maa n lo adie irana won gbagbo pe kii se ohun ajegbe sugbon awon musulumi ati omoleyin Kristi kii lo o

 

Sugbon awon abinibi omoleyin ati musulumi awon omo oku maa n bu eepe si oku lara ti won ba ti gbe ile

Awon metata lo n se eye fun oku agba

 

IGBELEWON

Awon ona wo ni asa isinku aye atijo ati aye ode oni fi jo ara won?

 

Litireso

OGBON ITOPINPIN LITIRESO

 

Akoonu:

Eyi ni awon koko to se pataki ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti ijoba ya eyi ti a maa ka. Oun akoko ti a gbodo mo ni oruko iwe, Oruko onkowe, ibudo itan, itan ni soki, awon eda itan, ona isowolo-ede, eko ti a ri ko, asa Yoruba ati beebee lo.

 

Iwe ti a maa gbe yewo ni ORIKI ORILE METADINLOGBON ati IREMOJE ERE ISIPA ODE won je ewi alohun abalaye.

Oruko Onkowe: oruko awon onkowe iwe naa ni: BABALOLA A. ati AJUWON B.

Ibudo Itan: n’ toka si ilu ti itan inu iwe yii ti waye.

Itan ni soki:

Eda Itan:

Akanlo Ede Ayaworan: owe, akanlo ede, afiwe, awitunwi, asorege, ifohunpeniyan, iforodara abbl.

 

IGBELEWON

 1. Kin ni oro – ise
 2. Salaye isori oro-ise merin pelu apeere mejimeji fun ikookan.
 3. Daruko awon koko to se pataki ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti a fe ka.

   

  APAPO IGBELEWON

 4. Kin ni oro – Ise?
 5. Daruko isori oro-ise marun-un
 6. Kin ni oro – ise
 7. Salaye isori oro-ise merin pelu apeere mejimeji fun ikookan.
 8. Daruko awon koko to se pataki ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti a fe ka.

   

  ISE SISE

 9. Ki ni oro aponle?
 10. Ko apeere oro oruko mmefa
 11. Salaye ni soki lori asa igbeyawo ile Yoruba.
 12. Ki ni silebu?

   

  IWE ITOKASI

  Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 334

   

  ISE AKATILEWA

 13. _____ ni opomulero fun gbolohun (a) oro-oruko (b) oro-ise (d) eyan
 14. E rowa ro ire je apeere oro-ise _____ (a) asoluwadabo (b) alapepada (d) agbabo
 15. Sola da obe nu. Oro_ise iru gbolohun yi ni (a) da (b) obe (d) danu.
 16. Awon ______ lo maa n lo adie irana ninu isinku won. (a) Omo leyin Kristi (b) Musulumi (d) abinibi
 17. Awon _________ ki lo posi fun oku won (a) abinibi (b) Musulumi (d) Omo leyin Kristi.

   

  APA KEJI

 18. a. Kin ni oro-ise?

b. Daruko isori oro-ise marun-un  

c. Salaye meji ninu won pelu apeere.

 1. Se afiwe asa isinku abinibi, omo leyin Kristi ati musulumi.

   

   

   

  OSE KEJI

  ISORI GBOLOHUN

  Oríkì

  Ìsorí gbólóhùn pèlú àpẹẹrẹ

  Akóónú

Gbólóhùn ni ìpèdè tí ó kún, tí o sí ní ìse tí ó ń jé. Gbólóhùn jé ìsọ tí ó ní ìtumo kíkún. A fún àwon gbólóhùn Yorùbá ní orúkọ gégé bí íse tí won ń se. Àpẹẹrẹ:

Bólú je èba.

Bàbá kọ ebè

 

Èyà gbólóhùn

Orisiirisii ni awon eya gbolohun ti o wa ninu ede Yoruba.

Gbólóhùn Eleyo oro-ise

Gbólóhùn Olopo oro-ise

Gbólóhùn Ibeere

Gbólóhùn Ase

Gbólóhùn Alaye  

Gbólóhùn Akiyesi alatenumo

Gbólóhùn Kani/Onikani.

Gbólóhùn lyisodi

Gbólóhùn Asodoruko

 

Gbólóhùn Eleyo Oro-Ise-: ni gbolohun ti o maa n ni eyo oro ise kan

Apola oro oruko ati apola oro ise ni o maa n wa ninu gbolohun eleyo oro-lse

Apeere

Baba te eba

Apola oro-oruko Apola oro-ise

Olu sun

Mo ra eran

Tisa na titi

 

Apola oro-oruko + Apola oro-ise.

Adekunle + lo ile.

 

Gbólóhùn Olopo Oro-Ise-: Eyi ni gbolohun ti o maa n ni ju oro-ise kan lo o le je meji, meta tabi ju bee lo. Iye oro ti o ba wa ninu gbólóhùn yii ni iye gbolohun ti a le ri fayo ninu re. Apeere:

– Omo naa gba ile baba mo tonitoni

– Omo naa gba ile baba

– Ile baba mo tonitoni

– Bolu sare
lo
ra aso

– Mama lo ra eran wa

 

Gbólóhùn–Ase: ni a maa n lo lati pase.

Apeere: Wa, Jade, Dake, Lo pon omi wa.

Gbólóhùn lbeere-: ni a maa n lo lati se lbeere tabi wadii nnkan ni orisiirisii ona nipa lilo wunren lbeere bii kin ni elo, nibo, tani, meloo, nigba wo.

Ki ni oruko re?

Nibo ni o n lo?

Elo ni o ra iwe yii?

Tola da ?

Se olu ti wa?

 

Gbólóhùn Kani-: ni a fi maa n so wulewule/kulekule bi nnkan se ri ati idi ti o fi ri bee. Apeere

Bi mo ba lowo, maa kole

Kaka ki n jale, maa seru

Bi Bolu ba ro bee yoo jeko

 

Gbólóhùn Akiyesi Alatenumo-: ni a fi n pe akiyesi si apa kan koko inu odidi gbólóhùn. ‘Ni’ ni atoka gbolohun yii . A le se atenumo fun oluwa ,abo tabi oro-ise. Apeere:

Mo ra iwe

Iwe ni mo ra (abo)

Rira ni mo iwe (oro-ise)

Emi ni mo ra iwe (oluwa)

 

Gbolohun Iyisodi-: ni a fi n ko isele. Apeere:

Bolu ko jeun

Baba ko yo

Se o maa lo?

N ko lo.

Bolu ti de?

Ko tii de

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 211-217

 

IGBELEWON

Kin ni gbolohun?

Salaye eya gbolohun marun-un pelu apeere kookan.

 

ASA ETO OGUN JIJA

asa :- Eto ogun jija

-oriki

 • orisii ogun ati ohun ti o n fa ogun
 • ipalemo
 • -awon omo ogun, olye ogun

  AKOONU

 • ogun jija:- ni biba ara eni ja nipa lilo awon omo ogun ti o ni ohun ija oloro ti o le pa ni tabi se ni ni ijamba, iru ibara-eni-ja bee maa n waye laarin ilu si ilu ati eya si eya.

  Orisii ogun meji ni o wa ogun adaja ati Ogun ajadiju tabi ajakuakata.

Ogun Adaja:- eyi ni isoro nla ti o n koju enikan tabi idale labe ile won, ti ko kan ara ilu, isoro bee le je aisan buruku, iku gbigbona tabi isoro nla.

 

Ogun Ajadiju tabi Ajaku Akata:- eyi le je ogun adugbo si adugbo, ileto si ileto tabi ilu si ilu,

awon ilu miiran a maa parapo lati gbogun ti eya miiran.

 

Ohun to n fa ogun

Ija lori aala ile

Ipinnu lati ko iwosi tabi ireje

Ojukokoro si oro tabi alumoni ile elomiran

Gbigbeja ilu ti a ni ife si

Sisigun lati fi agbara han

Sisigun lati fi wa owo bi oda owo ba fe da ni

 

IPALEMO

Yoruba je eya kan to maa n fi eto ati arogun si ise won, won kii deede sigun lo ba ilu keji, o ni

awon ilana ti won maa n tele. Bi ogun yoo ba bere, won a koko fi to oba leti ati gbogbo awon to

ye ko gbo leyin eyi ni won yoo fi oro naa si waju ifa.

