Share this:

ILANA ISE SAA KIN-IN-NI

 

ISE: EDE YORUBA KILAASI: JSS2

 

ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KIN-IN-NI

1  EDE:  Sise atunyewo fonoloji ede Yoruba.

 ASA: Atunyewo awon asa to jeyo ninu ise olodun kin-in-ni

 LIT: Atunyewo awon ewi alohun Yoruba to yo ninu ise odun kin-in-ni

2  EDE: Gbolohun onibo (oriki pelu apeere)

ASA: Asa igbeyawo nile Yoruba (eto igbeyawo) ifojusode,iwadi abbl Pataki

ibale

 LIT:  Kika iwe apileko oloro geere ti ijoba yan.

3  EDE: Gbolohun onibo-Eya gbolohun onibo gbolohun onibo apejuwe,

asaponle,asodoruko

 LIT:  Kika iwe apilleko oloro geere ti ijoba yan.

ecolebooks.com

 ASA:  Igbeyawo aye ode oni.

4  EDE: Pinpin gbolohun onibo si olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe

 ASA: Igbeyawo sise. Afiwe igbeyawo abinibi ati ode oni.

 LIT: Litireso alohun to je mo aseye: ekun iyawo (itumo, adugbo ati pataki

ekun iyawo.

5  EDE: Onka Yoruba (100-300).

 ASA: Itoju oyun-igbagbo Yoruba nipa agan (awon ohun to le dena omo bibi)

 LIT: Litireso alohun to je mo ayeye; bolojo,Alamo, (itumo, adugbo ayeye ati

ohun awon wonyi)

6  EDE:  Onka Yoruba (300-500).

 LIT:  Kika iwe apileko ti ijoba yan.

7  EDE: Akaye oloro geere (itonisona lori akaye oloro geere).

 ASA: Igbagbo Yoruba nipa abiku ati ona ti a n gba dekun abiku

 LIT: Kika iwe apileko ti ijoba yan.

8  EDE: Akaye oloro geere (yiyan ayoka fun akekoo)

 ASA: Omo bibi, eewo ati oro idile ebi baba omo

 LIT: Litireso alohun; oriki (itumo oriki pataki oriki eya oriki).

9  EDE:  Akoto (sise itokasi ipinu ijoba apapo lori akoto (1974).

 ASA: Isomoloruko– (Awon ohun elo isomoloruko, ilo won)

 LIT: Eya oriki (oriki abiso,borokini,orile)

10  EDE: Kiko Yoruba ni ilana akoto ode oni (b.a Sagamu,Ebute meta)

 ASA: Orisirisii oruko ile Yoruba(abiso, amutorunwa, abiku, oriki)

11&12  ATUNYEWO ISE SAA ATI IDANWO.

 

 

IWE ITOKASI

 • S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba iwe kin-in-ni [J s s1] Corpromutt Publishers
 • Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji Longman Nig.
 • Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun Iwe keji University Plc
 • Ayo Bamgbose (1990) Fonoloji ati Girama Yoruba University Press Ltd.

 

 

OSE KIN-IN-NI

ORI ISE: Atunyewo fonoloji ede Yoruba

AKOONU:

Fonoloji tumo si eto bi a se n sin awon iro kookan po di oro ninu ede Yoruba. Awon iro to se pataki ninu ede Yoruba ni iro faweeli, iro konsonanti ati iro ami ohun.

 

 1. IRO FAWELI

Ona meji ni a pin iro faweli si, awon ni faweeli aranmupe ati airanmupe.

 

Faweeli Airanmupe ni:

AKOTO  FONETIKI

 a a

 e e

 e

 i i

 o o

 o ↄ

 u u

 

Faweli aranmupe:-

Akoto Fonetiiki

 an a

 e ԑ

 i i

 o ↄ

 u u

Bi a ba fe se apejuwe iro faweli, a ni lati kiyesi ipo ti ahon wa ninu enu, boya a ranmu tabi a ko ranmu pe e, bi ete se ri lasiko ti a pe e ati bi ahon se lo si iwaju tabi seyin.

 

 1. IRO KONSONANTI

Iro miiran to tun se koko ninu èdè Yoruba ni iro konsonanti. Mejidinlogun (18) ni iro konsonanti, Awon ni:-

AKOTO  b d f g gb h j k l m n p r s s t w y

FONETIKI  bd f g gb h dz k l m n kp r s s t w y

Bi a ba fe se apejuwe awon iro konsonnati, a gbodo kiyesi boya iro akunyun tabi iro aikunyun ni. Ninu akoto ode oni konsonanti meji ko le da duro tabi ko tele ara won ninu oro.

 

 1. IRO OHUN

Orisii iro ohun keta ti a ni ninu ede Yoruba ni iro ohun. Iro ohun ni o maa n se iyato laarin oro ti won ba ni faweli ati iro konsonanti kan naa. Awon iro ohun ti a ni niwonyi:-

 Iro ohun oke ( / )

 Iro ohun aarin ( – )

 Iro ohun isale ( \ )

 

Awon iro meteeta to se Pataki yii ni a n pe ni foniimu. FonIiro aseyato ninu oro. Apeere:-

 Aja

 Aja

 Aja

 

Ori iro faweli ati konsonanti “n ati m” nikan ni a maa n fi ami ohun le lori.

IRO KONSONANTI ATI FAWELI

Ada  aja  apa  ara  ala  agba  aba  aya

Ede  ade  epe  ere  ele  egbe  ebe  aye

Ese  epe  ete  efe  eye  eke  ere  ede

Idi  iti  iyi  iri  igi  ika  ide  ire

Odo  oyun  oku  okun  osun  ori  osi  ose

Omo  oko  oto  opo  oso  ofe  ope  oke

 

PE AWON ORO YII

Adaba  oginlinti  ajapa  alade  alakori  oronbo

Iwonyi  ofin amebo akunyun  aikunyun

Konkoso  pongila  sogigun  sakatapara  aganrandi

Irere  alabahun  tafatafa  jagunjagun  atamatase

Iwerende  tonbolo  okodoro  gbagede  aamebo.

 

IGBELEWON

 1. Ki ni a n pe ni fonoloji?
 2. Awon iro meta wo lo se Pataki ninu ede Yoruba?
 3. Ona meloo ni a pin iro faweeli si?
 4. Orisii ami ohun meloo ni a ni ninu ede Yoruba?
 5. Ki ni a n pe ni foniimu?