 

-Ifa Dida:- won kii lo soju ogun laidafa, igbagbo won ni pe ifa yoo se alatileyin won.

-Bibo ogun ati esu:- won yoo se rubo si ogun, eni ti won gba pe o ni gbogbo ohun ija fun ogun nikawo ati pe ki esu ma se won.

-Pipolongo Ogun kaakiri Ilu:- ikede yii yoo de odo awon ara ilu ki won le maa mura sile.

 

Awon oloye ogun

Arare Onakakanfo: ni o je olori ogun ile Yoruba.

Balogun: ni oloye ogun ti ipo re ga ju ni ilu kookan ni ile Yoruba, o si tun ni awon asomogbe

Seriki: ni ipo re powole Balogun oun ni alakoso awon odo.

Asiwaju lo tele seriki oun ni o maa n saaju ogun.

Sarumi: ni olori awon to n fi esin ja loju ogun

 

IGBELEWON

Ko oloye ogun merin ki o si salaye ise pataki okookan won.

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i

 

Lit:  ITUPALE ASAYAN IWE TI IJOBA YAN

Awon eda itan ti o ko pa ninu iwe

 

IGBELEWO

 1. a. Ki ni gbolohun?

  b. Daruko orisii gbolohun marun-un ti o mo, ki o si salaye meta ninu won pelu apeere mejimeji fun ikookan.

 2. Daruko eda itan mefa ti o kopa ninu iwe Adakedajo.

  3  Salaye ipa ti meji ko ninu won.

   

  APAPO IGBELEWO

 3. Kin ni gbolohun?
 4. Daruko orisii gbolohun marun-un ti o mo, ki o si salaye meta ninu won pelu apeere mejimeji fun ikookan.
 5. Daruko eda itan mefa ti o kopa ninu iwe………

  4  Salaye ipa ti meji ko ninu won.

  5  Ko orisii ogun jija ki o si salaye won.

   

  ISE SISE

  Ko aroko oniroyin kan ti ko din ni eyo oro odunrun.

   

  IWE AKATILEWA

  Imo, Ede ASA ati Litireso Yoruba SS2 Adewoyin S.Y.O I 113 – 120

  Iwe Adakedajo – Iran Kinni ati Ikeji.

   

  ISE ASETILEWA

 6. Gbogbo yin e maa bo. je apeere gbolohun (a) Ibeere (b) ase (d) alaye
 7. Ise oni ti pari je. (a) Gbolohun Ibeere (b) Gbolohun ase (d)Gbolohun alaye
 8. Ona _______ni ogun pin si (a) meji (b) meta (d)merin
 9. ______je okan lara ohun ti o n fa ogun ni aye atijo (a) ile (b) aso (d) omo
 10. Iwe Adakedajo je _______ (a) olorogeere (b) ere onise (d) ewi

   

  APA KEJI

 11. a. Kin ni gbolohun?

  b. Salaye isori gbolohun marun-un pelu apeere mejimeji fun ikookan.

 12. a. Kin ni ogun jija?

  b. ona meloo ni ogun pin si?

  c. Daruko ohun merin ti o n fa ogun.

 

 

 

OSE KETA

DIDA ORO ORUKO TI A SEDA MO YATO SI EYI TI A KO SEDA

Ori-oro-: Dida oro – oruko ti a seda mo ninu gbolohun Isunki ati aranmo ninu awon oro–oruko ti a seda

Akoonu

Bi a se le da oro – oruko ti a seda mo nipe, a gbodo le tu oro- oruko ti a seda pale, ki a si mo awon wunren to, bi Ini oro – oruko bee.

 

Apeere

I + jo = ijo

I – je afomo ibere

Jo – je oro – ise, eyi ti o fun wa ni ijo – a o rii pe itumo oro – ise yii gbe irumo oto – oruko ti o fun wa jade.

Isunki maa n waye leyin ti a ba ti so gblohun di oruko eyniyan. Apeere

 Mo ri ohun mu bo yoo di

1  2  3  4  5  6

Bakan naa aranmo maa n waye laarin oro–oruko meji ti a seda ki won to di oro–oruko kansoso ti a seda. Apeere

 Omo ile – Omoole

 Oja Oba – Ojaaba.

 

IGBELEWON

Bawo ni a se le da oro-oruko ti a seda mo? Salaye.

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i

 

ASA

EGBE AWO

Akoonu

Egbe Awo je ohun ti a se ti a ko fi asiri re hani.

Egbe Awo:- ni egbe ti a da sile ti won n se ipade ti enikeni ko si mo ohun ti won nse nibi ipade naa. Iru egbe bee ti di egbe awo, ti awon omo egbe si fi ibura de ara won pe enikeni ko gbodo tu asiri ohun ti won n se.

 

Orisii egbe awo ti o wa nile Yoruba.

Orisiirisii egbe awo lo wa, opolopo nnkan ni won fi jora iyato diedie lo wa ni aarin won.

 1. Ogboni ibile
 2. Egbe ogboni ti a se atunse si (R. O. F)
 3. Awo Opa
 4. Awo to je mo esin ibile
 5. Awo oso ati aje
 6. Egbe Emere at Abiku

  Ipa ti awon egbe wonyi n ko ninu eto iselu.

  Ipa pataki ni awon ogboni n ko ninu eto iselu, awon lo maa n je oludamoran fun awon oba.

  Awon ni alase ilu, owo won ni eto ifobaje wa. Oba gbodo je okan ninu omo egbe,

  bi oba ba se awon ogboni ni ase lati da seria fun-un, bi ese re baju ijiya lo, won le yo kuro loye.

  Owo won ni eto idajo wa nitori pe awon lo n se idajo fun awon arufin ati odaran.

  Awon lo n fi oro gbe awon odaran ti ijiya ese won ba je mo iku.

  Awon lon se eto isinku oba, olola ati ijoye laarin ilu.

   

  ETO ORO AJE

Awon ogboni tun ni agbara nipa eto oro aje nitori pe awon ni parakoyi (onisowo pataki). Awon parakoyi lo maa n mojuto awon oja to wa laarin ilu.

Awon lo n ri si idagbasoke owo sise laye atijo.

Won maa n ran eni ti a je lowo lati ba a gba gbese pada.

 

ETUTU ILU

Awon ogboni lo maa n se etutu to le mu ilu tuba-tuse ni pataki julo ti ajakale arun ba wa.

Awon oye inu egbe awo bi eeyan ba darapo mo egbe awon ni pataki ogboni ipeyin tabi omode ni o maa koko wa, sugbon bi o ti n dagba si ninu egbe ni yoo ma ni igbega.

Iledi tabi ile ogboni ni a n pe ibi ti won maa n se ipade.

Oye mefa ni o ga ju nindu egbe ogboni, awon ni a mo si “iwarefa” awon naa ni:

Oluwo – ni olori patapata.

Lisa

Asalu

Aro

Apeena

Losi

Lemo

Nlado

Odofin abbl.

 

Imurawon

Ona ti awon ogboni n gba mura ni a fi maa n da won mo. Won maa n san aso mo idi, won yoo da bora, won yoo so saki tabi itagbe si ejika otun, leyin naa won yoo de akete fenfe, won yoo maa fi opa tele, won a si wa ileke sorun ati owo.

Awon omo egbe ogboni ka ara won si omo iya, won a si maa huwa omo iya meji si ara won. Idi niyi ti won fi maa n ran ara won lowo.

 

LITIRESO

Kika iwe ti ijoba yan . Iran kinni ati Ikeji.

 

IGBELEWON

1.  Pelu apeere salaye bi a se le da oro-oruko ti a seda mo.

2.  Se itupale fun oro-oruko eniyan (merin)

 

APAPO IGBELEWON

 1. Bawo ni a se le da oro-oruko ti a seda mo? Salaye.
 2. Pelu apeere salaye bi a se le da oro-oruko ti a seda mo.
 3. Se itupale fun oro-oruko eniyan (merin)

   

  ISE SISE

 4. Se ipaje awon oro yii: ekuro, edidu, akara, daradara, eti ile, ewe oko, irun agbon, orisa, otito.
 5. Ko iwa omoluwabi mejo sile.
 6. Salaye lori ounje ibile Yoruba kan ti o mo.

   

  IWE AKATILEWA

  Eko Ede Yoruba Titun, iwe keji SS3

  Oyebamiji Mustapha 0.1

  ISE ASETILEWA

  1.  Ewo ninu awon wonyi ni oro-oruko ti a seda lati inu gbolohun (a) Asona (b) Ogunniyi (d) Itiju

  2.  A gbodo le ______ oro –oruko ti a ba seda (a) pe (b) tu pale (d) fi ami si

  3.  ______ni awon ogboni ti maa n se ipade (a) ile egbe (b) Iledi (d) Ileipade

  4.  ________ ni Olori patapata ninu awon oloye ogboni (a)apeena (b)Lisa (d) Oluwo

  5.  Awon __________ lo n risi idagbasoke owo ni aye atijo. (a) Awon parakoyi (b) Awo opa (d) Doje

   

  APAKEJI

  1.  Salaye pelu apeere ona meji ti a le gba lati da oro-oruko ti a seda mo.

  2.  a. Kin in egbe awo?

  b. Salaye ipa merin ti awon ogboni n ko ninu eto iselu laye atijo.

   

   

   

  OSE KERIN

  IBA-ISELE

  – Oriki

  – Orisii iba-isele

  – Awon wunren ti o toka iba-isele

  Akonu:

  ORI-ORO: ASIKO ATI IBA ISELE

  ORIKI

  EYA IBA ISELE

  AKOONU

Asiko je oro girama ti a maa n lo lati fi toka si asiko ti isele kan waye. Orisii asiko meji lo wa ninu ede Yoruba.

 • Asiko afanamoni.
 • Asiko ojo iwaju.

  Asiko Afanamoni: ni isele ti o ti sele koja tabi eyi ti o sele lowolowo ni asiko yii. Apeere

  Olu lo ile

  Baba je amala

  Asiko Ojo Iwaju: eyi ni isele ti ko tii sele sugbon ti o si maa sele ni ojo iwaju. Apeere:

  Bade yoo lo si ilu oba.

  Baba yoo joba.

  Iba Isele: Eyi ni oro girama ti o maa n siwaju oro-ise lati toka si iba isele ni pato

   

  Eya iba-isele

  Orisii iba-isele meta lo wa ninu ede Yoruba

 1. Iba-isele Adawa
 2. Iba-isele Aisetan

  Aterere/Baraku

 3. Iba-isele Asetan

  Ibere /Ipari

  Iba-isele ninu asiko afanamonii

 4. Iba-isele Adawa

   

  Iba-isele ninu asiko afanamonii ko ni atoka Kankan. Apeere:

  Olu lo si oja

  Won ra moto

  ii.  Iba-isele aisetan aterere

  Eyi ni isele ti o si n lo lowolowo, isele ti ko kii pari, erun oro-ise ‘n’ ni atoka re. Apeere

  Bolu n korin.

  Won n fo aso.

   

  Iba-Isele Aisetan Baraku

  Eyi ni isele ti o maa n sele ni gbogbo igba. Atoka iba-isele yii ni a maa, maa n. Apeere:

  Dayo a maa pariwo soro

  Maa maa n we ni alaale

   

  iii. Iba-Isele Asetan: Asetan ibere. Eyi ni isele ti ibere re ti bere sugbon ti gbogbo isele maa ko ti i pari tan. Atoka iba-isele yii ni, ti n, ti maa n ati maa. Apeere

  Mama ti n dana

  Bade ti maa n jeun

  Sade a ti maa bo

   

  Asetan Ipari: Eyi ni isele ti o ti pari patapata. Atoka iba-isele yii ni ‘ti’. Apeere:

  Ayo ti korin.

  Mama ti gbale.

  Bolu ti de.

   

  IGBELEWON

  Kin ni iba-isele?

  Salaye awon iba-isele wonyi – aterete, asetan ipari

   

  IWE ITOKASI

  Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 174-176

   

  ASA

  IGBAGBO ATI ERO YORUBA NIPA OSO ATI AJE

  Akoonu

Awon Yoruba gba pe oso ati aje wa, won tile ni igbagbo yii to bee ti o fi je pe, o soro lati ri eni ti o ku, yagan tabi ti wahala sele si, ti won ko ni so o mo oso ati aje.

 

Bakan naa awon Yoruba gbagbo pe oso ati aje ni agbara oogun ti won le fi pa eni ti won ba fe pa. Won gbagbo pe inu ipade aje ni won ti maa n duna-dura bi won yoo se pa eni ti won ba fe pa. Won gbagbo pe ona meji ni okunrin fi n gba oso

-ajogunba

wiwo egbe oso bee naa ni ti aje o le je, nipa ajogunba/wiwo egbe aje

Iyato laarin oso ati aye

Iyato to wa laarin oso ati aje ni pe awon okunrin lo maa n je oso nigba ti awon aje je obinrin.

Litireso:- KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN

Iran keta ati ikerin

 

IGBELEWON

1.  a. Kin ni iba-isele?

b. Salaye orisii iba-isele ti owa pelu apeere mejimeji fun ikookan.

2.  Salaye igbagbo ati ero awon Yoruba nipa oso ati aje.

 

APAPO IGBELEWON

1.  a. Kin ni iba-isele?

b. Salaye orisii iba-isele ti owa pelu apeere mejimeji fun ikookan.

2.  Salaye igbagbo ati ero awon Yoruba nipa oso ati ajo.

3  Kin ni iba-isele?

4  Salaye awon iba-isele wonyi – aterete, asetan ipari

 

ISE SISE

 1. Salaye lori ise abinibi kan ti o yeo yekeyeke
 2. Ipaje ni
 3. Ko apeere mejo.

   

  IWE AKATILEWA

  Mustapha, O.Eko Ede Yoruba Titun S.S. 2 o.i 85 – 93

   

  ISE ASETILEWA

  1.  ____ ni isele ti o ti bere sugbon ti ko tii pari (a) asetan ibere (b) aterere (d) aisetan

  2  Atoka fun iba – isele aisetan aterere ni ____ (a) ni (b) n (d) ti

  3.  Iba-isele ti ko ni atoka kankan ni ____ (a) Adawa (b) asetan (d) aisetan

  4.  Kin lo poju ninu ohun ti oso ati aje n lo agbara won fun? (a) ire (b) ibe (d) alaafia

  5.  ____ ni won n lo si inu to n run Adigun. (a) Apoogun (b) Apooro epa ijebu (d) oogun jedi

   

  APA KEJI

  1.  Salaye awon iba-isele won yii pelu apeere mejimeji fun ikookan.

   Iba- isele asetan ibere

   Iba-isele aisetan aterere

   Iba-isele aisetan baraku

   Iba-isele asetan ipari

2. Salaye lekun-un rere ohun ti o sele si Adigun ati owo ti won fi ran-an nise.

 

 

 

OSE KARUN – UN

ORO – AGBASO

Akoonu

Oro agbaso naa ni a mo si afo agbaran.

Oro agbaso:- je siso oro ti a gbo lenu oloro fun elomiran. Iru oro tabi iroyin bee gbodo je eyi to ti koja. Oro agbaso le je ohun ti enikan so nipa wa tabi elomiran. O si le je iroyin ohun to sele nibi kan. Awon wunren atoka oro agbaso ni so, wi, ni, ki, pase, wi pe, salaye, so fun abbl

Tunde ni oun ko ni wa si ipade

Sola beere boya a ti jeun

 

Bi a ba n se agbaso, ayipada maa n de ba oro aropo oruko tabi oro aropo afarajoruko, ti eni to n soro ba lo oro aropo-oruko tabi oro aropo-afarajoruko enikinni ninu oro re – oro aropo –oruko tabi afarajoruko eniketa ni eni to n se agbaso yoo lo. Apeere:

Mo ri owo he.

Agbaso-  O ni oun ri owo he.

A ko mo won ri

Won ni awon ko mo won ri

Mo fo aso

O ni oun fo aso

Atunse maa n sele si oro-oruko

ap

Afo asafo: Eyi ni ki o ra.

O pase pe iyen ni ki o ra

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i

 

ASA

EKO ILE

(Eko imototo, itoju ara, ikini, oro, siso, ounje sise, awo fifo)

Akoonu

 

Eko Ile:- Je ilana eko abinibi ti awon obi fi n ko awon omo won lati kekere. Yoruba ni kekere ni musulumi ti n ko omo re laso. Awon Yoruba ka eko-ile si pupo, won a si maa du u ni gbogbo ona lati ko omo won, ki won si rii pe omo naa gbeko, nitori won gbagbo pe omo ti a o ba ko ni yoo gbe ile ti a ko ta.