 

IWE AKATILEWA

 1. S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba L1 (JS1) Copromutt Pubisher Oju iwe 50-53

2. Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji University

Press Ltd Oju iwe 1-6

 

ATUNYEWO ASA

AKOONU:

 • KINI A N PE NI ASA
 • ORISIIRISII ASA YORUBA

Nigba ti a ba menu ba asa awon eniyan kan, ohun ti a ni lokan ni iwa ati isesi awon eniyan naa. Ki i se iwa enikan soso ni a n toka si gege bi asa awon eniyan naa bi ko se iwa ajumohu. Iwa ajumohu le je mo bi won se n wo aso, ise ti won se, ounje ti won n je, esin won, iwa omoluabi, isinku ati oge sise. Ede je okan pataki ninu asa awon eniyan bee.

 

Ki i se awon nnkan wonyii nikan ni a le pe ni asa won. Bakan naa ni a le pe eewo, eto oselu ati owe ti awon eniyan naa maa n pa si asa won.

 

Orisirisi asa ni a ni ni ile Yoruba to n fi iwa ati isesi awa Yoruba han awon asa yii po lo sua bi ola Olorun. Ni opo igba ni awon agbalagba maa n so pe awon omode n ko asakasa. Eyi nipe iru awon omo bee n huwa ti ko ba ti awon eniyan re mu, iyen ni pe asa ti ko ba je teni ti ko ba iwa awon eniyan mu ni won n pe ni asakasa. Eyi ni pe asa ti ko dara.

 

Ni kukuru iwa ati isesi awa Yoruba ni a n pe ni asa Yoruba. Orisirisi asa ni a ni ni ile Yoruba, die lara won ni

 • Isomoloruko
 • Isile
 • Oye jije
 • Isinku
 • Ila kiko
 • Aso wiwo
 • Eto oselu
 • Eewo kika
 • Ogun jija
 • Asa ikini
 • Oge sise

   

ASA IKINI

Asa ikini je okan pataki ti a fi maa n da eya Yoruba mo laarin gbogbo eya ti o ku. Lati kekere ni imole ti n ko omo re laso, bee gege ni oro asa ikini je laarin awon Yoruba. Lati kekere ni won ti n ko omo ni orisiirisii ona ti a n gba ki ni nile Yoruba. Gbogbo akoko ni o ni bi a se n ki ni nile Yoruba. Ko si igba ti e ki i ki eniyan yala aaro, osan tabi ale koda a maa n ki eni ti o n sun lowo (asunji). Bee ni a ni orisii ikini fun igba kookan ninu odun bi igba ojo, oye, otutu, oginlintin. abbl.

 

Nile Yoruba, omokunrin maa n dobale ki eniyan ni ngba ti omobinrin maa n fi orunkun mejeeji kunle lati ki eniyan.

 

OGE SISE

‘ B’afinju w’oja, won a rin gbendeke, obun w’oja pa siosio’ … aajo ewa ni oge sise je. Awon Yoruba je eya ti o faari pupo, won a maa wo aso to ba ara won mu. Ti o sit un ba ohun ti won n se lowo mu. Won a maa se itoju ara won lopolopo beeni won ki i fi itoju ayika won fale rara. A le so pe ma rin doti ni awon Yoruba. O je asa won ati ise won ni gbogbo igba lati tun ara ati ayoka won se ni ona ti yoo fi se e ri. Awon Yoruba ko fi owo yepere mu oge sise.

 

Die lara awon ona ti a n gba se oge nile Yoruba ni: itoju ara: iwe wiwe, enu fifo, tiroo lile abbl. Itoju ayika: ile gbigba, oko riro, fifo gota abbl

 

IGBELEWON

1.  Ki ni a n pe ni asa?

2.  Ko asa Yoruba marun-un sile.

 

IWE AKATILEWA

Oyebamji Mustapha (2015) Eko Ede Yoruba Titun iwe kin-in-ni University Press Ibd. oju iwe 153-178

 

AKORI ISE:ATUNYEWO EWI ALOHUN

AKOONU

 • Eya litireso atenudenu
 • Awon ewi to je mo ayeye
 • Awon ewi to je mo esin

Eka meta pataki ni litireso atenudenu pin si. Awon eka meta naa ni ere onise, ewi ati oloro geere. Awon eya ewi alohun po to bee ti a ko le ka won tan. Gbogbo awon eya Yoruba lo ni orisirisii ewi atenudenu ni agbegbe won, sugbon awon kan wa to je pe gbogbo eya Yoruba lo n lo won. Die lara won ni ofo, rara, ijala, ekun-iyawo, iyere, ifa, oriki ati bee bee lo. Awon miiran wa to je pe adugbo kan ni a ti maa n ba won pade apeere bee ni olele, orin etiyeri, efe,bolojo, dadakuada ati bee bee lo.

Awon ewi alohun to je mo ayeye ni:-

 • Ekun-iyawo
 • Dadakuada
 • Obitun
 • Oku pipe
 • Efe
 • Ege
 • Orin apepe ati bee bee lo.

 

Awon ewi alohun to je mo esin abalaye ni:

 • Esu pipe
 • Oya pipe
 • Ijala.
 • Orin oro
 • Iwi eegun ati bee bee lo.

 

IGBELEWON

1.  Daruko litireso atenudenu merin

2.  So meta ninu ewi to je mo ayeye

3.  Daruko meji ninu ewi to je mo esin

 

IWE AKATILEWA

 1. Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe Kin-in-ni. Longman Publisher O ju iwe 64-65
 2. S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba L1 Book 1 Copromutt Publisher Oju Iwe 75-76

 

ASETILEWA

 1. …. ni iro aseyato (a) foniimu (b) iro (d) faweeli.
 2. A pin faweeli si faweeli airanmupe ati faweeli …… (a) iro ohun (b) aseyato (d) aranmupe
 3. Ami ohun ti a ni ninu ede Yoruba ni ami ohun oke, isale ati … (a) egbe (b) ikoko (d) aarin
 4. Ewo ni ki i se asa Yoruba nihin-in? (a) igbeyawo (b) isomoloruko (d) isile (e) ariwo pipa
 5. Ewo ni ki i se ewi atenudenu ayeye nihin-in? (a) rara (b) iyere (d) orin etiyeri.

 

APA KEJI

1 Ko apeere ewi alohun/atenudenu esin abalaye marun un sile.

2 Se alaye die lori asa ikini ati asa oge sise nile Yoruba.

 

 

OSE KEJI

EDE GBOLOHUN ONIBO

AKOONU

 • Oriki gbolohun onibo
 • Apeere atoka/wuren gbolohun onibo
 • Apeere gbolohun

Ni opo igba a maa n pe gbolohun onibo ni gbolohun olopo oro ise tabi gbolohun alakanpo.Gbolohun onibo ni eyi ti a fi gbolohun kan ha ihun omiiran. Irufe gboloun yii maa n ni ju eya kan lo. Atoka/wuren gbolohun onibo ni: ti, ki,iba,ni,pe,nigba,bi.Fun apeere.