Omo ti a ko ti ko gba ni akoogba. Won gba pe ajoto ni omo kii se ajoke .

 

Eko–ile: ki i se ojuse obi nikan, ojuse gbogbo ebi ni lati ko omo. Ni ile Yoruba, ni kete ti a ba ti bi omo si aye ni eko ti n bere titi yoo fi dagba bee ni eko ile ko ni opin, eko omobinrin bere lati kekere titi ti yoo fi wo ile-oko.

 

Imototo: Lati kekere ni awon Yoruba ti n ko omo won ni imototo, won a ti we fun won laaaro, won a fo enu fun won, iwa yii naa ni awon omo maa tele ti a si mo won lara dagba.

Ikini:- Je asa ti o se pataki laarin awon Yoruba , ojuse gbogbo obi si ni lati fi ko omo, won a ti ko won lati kekere pe bi a ba ti ji laaaro kutukutu omode gbodo koko ki awon obi re pe obinrin a kunle, okunrin a si dobale.

E ku ikale ni a n ki eni to wa ni ijoko.

‘E ku ewu’ – omo ni a n ki eni to bimo .

‘mo kota, mo kope ni a n ki awon tin ta ayo.

Gbogbo ikini wonyi ni awon Yoruba fi n ko omo won lati kekere.

 

Oro siso:- lati kekere ni awon Yoruba ti maa n to awon omo won sona nipa oro siso, pe kii se gbogbo oro tabi ohun ti a ri ni a n so; bakan naa won a to won sona nipa bi a se le ba agbalagba soro laini fi enu ko tabi ri agba fin nitori pe eko ile ni atona fun iwa rere.

Lati kekere naa ni awon Yoruba pataki julo awon iya yoo ti maa ko awon omobinrin bi a ti n toju ounje ati bi a se n se ise ile laaaro, ile gbigba ati abo fifo.

 

Litireso:- Kika iiran karun-un, kefa ati ikeje ninu iwe Adakedajo.

 

IGBELEWON

1.  Kin ni oro-agbaso?

b.  Se agbaso oro ti Alaga ijoba ibile agbegbe re so ninu ibewo re si ile eko re.

Mo ki gbogbo eyin oluko ati akeko, E ku ojo meta o. Inu mi dun pupo lati rii pe gbogbo ayika ile –eko yin lo mo tonitoni. Ise ribiribi ni e n se nile iwe tiyin. Gbogbo ohun ti e n fe ni oga ile-iwe yin ti fi to mi leti. Awa naa yoo gbiyanju lati ran yin lowo.

 

APAPPO IGBELEWON

 1. Kin ni oro-agbaso?
 2. Ki ni eko ile?
 3. Ko apeere afihan eko ile meje sile.

  Ko apeere awon merin ti won maa n ko pa ninu eko ile.

   

  ISE SISE

  Seda
  oro oruko merin pelu: lilo afomo ati apetunpe

   

  IWE ITOKASI

  Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers S.S.S.1 o.i

   

  IWE AKATILEWA

  Imo, Ede, asa ati litireso SS 2

  Adewoyin S.Y. O.i 156 – 158

  Eko Ede Yoruba Titun. Oyebanji SS.2 o.i 123 – 124

  Adakedajo – iran kejo & ikesan

   

  ISE ASETILEWA

  1.  Iwonyi ni oluko eko-ile fun omo ayafi (a) obi (b) ebi (d) Tisa

  2.  Mo kota, mo kope ni an ki awon ti n (a) ta yo (b) ko ebe (d) di irun

  3.  Ona pataki ti a fi n mo omluabi ni (a) ewa nini (b) ikini pelu oyaya (d) iran wiwo

  4.  ‘Emi kii se ole eniyan’ oro agbaso re ni (a) oluko so pe emi kii se ole (b) Oluko so pe oun kii se ole (d) Oluko so pea won akekoo kii se ole

  5.  Kanni ati Alade tun sa __________ jo ni eleekeji (a) Egberun mewaa (b) Egberun meedogun (d) Egberun lona ogun

   

  APA KEJI

  1.  a. Kin ni oro-agbaso?

  b. Salaye awon iyipada ti o maa n ba isori oro kookan pelu apeere

  2.  Kin ni eko ile?

  Ona wo ni awon Yoruba n gba lati ko awon omo won ni iwa imototo, Ikini ati oro siso ni aye atijo.

   

   

  OSE KEFA

  AROKO ONIROYIN

  Akoonu:

Aroko Oniroyin:- je mo iroyin sise tabi itan isele ti o ti koja seyin ti o si se oju eni ti a n royin re ni sise-n-tele ninu aroko oniroyin fun elomiran ti ko si nibe. A rii wi pe o fi ara pe aroko Asapejuwe. Ki a to le se iroyin yori, a gbodo je eni ti o ni ife si gbigbo tabi kika iwe itan kekere.

Eyi ni apeere ori-oro, to je mo aroko oniroyin.

Iroyin ipade maje–o–baje kan ti mo lo.

Ayeye odun eyo ni ilu eko

Ojo buruku, esu gbomi mu.

Ipolongo eto idibo ti o koja

Bi mo se lo isinmi mi ti o koja

Isomoloruko kan ti won se ni odede wa laipe yii.

 

IGBELEWON

Ko aroko lori ‘Isomoloruko kan ti won se ni adugbo wa laipe yi’.

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 23-26

 

ASA

OJUSE ENI NI AWUJO

Ojuse:  ni ohun ti a n reti ki enikookan se fun ilosiwaju awujo re. Gege bi ara ilu, a ni ojuse ti a ni lati se fun awujo wa.

 

 1. Akoko, gege bi omo ilu, ti o ni ife ilu re, a gbodo pa ofin ilu wa tabi awujo wa mo fun alaafia ati ilosiwaju awujo wa.
 2. Ojuse wa ni lati san owo ori wa, eyi a le je ki awon ijoba ri owo lati le pese iwosan, omi, eko ofe, ina, oju ona to dara fun wa, bi a ba ko lati se ojuse wa, awon ijoba naa ko ni to to fun wa.
 3. Ojuse wa ni lati lowo ninu ise ajumose ilu bii yiye ona, tite afara, abbl. Fun idagbasoke ilu tabi awujo wa.
 4. Bakan naa, ojuse wa ni lati je olooto nibikibi ti a ba wa, ki won si le gba eri wa je.
 5. Ojuse wa ni lati je asoju rere fun ilu awujo ati orile ede.

 

Lapapo, ki a mase ba oruko ilu wa je. Ibi ti a ti le se ojuse wa ni ibikibi ti a ba ti ba ara wa ni a ti gbodo se ojuse wa. O bere lati inu ile wa, laarin ebi, egbe lodo ala adugbo, alabaagbe, ilu, ati ni awujo lapapo.

 

IGBELEWON

1.  a. Kin ni iwa ojuse?

 b. Daruko awon ohun to je ojuse wa ni awujo

 

Litireso: ORI IRAN KOKANLA.

 

IGBELEWON

Se agekuru ohun to sele ni iran ti a ka yi.

APAPO IGBELEWON

1.  a. Kin ni iwa ojuse?

 b. Daruko awon ohun to je ojuse wa ni awujo

2.  Se agekuru ohun to sele ni iran ti a ka yi.

 

ISE SISE

Ko apeere gbolo:

 1. Ase
 2. Ibeere
 3. Alaye
 4. Olopo oro-ise

   

  IWE AKATILEWA

  Imo Ede ASA ati litireso Yoruba fun sekondiri agba S.S. 2 S.Y. Adewoyin o.i 71 – 73

  Adakedajo – Iran kejila – Ikeedogun.

   

  ISE ASETILEWA

  1.  Aroko oniroyin jemo _____(a) Itan siso (b) Alaye (d) Iroyin sise

  2.  okan lara amuye iwa omoluabi ni (a) Ipanle (b) suuru (d) Igberaga

  3.  ______ lo ye ki a ti maa huwa omoluabi (a) ile (b) adugbo (d) Ibi gbogbo

  4.  ____ ni moto ti Alade wo ti ni ijamba (a) Jebba (b) Ilorin (d) Kano

  5.  Nibo ni Alade fi sese (a) ori (b) eyin (d) ese

   

  APA KEJI

  1.  a. Kin ni iwa omoluabi?

   b. Ibo lo ye ki a ti huwa omoluabi?

  2.  a. Daruko amuye iwa omoluabi mefa.

   b. Salaye meji ninu won.

   

   

   

  OSE KEJE

  IYATO TI O WA LAARIN ORO-APONLE ATI APOLA-APONLE

  Isori oro ni oro-aponle sugbon apola aponle gbooro ju oro-aponle lo.

  Apeere:

  Ojo tete de

  O de nigba ti Ojo wole

Isori oro-aponle nikan ni oro-aponle je mo sugbon apola aponle je mo alopo oro-atokun ati oro-oruko

Baba olu gbon pupo

Aso mi mo tonitoni

Apola – aponle

Apeere:

Ile nlanla po ni Eko

Aja kan ku si ita

Ninu oro-aponle a ko le gbe oro-aponle si iwaju gbolohun

Apeere:

O dun mi gan an

Gan-an ni o dun mi

Tete ni ojo de

Oro-aponle ko se e gbe siwaju fun itenumo sugbon apola-aponle se e gbe siwaju fun itenumo

Apeere:

O se pupo

Pupo ni o see

Baba agba rin pelepele

Pelepele ni baba agba rin.

 

IGBELEWON

Salaye pelu apeere iyato meji to wa laarin oro-aponle ati apola-aponle.

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 204-208

 

ASA

Oran dida ati ijiya ti o to,

 Oran dida ati ijiya ti o to

 • Itumo
 • Ohun ti o faa
 • Orisii oran ti eeyan le da
 • Ipa ti oba ati ogboni n ko ninu fifi iya je odaran
 • Orisirisi oran ti eeyan le da
 • Ipa ti oba ati ogboni n ko ninu fifi iya je arufin

   

  AKOONU

Se Yoruba bo won ni ‘ilu ti ko si ofin ese ko si, bakan naa awon Yoruba ni igbagbo ninu idajo ododo won ki i si i fi ejo se egbe. Bakan naa, won ni elese kan ki yoo lo laijiya nitori idi eyi gbogbo oran lo ni ijiya. Oba, ijoye ati awon ologboni lo maa n se eto idajo ni aye atijo.

 

Oran Dida: Ni ti tapa si ofin tabi rire ofin ilu kan koja ni pa sise ohun ti won ni won ko gbodo se tabi sise omonikeji ni ibi. Ohun ti o n fa oran dida orisiirisii ni ohun ti o le fa oran dida, die ninu won niyi:-

 • Ojukokoro
 • Iwa imotara eni nikan
 • Aini itelorun
 • Etanu
 • Aigboran abbl.

Orisiirisii oran ti eeyan le da ati ijiya ti o to sii. Eyi ni orisiirisii oran ti eeyan le da:

ipaniyan, ole jija, idigunjale, ifadiya, jibiti lilu, aje sise, biba iyawo oniyawo lopo, lilo oogun ika, gbomogbomo abbl.  Ipa ti oba ati ogboni n ko ninu fifi iya je odaran.

 

Ipa kekere ko ni oba ati awon ogboni n ko ninu fifi iya je odaran. Gege bi a se mo pe oba ni olori ati alase ilu, ti o n ri si idagbasoke ati aabo ilu, ti odaran ba daran, ti o si ju eyi ti Baale tabi Baale le pari lo, aafin oba ni won yoo mu iru odaran bee lo, ti oba ati awon ijoye yoo si jiroro lori iru iya ti won yoo fi je iru odaran bee. Bakan naa ni awon ogboni naa ko gbeyin ninu fifi iya je arufin.

 

IGBELEWON

Daruko oran marun-un ti eeyan le da.

 

Ori – Oro:- ITANDOWE

– Kin ni itandowe

– Siso itandowe kookan

– Tokasi owe ati Asayan to suyo ninu itan naa.

 

Akoonu

Itandowe: Je awon itan ohun kan ti o ti sele ni aye atijo ti awon baba-nla wa si so isele inu itan naa di owe.

Itandowe le je itan atenudenu bii itan ogun, itan isedale tabi itan aroso. Apeere itandowe.

Ogbon ti alabahun gbon, eyin ni yoo ma to igbin.

Inu itan aroso yii ni owe yii ti jade. Ni ojo kan alabahun, ti adape re n je ijapa Tiroko oko yanubo, ni oun fe ko gbogbo ogbon aye jo sinu akangbe kan. Loooto, o ko awon ogbon yii jo, o si dii pa mo inu akangbe. Ijapa wa fe lo toju akengbe yii si ori igi kan, ki o ma ba a si mi arowoto enikankan rara.

O so Okun mo akengbe yii ni orun, o gbe akengbe si ogangan aya, o fe gun igi naa lo.

Bi o ti n gun igi yii ni o n jabo nitori pe, akengbe to gbe ko aya ko je ki owo re ka igi to fegun daadaa. O n se idiwo fun-un igba die. Inu isoro yii ni o wa ti igbin fi de baa, ti o si koo pe ki o yi akengbe si eyin ki o le rorun fun-un. Ijapa se bee, o si ri igi naa gun.

Ijapa wa gba pe ogbon tun ku si ibikan, ati pe eni ti o si tun gbon ju oun lo wa.

O si fi ibinu fo akengbe ti o ko ogbon jo si. Isele yii ni o faa ti awon eniyan fi maa n paa ni owe lati igba naa. E wo bi igbin se kere si ijapa.

 

Owe ati Asayan oro to suyo ninu itan naa.

Ninu itan ogbon ti alabahun gbon, eyin ni yoo maa to igbin’ a ri i pe ijapa ro pe oun ni oun gbon ju, ko tun si elomiran mo, eyi ni o mu un hu iwa omugo ti o hu. Sugbon o mo nigba ti o ya pe igbin, bi o se kere to tun gbon ju ohun lo.

 

IGBELEWON

1.  a. Kin ni oran dida?

b. Daruko orisii oran marun-un ti eeyan le da ati ijiya ti o to fun oran naa.

2.  Pelu apeere salaye iyato ti o wa laarin oro-aponle ati apola-aponle.

APAPO IGBELEWON

 1. Salaye pelu apeere iyato meji to wa laarin oro-aponle ati apola-aponle.
 2. Kin ni oran dida?
 3. Daruko orisii oran marun-un ti eeyan le da ati ijiya ti o to fun oran naa.
 4. Pelu apeere salaye iyato ti o wa laarin oro-aponle ati apola-aponle.
 5. Ko owe meji ki o itan ti o je mo eyo kan.

   

  ISE SISE

 6. Ki ni fonoloji? Pelu apeere.
 7. Ki ni aranmo? Pelu apeere
 8. Ki ni oro ayalo?
 9. Pelu apeere

   

  IWE AKATILEWA

  Eko Ede Yoruba titun – Oyebamiji Mustapha et al. o.i 71 – 75

  Iwe igbaradi fun idanwo asekagba.

   

  ISE ASETILEWA

  1.  ________ ni oro – aponle maa n pon ninju gbolohun (a) or-oruko (b) atokun (d) oro – ise

  2.  Oruko miiran fun alabahun ni (a) eni to ni aba (b) Okere (d) Ijapa

  3.  Apola – aponle je ______ ti o n yan oro–ise ninu gbolohun. (a) eyo oro (b) akojopo oro (d) oro

  4.  Laye atijo oran ti o ba ti mu eni o di dandan ki odaran naa (a) salo (b)fi ilu sile (d) ku

  5.  ________ lo maa n se idajo awon odaran laye atijo (a) Awon oba ati ijoye (b) Awon okunrin (d) gbogbo eniyan

   

  APA KEJI

  1.  a. Kin ni oran dida?

  b. Daruko ohun meji ti o n fa oran dida.

  2.  Pelu apeere salaye iyato to wa laarin oro-aponle ati apola – aponle.

   

   

   

  OSE KEJO

  AAYAN OGBUFO

  Aayan ogbufo ni ise titumo ede kan si ede miiran.

 • Ki ogbufo to le kogo ja ninu itumo ede, o gbodo mo tifun tedo ede Geesi , ki o si le tusu ede Yoruba naa de isale ikoko.
 • Kii se gbogbo oro inu ede kan naa le tumo si ede miiran.
 • A ko gbodo mu gbolohun ni okookan lati tumo, sise bee yoo so ewa ati itumo iru ayoka bee nu.