 O gba ile ti mo ra

 E gbodo so fun mi ki e to wa

 A o jo lo bi e ba de

 Iba se pe mo lowo, n ba ra moto

 Kani e tete de ni,e ba ba won

 Gbogbo ilu gbo pe oba waja

 

IGBELEWON

Fa ila si idi gbolohun onibo nihin

 1. O dara pe mo ra iwe
 2. A gbodo lo bi ojo baro
 3. Ibaje je pe mo lowo n ba kole
 4. Awon obinrin ti o mo
 5. Omobinrin yen le pada bi o ba fe

 

IWE AKATILEWA

AyoBamgbose (1990) Fonoloji ati Girama Yoruba University Press Ltd oju iwe 192-200


ETO IGBEYAWO ABINIBI

AKOONU

 • IFOJUSODE
 • ALARINA
 • IJOHEN/ISIHUN
 • ITOORO
 • IDANA

ASA IGBEYAWO ATIJO (IBILE)

IGBESE IGBEYAWO ALAYE

Ifojusode Awon obi okunrin yoo maa fi oju sile wa obinrin.

Iwadii Won yoo se iwadii idile obinrin naa ni aarin ilu. Won yoo tun se,

Iwadi lowo ifa.

Alarina Alarina ni won yoo maa rann si ara won( oko ati Iyawo afesona), Boko

ba moju aya

Tan, alarina a yeba.

Isihun/ijohen Gbigba ti obinrin gba lati fe okunrin.

Itoro Awon ebi okunrin yoo wa toro omobinrin ni owo obi re.

Baba gbo, iya Awon ebi mejeeji gbo, won si gba pe ki obinrin ati okunrin feragbo

Idana Ebi oko yoo gbe eru idana lo fun ebi omobinrin ti ojo igbeyawo won

Ba ku feere.Isu ogoji, orogbo ogoji, obi ogoji.

Ifa iyawo Baba iyawo yoo difa ni aaro ojo igbeyawo lati mo ile oko naa yoo se

Ri boya yoo san sowo somo.

Ojo igbeyawo Ale ni awon ebi ati ore iyawo yoo ba a palemo, won yoo sin iyawo lo

Si ile oko pelu orin ati ijo titi yoo fi de enu ona oko re.

Ese iyawo Ni enu ona abawole won yoo fi omi we ese iyawo naa.

wiwe

Ibale Ti iyawo ko ba ti i mo okunrin kan ri, ti oko re ba a nile, oko yoo gbe

ekun agbe emu tabi ile isana kikun ranse si obi iyawo pelu owo ibale.

 

IGBELEWON

1.  Ki ni a n pe ni ifojusode ninu eto igbeyawo abinibi

2.  Se alaye ise alarena

3.  Kini ijohen tabi isihun tumo si?

4.  Kini iyato laarin itoro ati idana?

 

IWE AKATILEWA

1. Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji Longman Nig oju iwe114-118

2. Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun (J S S 2) iwe keji University Presss oju iwe 85 92

 

ISE ASETILEWA

1 Gbolohun ti a fi ihun re ha omiiran ni golohun…. (a) ase (b) onibo (d) afibo

2 Ki je atoka gbolohun ……(a) olori (b) onibo (d) afibo.

3.  Awon wo lo maa n se itoro omo? (a) idile iyawo (b) idile oko (d) idile iyawo ati oko

4.  Ise alarina ni lati maa ……….(a)se oju fun iyawo lodo baba oko (b) se atunse laarin oko ati iyawo  (d) Soju oko lodo baba iyawo

5.  Gbogbo ohun ti a n san lori iyawo ti a fe fe ni a n pe ni ……….. (a) Owo igbeyawo  

(b) Owo ijohen  (d) owo ori

 

APA KEJI

1.  Kini a n pe ni idana ninu eto igbeyawo nile Yoruba

2.  Kini ijohen, lati odo tani ijohen ti n wa?

3 Toka si gbolohun onibo nihin-in

 • Gbogbo ilu gbo pe oba waja
 • Bade ka iwe ki o le yege
 • N o ni lo kani mo mo
 • Mo ti lo ki ore mi to de
 • Akekoo naa mura ki o le gbebun

 

 

OSE KETA

EDE AWE GBOLOHUN

Awe gbolohun ni apakan odindi gbolohun. Awe gbolohun pin si orisii meji. Awon naa ni awe gbolohun afarahe ati olori awe gbolohun.

Olori Awe Gbolohun: Olori awe gbolohun ni abala apakan odindi gbolohun ti o le da duro pelu itumo. Fun apeere.

 • Mo ti lo ki ore mi de
 • Gbogbo ilu gbo pe oba waja
 • Akekoo naa mura ki o le gbebun

Awe Gbolohun Afarahe: Awe gbolohun afarahe je awe gbolohun ti ko le da duro pelu itumo. Omaa n fara he olori awe gbolohun ni. Fun apeere.

 • Ore mi ti o lo si Eko ti de
 • Mo ti lo ki ore mi to de
 • Mo we nigba ti mo setan
 • Awon eniyan mo pe ounje won.

   

IGBELEWON

1. Toka si olori awe gbolohun nihin-in

 • Maa jeun bi mo ba se tan
 • Bisi a ti lo ki o to de
 • Ounje yii dun bi I pe ki n je tan

2. Tokasi awe gbolohun afarahe ninu awon oro wonyi

 • Oluko ri Dada ni oko oloko
 • Mo we nigba ti mo ti oko de

 

IWE AKATILEWA

Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) Longman Nig oju iwe29-32

 

IGBEYAWO ODE ONI

AKORI ISE:

AKOONU:

 • IGBEYAWO SOOSI
 • IGBEYAWO MOSOLASI
 • IGBEYAWO KOOTU

Lode oni, aye ti di amulumala. Orisirisii ona ni a n gba gbe iyawo. A n gbe iyawo ni ile Olorun, a n gbe e ni kootu, a si n gbe ni mosalasi. Igbeyawo soosi yii fese mule laarin awon onigbagbo, igbeyawo mosalasi si mule laarin awon musulumi.

 

Igbeyawo soosi ni eyi to maa n waye laarin awon elesin Kristeni ninu ile ijosin won, sugbon ki eto igbeyawo yii to waye ni won yoo ti maa kede eni to ba ri idi ti won ko le fi so oko ati iyawo naa papo ko tete wa so bi bee ko, ki eni be gbe enu re dake laelae. Bi won ko ba tiri enikeni ko yoju ni won to le so awon mejeeji po. Iru igbeyawo yii ko faye gba ju iyawo kan lo.