   

 • A ko gbodo mu oro ni eyo kookan lati tumo, ti a ba se bee yoo so itumo oro ti a fe tu nu.
 • Akaye ati akatunka ayoka se pataki ki o to le se ogbufo to peye. Rii pe o lo akoto to munadoko eyi ni yoo je ki o see ka.
 • Lilo itumo erefee ko bojumu, eyi ko ni fun wa ni itumo ti o kun, itumo ijinle ni o ye ogbufo.
 • O san ki ogbufo lo oruko ti o wa ninu ayoka.

   

  IGBELEWON

  Tumo ayoka isale yii si ede Yoruba

  Yoruba languagesis one of the developing Nigeria languages.

  Many books have been written in Yoruba for Pimary, Secondary and tertiary institutions.

  As Yoruba, it is necessary that we know, not only how to speak the language, but also read it.

 

The knowledge of how to read and write Yoruba, would certainly enable the language to compete with other Nigerian languages.

 

In pursuance of this objective, Yoruba language experts have put in much efforts towards the development of the language.

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 234-254.

 

ASA

IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ASEYIN WAYE ATI AWON ABANI EDA.

 • Itumo aseyinwaye (iye leyin iku)
 • Ohun to mu Yoruba gbagbo pe ajinde n be leyin iku

  AKOONU

Awon Yoruba ni igbagbo ninu iye leyin iku, won gbagbo pe bi eni won ba fi owo rori ku, o le pada wa ya lodo omo re ki won si tun bi. Eyi ni o mu won maa so oruko bii Babawale, Babajide, Iyabode, Yejide. Bakan naa won gbagbo pe eni ti o ba ku ni rewerewe ko le lo si orun taara, kaka bee yoo maa rin kaakiri ni, o si tun le lo si ile ibomiran lati maa gbe, iru awon bee ni a mo si akudaaya. Bakan naa nitori igbagbo ti won ni ninu iye leyin iku ni won se maa n sin owo, ounje ati awon nnkan miiran mo oku laye atijo pe ti oba je ile ibomiran, a le ri owo ati ounje lo lohun-un.

 

Igbagbo awon baba-nla wa nipa abiku tun fi igbagbo ninu iye, leyin iku han, eyi ni o mu ki won maa so omo won loruko bii Malomo, Okoya, Kokumo, Kosoko abbl.

Igbagbo awon baba wa tun han nipa abobaku, ni aye atijo ti oba ba ku, ti won ba maa sin-in pelu Abobaku ni, awon wonyi logbodo ku pelu oba, won gbagbo pe ti oba ba ji si ile ibomiran, ko le ri awon eru ti a maa ran nise.

 

IKINI

Awon Yoruba ni igbagbo ninu iye leyin iku. Eyi si han ninu ikini won lakoko ti oku ba ku . Won a ni iya a ya o. Baba a somo o.

 

IGBELEWON

Pelu apeere salaye Igbagbo awon Yoruba ni pa aseyinwaye ati abani-eda.

 

Litireso KIKA APILEKO TI AJO WAEC/NECO

Iran kejila – Ikeedogun

 

IGBELEWON

Pelu apeere Salaye igbagbo awon Yoruba nipa aseyinwaye.

 

APAPO IGBELEWON

Pelu apeere salaye Igbagbo awon Yoruba ni pa aseyinwaye ati abani-eda.

Ni kukuru, salaye iran kokanla si ekejila.

 

ISE SISE

 1. Ko iwa omoluwabi mewaa sile.
 2. Fun iba isele aterere ni apeere meji
 3. Fun iba isele baraku ni apeere meji
 4. Fun iba isele asetan ni apeere meji

   

  IWE AKATILEWA

  Imo, Ede, asa Ati Litireso Yoruba SS2

  Adewoyin S.Y. O.i 166 -168

  Adakedajo o.i 77 -89

   

  ISE ASETILEWA

  1.  Aseyinwaye tumo si (a)Ati eyin waye (b) Iye leyin iku (d) Atunwa

  2.  ______ ni a n pe eni ti o ku, ti o tun ji si ile ibomiran (a) Akudaaye (b) eni ti o ye leyin iku (d) atunbi

  3.  Igbagb aseyin-waye han nibi afi (a)isomoloruko (b) Ikini nibi oku (d) Oye idile jije

  4.  Elo ni Aremu san fun owo emu? (a) Egberun meji (b)meta (d)merin.

  5.  Aremu lo owo ti o ba Kanmi paaro fun (a) Isomoloruko (b) Isinku (d) Oye

   

  APA KEJI

  1.  a. Kin ni aseyinwaye?

  b. Nje awon Yoruba gbagbo ninu aseyinwaye? Salaye re lekun-un-rere.

  2.  Salaye lekun-un rere ohun ti o sele si Kanmi nigba ti o lo beere owo re lodo Aremu.

   

   

   

  OSE KESAN-AN

  AKAYE

  Akoonu

Eka pataki ni akaye je ninu ede Yoruba. Akaye gba suuru lati ka, o gba iyosira ati amodaju awon koko-oro ti ibeere ba da le lori.

Ayoka oloro wuuru

Ayoka le je ewi

Ayoka le je asotan

Ayoka le je alariyanjiyan

Ifokan-ba-ayoka lo ti aba n kaa se pataki. Eyi ko ni je ki a fi ojo pe ojo ninu idahun si awon ibeere ti won ba gbe ka iwaju wa.

Ohun ti a nilati se lati kogo ja ninu akaye. Koko ka ayoka wa daadaa lati mo ero onkowe. Se akiyesi awon ona ede inu ayoka ati itumo won ni ibamu pelu bi onkowe se loo. Tun akaye wa ka pesepese ki a to dahun awon ibeere ti o tele akaye.

 

IGBELEWON

Ka akaye isale yii ki o si dahun ibeere ti o tele e.

Ni owuro ojo Satide, Akanni, Arije ati Alamu gbera lati abule nla, won fori le aba Adubi. Bi won ti de ibe, won wonu oko Raimi won si bere si sise laiweyin. Ki o to di ojo yii, won ti base lo bi ile bi eni.

Yoruba bo won ni oosa bi ona ofun ko si ojoojumo nii gbebo lowo eni.

Akanni ni o koko logun pe maanu n fagi. Oloko ko pese ohun ipanu gege bi adehun re. Ibi ti won ti n ronu ohun ti won yoo se ni Raimi de. Iyalenu ni o si je fun un nigba ti won bere si so kobakungbe oro si. O ranti pe oun fi ounje ranse si awon alagbase yii ni nnkan bi wakati merin sehin. Bi o ti n salaye pe oun ko gbagbe won ni omo re Foluso to fi ounje ran si won de pelu omije loju. Ase ohun to fa sababi ni pe ounje danu loju ona. Wiwa ti o way ii lo je ki oro lojutu lojo naa.

 

1. “Maanu n faagi ti a fala si tumo si (a) Aare mu won (b)

2. Wiwa ti o wa yii lo je ki oro loju tuu. Ta ni o n tokasi?

3. Ta ni oloko?

4. Oko wo ni awon alagbase yii ti n sise?

5. Ojo wo ni won lo sise agbase yii?

 

ASA

EEWO

EEWO

Eewo je ohun ti a ko gbodo se rara, awon Yoruba si gbagbo pe ti a ba se awon nnkan wonyi tabi ti a ba dejaa nnkan buruku le sele.

Eewo ni ohun ti a agba ni ile Yoruba pe eniyan ko gbodo se, bi eniyan ba si dejaa yoo jiya re. A da eewo sile lati le ko awon omode ni iwa imototo, omoluwabi, ibowofagba ati igbe laruge ASA wa.

A le pin eewo ile Yoruba si awon isori wonyi:-

 • Eewo ikilo / ikonilogbon
 • Eewo iderubani
 • Eewo ti o je mo eri okan tabi ikora eni ni ijanu
 • Eewo idile
 • Eewo ilu
 • Eewo esin
 • Eewo fun ibagbepo eda

  Eewo ikilo: Eyi ni eewo ti a gbe kale lati fi kilo tabi lati fi ko ni logbon. Apeere:

  –  Aboyun ko gbodo rin ni osan tabi ni oru ganjo

  –  A ko gbodo fi igi owo dana

  –  Omode ko gbodo fi owo gbe ojo

  Eewo Iderubani: Ni a maa n lo tabi deruba omode. Apeere:

  –  Omode ko gbodo to si aarin aaro ki iya re ma baa ku

  –  Omode ko gbodo jokoo si eti odo

  –  Omode ko gbodo jokoo si enu ona nigba ti ojo ba n ro

  –  A ko gbodo soro nigba ti a ba n jeun.

  Eewo ti o je mo eri okan

 • Ode ko gbodo ba iyawo egbe re se nnkan papo
 • Babalawo ko gbodo gba iyawo babalawo lati dekun iwa odale

  Eewo esin

 • Obatala ko gbodo mu emu ope
 • Onisango ko gbodo mu siga, je sese
 • A kii fi adi ko esu. Eni ti o ba dejaa yoo ri ija orisa re

  Eewo Idile/orile: Eyi ni eewo ti o je mo idile kookan. Apeere

 • Iran onikoyi ko gbodo je eran okete ati eran oore

  Eewo Aisan

 • Eni ti warapa ba n se ko gbodo duro si ibi ti ariwo ba tip o.
 • Eni aromolegun ba n se ko gbodo fo egungun eran ki ara riro re ma baa po sii

  Eewo fun Ibagbepo

  A kii toju elese mesan-an kaa ki ija ma baa sele

   

  LITIRESO

  Kikai we Litireso

   

  IGBELEWON

  1.  a. Ki n ni eewo?

  b. Daruko orisii eewo ti o wa

  2.  a. Salaye ohun ti eewo aisan je

  b. Kin ni anfaani eewo aisan

   

  APAPO IGBELEWON

  1.  a. Ki n ni eewo?

  b. Daruko orisii eewo ti o wa

  2.  a. Salaye ohun ti eewo aisan je

  b. Kin ni anfaani eewo aisan

  3. Awon igbese marun-un wo ni eeyan maa n gbe ki o to le dahun akaye

   

  ISE SISE

  Ko
  aroko oniroyin kan.

   

  IWE AKATILEWA

  Imo Ede, asa ati Litireso Yoruba SS2

  Adewoyin S.Y o.i 169 – 174.

  Adakedajo

   

  ISE AMURELE

  1. ______ ni o maa n tele ayoka (a) akonlo-ede (b) Ibeere (d) owe

  2. Ohun ti a ko gbodo se rara ni a n pe ni ___________ (a) Aise (b) eewo (d) Agbedo

  3. Oniwarapa ko gbodo _________ (a) je epo (b) ja (d) duro si ibi ti eeyan ba po ati ibi ti ariwo ba wa.

  4. Onikoyi ko gbodo je okete tabi eran oore je eewo (a) Idile (b) Ikilo (d) Igbe aye alaafia

  5. Idi ti o fi je eewo fun aboyun lati rin ni oru-ganjo tabi inu oorun ki (a) oyin re ma baa baje (b) abami omo ma baa ko wo o ninu. (d) o ma baa bimo dud fafa

   

  APA KEJI

  1.  a. Kin ni eewo?

  b. Daruko orisii eewo ti o wa

  2.  a. Kin ni eewo aisan?

  b. Kin ni anfaani eewo aisan.

 

 

 

OSE KEWAA

ORO-ORUKO

– oriki

– orisiirisii oro oruko.

– ise ti oro oruko n se ninu gbolohun.

– lilo oro oruko ninu gbolohun.

AKOONU : –

Oro –oruko ni awon oro ti won le da duro nipo oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun. AP.

 Baba ko ebe.

 Tolu fo aso.

 Mama se isu ewura.

EYA ORO ORUKO/ORISII ORO ORUKO.

 1. ORUKO ENIYAN : -Oro oruko le je oruko eniyan, eyi ni oruko ti o n toka si ohun ti o je mo eniyan. Ap

  -Rotimi

  – Dele

  -Ahmed

  – Dokita

  – Iyalaje…abbl

  2. ORO-ORUKO ALAISEEYAN: -Eyi ni oruko to n toka si awon nnkan ti kii se eniyan AP.okuta,iwe, ewure,omi,iyanrin,bata abbl.

  3.  Oro-oruko le je ohun Elemi : – Eyi je oruko nnkan ti won ni emi bii eniyan tabi eranko.apaja,eniyan,esin,maalu,alangba,okunrin.abbl.

  4.   Oro-oruko le je ohun Alailemii: – Eyi ni awon nkan ti ko ni emi.ap iwe,ile,bata,ewe,igi,abbl.

  5.   Oro-oruko le je ohun Aridimu : – Eyi ni awon ohun ti a le fi oju ri tabi fi owo kan.apewa,eja,isu,tabili,sokoto,aga,ewedu,abbl.

  6.  Oro-oruko le je oruko Ibikan :- Eyi ni awon oro oruko ti a le fi ibo se ibeere won.Ap ibo lo n lo? Osodi,Meka,Soosi.

  7.   Oro-oruko le je ohun Afoyemo : – Eyi ni awon ohun ti a ko le fojuri sugbon ti a le mo nip aero opolo.Ap ogbon,ilera,ero,ife,alaafia,igbadun,wahala,imo.

  8.   Oro-oruko le je Aseeka : – Eyi ni o n toka si ohun ti a le ka Ap. Ile,ilu,eniyan,iwe,tatapupu.

  9.   Oro-oruko le je Alaiseeka : – Eyi ni o n tokasi awon ohun ti koseeka Ap Iyanrin,epo,omi,afefe,gaari,irun.

  10.   Oro-oruko le je oruko Igba : – Eyi ni oro ti a le lo lati toka si igba ti nnkan sele han.Ap Aaro,ana,odun,irole,oni,ola,ijeta.

   

  IGBELEWON

 2. Ko eya oruko mewaa sile.
 3. Fun marun-un ni apeere mejimeji.

   

  ISE TI ORO-ORUKO N SE NINU GBOLOHUN

  Ona meta pataki ni a le gba lo oro-oruko ninu gbolohun, o le sise:

  i.Oluwa,

  ii. abo

  iii. eyan.

  OLUWA: ni eni tabi ohun ti o se nnkan ninu gbolohun. ap

  Baba ko ebe.

  Bola fo aso.

   

  ABO: ni eni tabi ohun ti a se nnkan si,ap

  Mama n se obe

  Bolu ko leta.

   

  EYAN: ni o maa n se afikun itunmo fun oro-orukoap

  Mama se obe eja yiyan.

   

  IGBELEWON

 4. Ko ise oro oruko ninu gbolohun sile ki o si fun ni apeere mmetameta.
 5. Bola se isu ewura.

   

  Ona miiran ti a tun le gba da oro oruko mo ni pe

  Oro-oruko maa n gba oro aropo bii eyan, ap:

  ‘oro yin ni a sese so tan yii.’

  ‘ile re ni mo n lo.’

  Oro-oruko le see lo fun sise akiyesi alatenumo ti a ba gbe saaju wunren ‘ni’ap

  ‘iwe ni mo ra.’

  Rira ni mo ra iwe yii.

   

  ORO AROPO ORUKO.

 • Oriki
 • Abuda oro aropo oruko
 • Ate oro aropo oruko
 • Irisi oro aropo oruko.

   

  AKOONU

Oro aropo oruko ni a maa n lo dipo oro-oruko ninu apola oruko.apeere

 ‘Bolu je akara.

 ‘O je e.’

 ‘ewure je agbado Bola’

 ‘ewure je agbado re.

 

Abuda Oro Aropo Oruko.

1. Oro aropo oruko ni eto to n toka si iye bi eyo tabi opo.apeere

O lo [ eyo ni o ]

Won wa [ opo ni won]

 1. oro aropo oruko ni eto to n toka si eni.apeere.

  enikinni /eyi ni eni ti o n soro.

  Enikeji / eyi ni eni ti a n soro sii.

  Eniketa / eyi ni eni tabi ohun ti a n soro re.

   Mo ko leta.

   O ko leta

   O ko leta.

  2. Oro aropo oruko ni eto ipin si ipo.

   
   

    IYE
  Eyo  Opo

  Enikin-in-ni mo  a

  Enikeji o  e

  Eniketa o  won.