 

Igbeyawo mosolasi maa n waye laarin awon musulumi, eyi faye gba ju iyawo kan lo nitori won ni “me” ni Olorun wi, ti agbara eniyan ba ti kaa. Awon musulumi a maa fi omo se saara lai je pe onitohuni fi okan sii tele eyi ni pe ki won fun eniyan ni iyawo lairo tele (ki won fun eeyan ni iyawo ofe). Eyi ni won naa n pe ni iyawo saara.

 

Orisii igbeyawo yii fese mule daadaa nile Yoruba nitori esin igbagbo ati Isilamu to fese mule lode oni. Gbogbo ilana lati ibi itoro titi de idana maa n saba je eyi ti a n tele.

Awon loko laya miiran a ma n se igbeyawo alarede ti o je pe won a lo si olu ile-ise ijoba ibile tabi Kootu lati fowo si iwe ase lodo ijoba, won a si fi bee gba oruka arede. Eleyii naa ko faye gba ju iyawo kan ati oko kan lo.Igbeyawo kootu ni a n pe e.

 

Ni aye ode oni ko si ohun to n je ekun iyawo mo, opolopo awon wundia iwoyi ni won ti daju, gbogbo won ni oju n kan lati lo ile oko. Ko tile sohun to fe pawon lekun nitori won ko ka ile oko si ohun babara.

 

IGBELEWON

1.  Salaye igbeyawo soosi

2.  Ki ni ohun ti o le so lori igbeyawo kootu

3.  Se afiwe igbeyawo abinibi pelu igbeyawo ode oni

4.  Awon ona wo ni awon musulumi n gba se igbeyawo

 

IWE AKATILEWA

 1. Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun (J S S 2) University Press Ltd iwe keji oju iwe 35-54
 2. Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba Longman Nig Ltd iwe keji oju iwe114-118

 

ISE ASETILEWA

 1. Awon ____ lo n se igbeyawo soosi (a) Musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa.
 2. Awon ____ lo n se igbeyawo Mosolasi (a) musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa.
 3. Awon ____ lo maa fi omo se saara (a) Onigbagbo (b) Alarede (d) Musulumi  
 4. Oluko gba pe ise yii dara.gbolohu ti a fala si nidi ni … (a) awe gbolohun afarahe (b) olori awe gbolohun (d) odindi gbolohun.
 5. ____ni gbolohun ti o fara he olori awe gbolohun. (a) awe gbolohun afarahe (b) olori awe gbolohun (d) odindi gbolohun.

 

APA KEJI

1.Fa ila si awe gbolohun afarahe nihin:

 1. Omo naa sun nigba ti o setan
 2. Gbogbo ilu gbo pe ounje won

2. Salaye igbetawo aye ode oni

 

 

OSE KERIN

EYA AWE GBOLOHUN AFARAHE

AKOONU:

– Awe gbolohunafarahe

 • Olori Awe Gbolohun

ORISII AWE GBOLOHUN AFARAHE

Orisii awe gbolohun afarahe meta ni o wa ninu ede Yoruba, awon meteeta ni: –

(a)  Awe Gbolohun Afarahe Asodoruko: eyi maa n sise oro oruko ninu gbolohun. Apeere: –

 Awon eniyan mo pe ounje won

 Bisi daba a moto rira

 Alaga feiyawo

(b)  Awe Gbolohun Afarahe Asapejuwe: – Awe gbolohun yii maa n sise eyan tabi sapejuwe oro oruko ninu gbolohun. Wunren re ni “ti” ni (ami itoka won).

 Apeere: –

   Iresi ti mo se ko din rara

Iyawo mi ti o lo idale ti de

Iwo ti mo ri nile ijo ko niyi

(d)  Awe gbolohun Afarahe Asaponle: – eyi ni o maa n se epon fun oro ise ninu gbolohun. O maa n fun oro ise ni itumo to kun Apeere: –

Oga naa rin bi elemu ti n rin

Mo yo bamubamu

Ojo kan ilekun koko

 

IGBELEWON

1. Lo awo oro wonyi ni gbolohun: ti,bi,nigba,pe

2. Iyato wo lo wa laarin awe gbolohun afarhe asaponle ati awe gbolohun afarahe asapejuwe

 

IWE AKATLEWA

1 Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S 2 ) Longman Nig Ltd oju iwe 25-26

 

AFIWE IGBEYAWO AYE ODE ONI ATI TI AYE

Ni aye atijo, ona odo, oja ale, abe igi oronbo ni omokunrin ati omobinrin ti maa n pade sugbon laye ode oni ka pade ni pati, ile sinima, ile eko ibi ise ati inu oko ki a si di toko-taya ko wopo laye ode oni.

 

Bakan naa, awon agbalagba a maa fi omo won fun ore won, pupo ninu awon ore yii si le je agbalagba bii ti won. Won ko ni je ki awon omo yii fe omode egbe won, sugbon laye ode oni won kii fomo foko mo, eni to ba wu omo ni o le fe e.

 

Laye ode oni, ki i fi bee si alarena mo bii ti aye atijo, awon odokunrin ati obinrin n konu ife sira won laisi alarena kankan. Awon obi paapaa ki i se iwadii daindain kan mo lori eni ti omo won ba fe fe, won ko fe mo boya o n sise owo ni tabi o n digun jale. To ba saa ti lowo lowo baba nla la fi n wo won.

 

Oju ti awon baba nla wa fi n wo igbeyawo laye atijo ko je nnkan babara loju awon omo iwoyi mo, ibale obinrin ti won ka si nnkan babara ko ju bintin loju won, won ko si mo o ni nnkan abuku. Opolopo won ni won ti n ni ajosepo ki won to se igbeyawo lode oni. O fe ma fe si igbeyawo laisi oruka lode oni koda awon ti won n se igbeyawon abinibi n lo oruka eyi ko ri be ni aye atijo.

 

IGBELEWON

1. Se afiwe igbeyawo onigbagbo ati igbeyawo awon musulumi/Yigi

2.Iyato wo lo wa laarin igbeyawo ode oni ati ti aye atijo

 

IWE AKATLEWA

Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) Longman Nig Ltd oju iwe25-26

 

LITIRESO AYEYE TO JE MO IGBEYAWO

AWON EWI ATENUDENU TI A LE LO NIBI IGBEYAWO

 • EKUN IYAWO

Orisirisii ewi atenudenu ni a ni ni ile Yoruba ti a maa lo nibi ayeye, awon ewi atenudenu yii ko lo n ka. Lara iru awon ewi bayii ni a ti ri Rara, Olele, Oku-pipe, Alamo, Ege, Ekun-Iyawo, Efe, Dadakuada, Etiyeri ati bee bee lo.

 

Bi orisirisii ayeye se wa bii ayeye igbeyawo, isinku agba, ikomojade, isile, oye jije ati bee bee lo, bee naa ni awon Yoruba ni oniruru ewi ti o ba okookan mu sugbon awon ewi alohun ti a le lo nibi igbeyawo ni a fe gbe yewo.