   

  3. A ko le fi oro-asopo so oro aropo oruko meji papo.apeere

  mo ati o

wa ati won.

 

4. A ko le lo oro aropo oruko pelu da ati nko,ni,ko.apeere

mo n ko?

E da?

O ko?

5. A ko le lo eyan pelu oro aropo oruko.apeere

 mo naa

 e gan-an

 

IGBELEWON

1.  Kin ni oro aropo oruko?

 1. Salaye isori oro aropo oruko mejo pelu apeere.
 2. Salaye abuda oro aropo oruko.

  IRISI ORO AROPO – ORUKO.

  Ona meta Pataki ni a le gba lo oro aropo oruko ninu gbolohun.

 • O le sise oluwa
 • Abo
 • Eyan ninu gbolohun.

  Image From EcoleBooks.comIpo oluwa; – oro aropo oruko maa n sise oluwa ninu gbolohun,

  Image From EcoleBooks.comImage From EcoleBooks.comENI EYO OPO.

  Image From EcoleBooks.comEnikin-ni  mo a

  Image From EcoleBooks.comEnikeji  o e

  Image From EcoleBooks.comEniketa  o won

  Apeere;-mo n jo

  O n jo

  Won n jo

  E n jo

  A n jo.

  Ipo abo : – oro aropo oruko maa n sise abo bakan naa ninu gbolohun.

  Image From EcoleBooks.comImage From EcoleBooks.comImage From EcoleBooks.com

  Eni  Eyo Opo.

  Image From EcoleBooks.comImage From EcoleBooks.comEnikin-in mi wa

  Enikeji o/e yin

  Image From EcoleBooks.com Eniketa fifa oro ise gun  won

   

  Oro-ise.

  Baba na mi.

  Bolu n pe o/e

  Oluko pe e.

  Oba ri wa.

  Ipo eyan : -oro aropo oruko maa n ni ipo eyan ninu gbolohun.

  Image From EcoleBooks.comImage From EcoleBooks.comImage From EcoleBooks.com

  Image From EcoleBooks.comENI EYO OPO.

  Image From EcoleBooks.comEnikin-ni mi wa

  Enikeji re/e yi

  Image From EcoleBooks.comEniketa re/e won.

  Apeere; –

  Aja mi

  Aja re

  Aja re

  Ile wa

  Aso yin

  Aja won.

   

  Oro – Ise

   

  ASA

  Ori-oro:- Oruko Ile Yoruba

  Akoonu

Oruko se pataki ni ile Yoruba, awon Yoruba kii si deede fun omo ni oruko, awon oruko Yoruba maa n ni itumo. Idi niyi ti awon agba fi maa n se akiyesi ipo ti omo ba gba waye, Ipo ti ebi wa, esin idile baba ki won to fun omo ni oruko, Yoruba ni ile laawo ki a to so omo ni oruko.

Eyi ni orisii oruko ti a ni ni ile Yoruba.

 1. Oruko amutorunwa
 2. ii. Oruko abiku

  iii. Oruko Inagije

  iv. Oruko abiso

Oruko amutorunwa:- ni oruko ti a fun omo nipa sise akiyesi ona ara ti o gba wa si aye tabi isesi re nigba ti a bii.

Ap

Oruko amutorunwa:-

Ige Omo ti o mu ese waye

Aina  Omobinrin ti o gbe ibi korun.

Ojo  Omokunrin ti o gbe ibi korun.

Oke  Omo ti o di ara re sinu apo ibi wa si aye epo tutu ni won ma

anta si ara apo naa, ki o to le tun

Oke  Omo ti o maa n daku ti won ba n fun ni ounje ni idubule.

Dada  Omo ti irun ori re ta koko.

Ilori  Omo ti iya re ko se nnkan osu ti o fi loyun

Oni  Omo ti won bi sile to n kigbe laisinmi

Babarinsa Omo ti baba re ku ni kete ti won bii.

Abiona  

Oruko abiku: Oruko ti a fun omo ti o maa n ku, ti a sit un pada wa saye.

Won maa n fun won ni oruko bii ebe tabi epe ki won le duro.ap

Oruko  Itumo

Durojaye  –  Ki o duro ni ile aye je igbadun

Rotimi –  Duro ti mi, ma se fi mi sile.

Malomo  –  Duro si aye, ma pada si orun mo

Kosoko  –  Ko si oko ti a o fi sin oku re mo

Kasimaawoo  –  Ki a si maa wo boya yoo tun ku tabi ye.

Bamitale  –  Duro ti mi di ojo ale

Aja –  Iwo ko ye ni eni ti a le fun ni oruko eniyan mo afi aja.

 

Oruko Inagije:- oruko atowoda ti a fi eniyan tabi ti eeyan fun ara re lati fi se aponle tabi apejuwe irisi tabi iwa re ap.

Eyinafe: Eni tie yin re funfun ti o si gbafe.

Ajisafe: Eni to feran afe ni owuro ti gbogbo eeyan ba n sise

Peleyeju: Eni to ko ila pele, ti ila oju naa si ye e gan-an.

Oginni: Eni ti o maa n roar n tele ginniginni.

 

Oruko Abiso: eyi ni awon oruko ti o n toka si ipo idile tabi obi omo saaju tabi asiko ti a bi.

Apeere oruko to n tokasi ipo tabi esin idile.

 

Ipo  Oruko abiso

Oba  Adebisi, Adegorite, Adegoroye, Adesoji, Adegbite, Adeyefa.

Eleegun Ojewunmi, Ojeniyi, Eegunjo bi

Jagunjagun Akintola, Akinkunmi, Akindele

Onisona Onajide, Olonade

Elesin Ifa Fayemi, Faleye, Awobiyi, Awotunde

Onisango Sangobunmi, Sangodele

Orisa Oko/Idobatala  Efunjoke, Opakunle, Soyinka.

Orisa Ogun Ogunyemi, Ogunbiyi, Odetola.

Oruko to n tokasi ipo obi saaju tabi ni akoko ti won bii.

 

Oruko Itumo

Ekundayo Ibanuje ati ekun ti o wa ninu ebi di ayo.

Olabode Ola to ti lo ninu ebi tun ti pada de.

Tokunbo  Omo ti won bi si Ilu oyinbo tabi ile okeere ti won gbe wa ile.

 

IGBELEWON

1.  a. Kin ni Oruko?

b. Daruko orisii oruko ti o wa.

 

LITERESO

Ori-oro: Sise itupale iwe ti a ka

– Eko ti a ri ko.

asa Yoruba ti o je jade

Awon eda itan.

 

IGBELEWON

1. Salaye awon oruko amutorunwa wonyi.

i. Dada

ii. Oke

iii. Ilori

iv. Aina

 

2. Salaye awon isori-oro wonyi pelu apeere.

i. oro-oruko

ii. oro – ise

 

APAPO IGBELEWON

 1. Pelu apeere salaye Igbagbo awon Yoruba ni pa aseyinwaye ati abani-eda.

  Ni kukuru, salaye iran kokanla si ekejila.

   

  ISE SISE

 2. Ko oruko amutorunwa merin]
 3. Salaye awon iro yii g, t, s, b, f ati j.

   

  IWE AKATILEWA

 4. Imo, Ede ASA ati Litireso Yor. SS2 o.i 34, 37, 18, 20

   

  ISE ASETILEWA

 5. O je oro aropo oruko (a) enikninni eyo (b) enikeji opo (d) eniketa eyo
 6. Aja je apeere oruko ____ (a) abiku (b) amutorunwa (d) Inagije
 7. Omo ti won bi sile ti o n kigbe laisinmi ni _____ (a) ojo (b) oni (d) oke
 8. E row a ro ire, oro-ise inu gbolohun yii ni ____ (a)agbabo (b)Asapejuwe (d)alapedada
 9. Okan lara asa Yoruba ti o je yo ninu iwe Adakedajo _____ (a) Igbeyawo (b) Isomoloruko (d) oye jije

   

  APA KEJI

 10. Salaye isori oro-oruko marun un, oro-ise pelu apeere mejimeji fun ikookan.
 11. a. Kin ni oruko?

  b. Daruko orisii oruko ti o wa pelu apesere meji meji fun ikookan.
Share this:


EcoleBooks | 1ST TERM SS3 YORUBA SCHEME OF WORK AND NOTE

subscriber

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Accept Our Privacy Terms.*