 

Bi o tile je pe ekun iyawo gan ni ewi atenudenu ti a ya soto fun aseye igbeyawo, ti o si gbe oruko iyawo lori, awon ewi atenudenu kan wa to je pe ojo ni won, sasa ni ibi ayeye ti won kii ti lo won. Iru awon ewi atenudenu bee ma n waye nibi ayeye igbeyawo bakan naa. Die ninu awon ewi naa ni rara, ege, olele, apepe, obitun, dadakuada ati bolojo.

 LITIRESO ATENUDENU EYA/AGBEGBE

Rara Oyo

Olele Ijesa

Biripo Ikale/Ilaje

Ekun iyawo  Oyo

Bolojo Ye wa(Egbado)

Alamo Ekiti

Adamo Ife

Igbala Egba

Dadakuada  igbomina

Orin etiyeri  Oyo

Ege/Ariwo  Egba

Orin Edi  Ile-ife

Obitun  Ondo

Apepe Ijebu

 

Apeere Ekun-Iyawo

Iya mi mo n rele oko

Ile-eko ni ile oko je

Mo wa gba’re temi ki n to maa lo

Ki n ma mo si

Ki n ma kagbako nile oko

Ori mi sin mi lo

Ori eni nii sin ni rele oko

Ori leja nla fi la inu ibu

Emi Aduni ogo, olofa mojo

Omo okan o gbodo jukan lo

Omo abisu jooko —-

 

IGBELEWON

1.  Daruko marun-un ninu awon ewi atenudenu ti a le lo nibi ayeye igbeyawo

2.  Awon nnkan wo lo maa n wa ninu ekun iyawo

3.  Ki ni itumo ekun iyawo gan-an?

 

IWE AKATILEWA

Egbe Akomolede ati Asa (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) Longan Nig Ltd oju iwe123-127

 

ISE AMURELE

 1. Orisii awe gbolohu afarahe…. ni o wa. (a) merin (b) marun-un (d) meta.
 2. Oluko gba pe ise yii dara. Gbolohun ti a fala si nidi je gbolohun ….. (a) awe gbolohun (b) olori awe gbolohun (d) odindi gbolohu.
 3. ____je okan ninu ewi alohun to je mo igbeyawo julo. (a) ijala (b) sango pipe

  (d) ekun iyawo.

4. ____ je okan ninu ewi alohun to je mo igbeyawo julo

(a)  ijala (b)  sango pipe  (d)  ekun iyawo.

5. ____ lo saba maa n ko awon obinrin ni ekun iyawo

(a)  awon agba obinrin  (b)  awon ode  (d)  awon odomobinrin.

 

APA KEJI

1.  Fun orisi awe afarahe ni apeere kookan

2 Awon nnkan wo lo maa n suyo ninu ekun iyawo

3 ko ewi meji miiran ti a le ba nibi igbeyawo sile.

 

 

OSE KARUN-UN

ONKA (100-300)

Ninu onka Yoruba, a maa n lo ilana aropo (+), ayokuro (-) ati isodipupo (*). Awon ilana yii maa n waye ni gbogbo igba ti a ba n ka Yoruba. Isodipupo ogun

 1. ogun
 2. ogoji (ogun meji)
  1. ogun (ogun marun) (20*5)

120 ogofa (ogun mefa) 20*6

140 ogoje (ogun meje) 20*7

160 ogojo (ogun mejo) 20*8

180 ogosan (ogun mesan) 20*9

200 Igba (ogun mewa) 20*10

Awon onka kan wa ti o maa n din mewaa. Iru onka bee bere lati ori 50 titi de 190.Fun apeere.

50 aadota (ogun meta din ni mewa) 20*3-10

 70 aadorin (ogun merin din ni mewa) 20*4-10

 90 aadorun (ogun marun din ni mewa) 20*5-10

 110 aadofa (ogun mefa din ni mewa) 20*6-10

 130 aadoje (ogun meje din ni mewa) 20*7-10

 150 aadojo (ogun mejo din ni mewa) 20*8-10

 170 aadosan (ogun mesan din ni mewa) 20*9-10

 190 aadowa (ogun mewaa din ni mewa) 20*10-10

 

Leyin igba (200) ona ti a n gba pe 20, 40, 60 ati 80 yato.

 1. okoo
 2. oji
  1. ota
  2. orin
   1. okoolerugba (200+20)

240 ojilerugba (200+40)

260 otalerugba (200+60)

280 orinlerugba (200+80)

300 oodunrun.

 

IGBELEWON

1. a.Ko onka wonyi sile. 50, 70, 90, 110, 130.

b. kin ni a n pe 20, 40, 60, 80 leyin igba?

2. Ko awon onka wonyi sile: 120, 140, 80, 220, 280.

 

IWE AKATILEWA

 1. Egbe Akomolede ati Asa (2002) Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) Longman Nig Ltd oju iwe123-127
 2. Mustapha Oyebamiji (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji ( J S S 2) University Press Nig Ltd oju iwe 69-74

 

ITOJU OYUN

AKOONU:

 • ITOJU OYUN
 • IBIMO

Gbogbo wa la mo bi omo ti se pataki to laarin awa Yoruba. Ko si bi owo, ola ati ola eniyan ti le po to ti ko ba bimo aye asan ni oluwa re wa. Igbagbo yii fese mule laarin awon Yoruba to bee to fi je pe ko si ohun ti won ko le fi wa omo. Nitori naa asa oyun nini ki i se nnkan ti won n fi owo yepere mu rara, obinrin ti ko ba ri omo bi ni won n pe ni agan nile Yoruba. Ti okunrin ba gbe iyawo ti iyawo yii ko tete loyun tabi ti omo ba dagba lowo obinrin ti oyun ko ba tete ri omo bi kiakia ni yoo ti to awon agba lo fun aajo ki iyawo le tete loyun.

 

Orisirisi itoju ni a maa n fun awon alaboyun ni ile Yoruba, lati igba ti iyawo ba ti so fun oko re pe oun kori nnkan osu oun mo ni yoo ti maa fi inu ro ona ti yoo gba ti a o gbohun omo ti a o si tun gbo ti iya ti oyun naa ko fi ni baje. Lara ona ti a n gba se itoju oyun ni Oyun dide eyi saba maa n waye ti oyun ba n baje lara obinrin, ti iru obinrin yii ba loyun miran won maa n de e ki oyun naa ma ba tun baje.

 

Ohun miran to tun maa n je ki won de oyun ni pe laye atijo won ki i fe se oyun fun obinrin nitori ese ni won kaa si dipo bee se ni won ade ki oyun naa ma ba soke. Looto ni won n lo orisirisii oogun, sugbon a ki i saba lo oogun fun aboyun laarin osu kini si eketa, to ba pe osu meta orisirisii oogun ni won le lo. Oogun ki omo le maa gbera daadaa ninu, ki ara obinrin le fuye, eyi ti yoo maa lo ti ese re ba n wu ati eyi ti yoo fi bi were (oogun abiwere).

 

Omiran ninu awon oogun wonyi yoo je nnkan bi agbo fun mimu tabi nnkan wiwe, omiran si le je lila. Gbogbo agbo tabi ogun yii lo ni asiko ti a gbodo lo won. Omiran ni osu keta, omiran ni osu karun-un tabi osu keje.

 

Ti oyun ba ti bere si mu obinrin daadaa, won a ni ko kunle ko bere si ni gbin kikan-kikan. Agba obinrin kan yoo duro leyin re. ekeji niwaju lati maa so igba ti omo ba fe yo ori sita, ni kete ti won ba ti ri ami pe omo n bo ni won yoo ti te aso sile ti won yoo si fi owo pade re. Nigba miran isoro le wa sugbon gbogbo itu ti won ba mo ni won yoo pa tan.

 

IGBELEWON

1.  Ona wo ni awon Yoruba n gba se itoju oyun?

2.  Se alaye soki lori ibimo nile Yoruba

 

IWE AKATILEWA

Mustapha Oyebamiji (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji ( J S S 2) University Press Nig Ltd oju iwe 104-111

 

LITIRESO ALOHUN AYEYE/EWI ATENUDENU AYEYE

AKOONU:

 • Etiyeri
 • Rara
 • Bolojo

Orisirisii ayeye ni a maa n se ni ile Yoruba bi ayeye isile, isomoloruko, oku agba, igbeyawo, oye jije ati bee bee lo. Bi orisirisii ayeye se wa naa ni awon ewi atenudenu lokan-o-jokan ti a maa n lo nibi awon ayeye wonyi. Lara won ni :-

ETIYERI:- Eyi wopo ni Oyo. Gbogbo ibi ayeye ni a ti le lo o. Won si tun n lo o lati dekun awon iwa aito ni awujo.

RARA:- A maa n lo rara naa nibi ayeye orisirisii. O wopo ni Oyo, won n lo o lati fi ki eniyan tabi se ayesi eniyan.

BOLOJO:- Awon Egbado ni won ni orin bolojo. O je orin amuludun ti won maa n lo nibi ayeye orisirisii. Awon odomokunrin ilu lo maa n koo lati dekun iwa ibaje laarin ilu bee ni won n loo lati sure fun eniyan.

Awon ewi atenudenu miran ti a tun le lo nibi ayeye ni Oku pipe, Alamo, Olele, Ege, Efe, Orin apepe, Biripo, Adamo ati bee bee lo. Sugbon awon kan wa to je pe ayeye kan pato ni a ti le lo won. Apeere won ni ekun iyawo, oku pipe tabi iremoje.

 

IGBELEWON

1.  Daruko ewi atenudenu marun-un ati agbegb ibi ti won ti wopo.

2.  Daruko awon ewi atenudenu to je ayeye kan pato ni a ti le lo won.

 

AKATILEWA

 1. Mustapha Oyebamiji (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji ( J S S 2) University Press Nig Ltd oju iwe 24-31
 2. S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba L1 Book Two Copromutt Publisher oju iwe 16-20
 3. Egbe Akomolede ati Asa (2002) Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) Longman Nig Ltd oju iwe 37-38

 

ISE ASETILEWA

 1. Oodunrun ni…. (a) 120 (b) 150 (d) 300.
 2. 120 je …… (a) ogofa (b) ogoje (d) aadoje
 3. Obinrin ti ko ba le loyun ni won n pe ni …. (a) olomo (b) agan (d) iya ibeji.
 4. Lara orisi oogun ti a n lo fun itoju oyun ni …. (a) eyi ti yoo maa fi yagbe (b) eyi ti yoo fi bi were (d) ti yoo maa fi sun.
 5. A ko le lo okan ninu awon wonyi nibi gbogbo ayeye (a) rara (b) obitun (d) ege.

 

APA KEJI

 1. Ko awon onka wonyi ni Yoruba: 150, 160, 170, 180, 190.
 2. a kin ni itumo agan?
 3. b ko ona meta ti a le gba se itoju oyun

  d Ko ewi ayeye marun sile.

 

 

OSE KEFA

ONKA YORUBA (300-500)

Gege bi a ti a so seyin pe iyato diedie yoo ba onka 20, 40, 60, ati 80 ni kete ti a kuro lori igba (200). Fun apeere:

20 okoo

40 oji

60 ota

80 orin

300 ni a n pe ni oodunrun.400 je irinwo ti 500 maa je eedegbeta (600-100)=500. 600 ni a pe ni egbeta (200*3).

 300 oodunrun

 320 okooleloodunrun

 340 ojileloodunrun

 360 otaleloodunrun

 380 orinleloodunrun

 400 irinwo

 420 okoolerinwo

 440 ojilerinwo

 460 otalerinwo

 480 orinlerinwo

 500 eedegbeta

 

IGBELEWON

1. Ko awon onka wonyi sile 320, 340, 460, 480, 490

2. Ko awon onka wonyi sile 330, 350, 370 430, 470.

 

IWE AKATILEWA

Egbe Akomolede ati Asa (2002) Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) Longman Nig Ltd oju iwe 24-28

 

ITOJU OYUN NILE YORUBA DEETI……………………

Awon Yoruba maa n de oyun nigba ti oyun ba n baje lara obinrin. Ohun miiran to tun maa n je ki won de oyun ni pe laye atijo won ki i fe se oyun fun obinrin nitori ese ni won ka a si dipo bee se ni won a de e ki oyun naa ma ba baje. Looto ni won n lo orisirisii oogun fun aboyun Awon oogun ti won maa n lo naa ni awebi, abiwere eyi ti yoo je ko bi were sugbon a ki i saba lo oogun fun aboyun laarin osu kini si eketa, to ba pe osu meta orisirisii oogun ni won le lo. Oogun ki omo le maa gbera daadaa ninu, ki ara obinrin le fuye, eyi ti yoo maa lo ti ese re ba n wu ati eyi ti yoo fi bi were.Omiran ninu awon oogun wonyi yoo je nnkan bi agbo fun mimu tabi nnkan wiwe o si le je jije aseje, omiran si le je lila. Gbogbo agbo tabi ogun yii lo ni asiko ti a gbodo lo won. Omiran ni osu keta, omiran ni osu karun-un tabi osu keje.

 

Ni aye ode oni opolopo alaboyun ni ki i saba lo agbo tabi orisirisi aseje ile iwosan ni opolopo won ti maa n lo gba itoju.

 

Ti oyun ba ti bere si mu obinrin daadaa, won a ni ko kunle ko bere si ni gbin kikan-kikan. Agba obinrin kan yoo duro leyin re. ekeji niwaju lati maa so igba ti omo ba fe yo ori sita, ni kete ti won ba ti ri ami pe omo n bo ni won yoo ti te aso sile ti won yoo si fi owo pade re ti o ba n bo. Nigba miran isoro le wa sugbon gbogbo itu ti won ba mo ni won yoo pa tan.

 

IGBELEWON

1.  Ona wo ni awon Yoruba n gba se itoju oyun

2.  Se alaye soki lori ibimo nile Yoruba

 

IWE AKATILEWA

Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Tuntun iwe keji (J S S2 ) University Press oju iwe104-111

 

ISE ASETILEWA

1. Mewaleniloodunrunni …. (a) 300 (b) 310 (d) 320.

2. Ko si ilana isiro … ninu onka Yoruba (a) aropo (b) ayokuro (d) isodipupo.

3. … ni 365 ni onka Yoruba (a) otaleloodunrun o le mewa (b) otalerugba o din merin

(d) otaleloodunrun o din merun-un.

4.Okan lara ohun to n mu ki won de oyun ni …. (a) ti oyun ba ga (b) ti oyun ba n baje

(d) ti obinrin ba n beru.

5. …… ni asiko ti obinrin maa bimo. (a) osu meta (b) osu meje (d) osu mesan.

 

APA KEJI

Salaye awon oro wonyi ni sokisoki: iwo dida, abiwere ati esentaye.

 

 

OSE KEJE

AKAYE

Akaye je okan ninu ise ti a fi n mo bi eniyan se gbo ede Yoruba to. Akekoo gbodo le ka ayoka ti a fun-un ki o si le dahun awon ibeere lori re lati fi han pe ayoka bee ye oun daadaa. Ohun ti a ka to yeni yekeyeke ni akaye. Gbogbo koko to wa ninu ni akekoo gbodo fayo, ki akekoo to le se eyi ni aseyori. O ni awon igbese kan ti akekoo gbodo gbe lori ayoka bee.

1.  O gbodo koko fi pelepele ka a de le ni igba akoko

2.  A tesiwaju lati ka ayoka naa leekeji lati wa awon ibi ti ibeere ti jeyo

3.  Igbese to tele ni ki o wa maa dahun awon ibeere naa ni okookan ni oro ara re.

4.  Idahun re gbodo je mo ohun ti won beere lori ayoka naa

5.  Lopin gbogbo re, akekoo ni lati tun idahun wa ka si ibeere kookan.

 

IGBELEWON

1.  Salaye awon igbese akaye

 

IWE AKATILEWA

1 Egbe Akomolede ati Asa (2002) Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) Longman Nig Ltd oju iwe 69-7

 

IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ABIKU

Abiku ni awon omo ti won maa n bi ju eekan lo. Iru awon omo bayi maa n ku ti won ba ti n bi won. Igbagbo Yoruba ni pe iru awon omo bayi ni egbe lorun gege bi igbagbo awon Yoruba. Inu le bi awon obi omo ki won ge ika ese tabi ti owo omo naa nigba ti o ba su won. Igbagbo won ni wi pe iru awon omo bee ko ni ya odo won mo ti o ba tun ile aye wa. Abuku ni iru eyi je fun won tori pe awon egbe re o ni gba mo. Orisirisii oruko ni o fi han pe abiku n be. Fun apeere kokumo, Fidimaye,Malomo, Kukoyi, Maku, Kosoko,Rotimi, Durosinmi Kosoko.

 

 

IGBELEWON

1. Ko oruko abiku merin sile

2. Ona wo ni won maa n gba dekun abiku nile Yoruba

 

IWE AKATILEWA

Mustapha Oyebamiji (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji ( J S S 2) University Press Nig Ltd oju iwe 231-233

 

ISE ASETILEWA

1.  Ohun ti a fe ki akekoo se ti a ba ka akaye tan ni ki a ____ (a) fami si

(b) wa ibi ti ibeere ti jeyo(d) Bere si ni dahun awon ibeere

2.  Nnkan ti a fe mo bi a ba fun akekoo ni ayoka ni …………. (a) bi o se gbo ede Yoruba to (b) bo se gbo geesi to (d) bo se mo owe to

3.  Ewo ni ki i se ooto?

(a) idahun wa gbodo je ni oro ara wa (b) a gbodo kiyesi awon ijinle oro

4. Ewo ni ki i se oruko abiku nihin (a) Kokumo (b) Kosoko (d) Ajibade

5. Toka si oruko abiku ninu awon wonyi (a) Kokumo (b) Ajibade (d) Ajayi.

 

APA KEJI

 1. Salaye itumo akaye
 2. Ko oruko abiku merin sile.

 

 

OSE KEJO

ITESIWAJU LORI AKAYE

Ni aaro kutukutu ni Abeni iya Olatide kan ilekun mo o lori. O wa ba a soro lori aitete ni iyawo. Pelu omije ni Abeni fi kuro nibe. Ori ekun ni Akangbe ba ore re Olatide. O ro pe ki o ma ba okan je, ko si je ki awon jade lo si agbo faaji.

 

Olatide binu soro ore re pe ase ore alainironu ni oun n ba rin. Gbogbo ore ti o ju pe ki a lo ile oti lo . Nko ni iyawo bee ni nko bimo kan soso se iyen o to ro. Soobu iya gbajumo oloti ni Akangbe lo. O ra igo oti nla meji pelu eran igbe meji. Laipe ti o mu eyi tan o tun ra igo oti merin si. Oti bere si pa a. O wa n fi igo oti le awon eniyan kiri Bayi ni iya oloti pe awon olopaa ti won si mu lo si ago won.

 

IGBELEWON

 • Tani iya re n ba soro ninu ayoka yi?
 • Ki lo fa ti awon olopaa se mu Akangbe lo si ago won?

3 Kin ni oruko iya Olatide?

 

IWE AKATILEWA

S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba L1 Book Two Copromutt Publisher oju iwe 87-91

 

OMO BIBI/ OJO IKUNLE

Ori ikunle ni obinrin ti maa n bimo.Bi o ba to asiko atibimo. Aboyun yoo ri eje ati omi die lara omirare ami pe o to akoko lati bimo niyen. won a ni ki o maa gbin leralera. Agba obinrin yoo duro leyin re okan niwaju lati ma so igba ti omo maa yo ori sita ni igba miira isoro le wa sugbon gbogbo itu ti agbebi ba le pa ni yoo pa.

 

Eewo/Oro ile: Oro ile ni nnkan ti obinrin ti o bimo ko gbodo se fun anfaani ara re ati nitori omo to sese bi .Oro idile ibikan yato si omiiran. Fun apeere:

 

Ni idile olu oje, obinrin to bimo ko gbodo je iyan tabi amala titi ojo ikomojade. Isu ati ekuru ni yoo maa je. Ni idile onigbeeti, iya ikoko o gbodo je obe to ni iyo tabi ata titi di ojo ikomojade iru eyi ni won n pe ni obe ate. Won maa n gun iyan ati iru pelu epo pupa ni idile olokun esin iru ounje yii ni yoo maa je titi di ojo ikomo. Idile olofa ni won ti maa n je obe ate obe afun ni obinrin to sese bimo yoo maa fi je oka amala igbako kan soso lemeeta lojumo

 

IGBELEWON

Salaye perete lori:

1. omo bibi/ojo ikunle

 • oro idile onigbeeti
 • oro idile olokun esin
 • oro idile olofa

 

IWE AKATILEWA

Mustapha Oyebamiji (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji ( J S S 2) University Press Nig Ltd oju iwe 107-110

 

ORIKI

Oriki ni oruko keji ti a maa n fun omo ni ojo ti a ba somoloruko gan-an, oriki yii ni a maa n fi ki eniyan. Won a si ma a te mo eniyan lara gege bi oruko akoko. A ni oriki amutorunwa, inagije, abiso, borokini pelu oriki orile. Ti awon Yoruba ba n ki eniyan ori iru eni bee maa n wu ni.A le toka si omo bibi ibi ti eniyan ti wa ninu oriki. Ninu oriki a le so wi pe oruko bayi ni eniyan nje. Eyi le sele boya a ti gbo oriki eni bee nibi kan. Eya oriki ni: oriki borokinni, oriki abiso, oriki orile.

 

ORIKI ORILE IBADAN

 Ibadan omo ajorosun

 Omo ajegbinyo

 Omo afikarahun fori mu

 Ibadan maja maja bii tojo kiini

 Eyi to o ja ladugbo gbogbo logun

 Ibadan kure

 Ibadan mesiogo nile Oluyole:

 Nibi ole gbe n jare olohun

 Ibadan ki i gbonile bi ajeji

A ki i waye ka ma larun

 Ija igboro ni ti Ibadan…………….

 

IGBELEWON

 1. Ki ni oriki?
 2. Ki Ajayi
 3. Ki Taye/Kehinde

 

AKATILEWA

Olu Daramola (1990) Awon Asa ati Orisa Ile Yoruba Onibon-oje Press oju iwe 161-172

Mustapha Oyebamiji (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji ( J S S 2) University Press Nig Ltd oju iwe 16-27

 

ISE ASETILEWA

 1. Ohun ti a fe ki akekoo se ti o ba ka akaye tan ni ki o ………(a) faami sii (b) wa ibi ti ibeere ti jeyo (d) bere si ni dahun awon ibeere
 2. Nnkan ti a fe mo bi a fun akekoo ni ayoka ni …………..(a)  bi o se gbo ede Yoruba  (b) bo se gbo geesi to (d) bo se mo owe to
 3. Okan lara oogun ti awon Yoruba maa n lo fun oloyun ni ……… (a) aseje (b) oogun ounje (d) oogun oorun.
 4. ojo …… ni won maa n so omo loruko nile Yoruba (a) keta (b) karun-un (d) kejo.
 5. Onikanga-ajipon je oriki oruko amutorunwa ……. (a) Idowu (b)Ige (d) Ajayi.

 

APA KEJI

 1. salaye oro idile oluoje
 2. ki oriki orile ilu Ibadan
 3. ki ni oriki re
 4. awon oogun wo ni awon Yoruba maa n lo fun alaboyun

 

 

OSE KESAN-AN

AKOTO

AKOONU:

 • Akoto
 • Awon oro to ni iro ti ko ni itumo.

Akoto ni sipeli titun ti awon onimo ede Yoruba fi enu ko le lori ni odun 1974 lati ma lo.

SIPELI ATIJO SIPELI TUNTUN

 • Aiye  Aye
 • Aiya  Aya
 • Eiye  Eye
 • Gan an  Gan-an
 • Enia  eniyan
 • Kini  kin-in-ni
 • Okorin  okunrin
 • Obiri  obinrin
 • Nkan  nnkan
 • Onje  ounje
 • Tani  ta ni
 • Wipe  wi pe
 • Otta  Ota
 • Oshodi  Osodi
 • Ogbomosho  Ogbomoso
 • Iddo  Ido
 • Ottun  Otun
 • Shade  Şade

   

  GBELEWON

  1  Tun awon oro wonyi ko ni ilana akoto

  • Aiya
  • Ofon-on
  • Enia
  • Obirin

2.  kin ni akoto?

 

IWE AKATILEWA;

S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba L1 Book Two Copromutt Publisher oju iwe 27-29

 

ASA ISOMOLORUKO

AKOONU

 • OHUN ELO ISOMOLORUKO
 • ETO ISOMOLURUKO
 • EWI ATENUDENU TO JE MO IKOMOJADE

Ebun nla gbaa ni Yoruba ka omo si, won si gba wi pe ko si iru dukia ti Olodumare le fun eniyan ti o bori omo. Nitori idi eyi inu won maa n dun pupo nigba ti Oluwa ba yonu si awon idile kan to fi omo titun ta won loore.

 

Orisirisi ona ni awon Yoruba n gba so omo loruko. Awon miiran a maa wo sababi, asiko ati igba ti won loyun omo naa titi won fibi sile, boya won wa ninu idunnu tabi isoro nigba ti won loyun re ti o wa se pe nigba ti won bii gbogbo oke isoro won di petele, iru ipo bee a maa han ninu oruko omo bee. Oruko Yoruba a tun maa fi iru esin ti idile tabi ebi kan n sin han. Omiran yoo maa fi ise owo ti won se han.

 

Ni aye atijo, awon obi mejeeji, iya ati baba ni o ni ase lati so omo won loruko ni ojo kejo ti won ba bi omo naa, sugbon oruko ti baba tabi ebi baba ba fun omo ni won maa n te mo o lara ju. Aro kutukutu ni won maa n so omo loruko tori pe owo ero ni asiko owuro je gege bi asa. Baale ile tabi iyaale ile lo maa n dari eto yii, awon obi omo a file ponti, won a fona roka fun awon alejo won.

 

Leyin pe won a file ponti, won gbodo to ju awon nnkan apeere kan fun eto isomoloruko gan-an. Awon nnka bii oti, orogbo, obi, aadun, omi, iyo, suga, ireke, ataare, oyin, epo pupa ati awon nnkan miran. Awon ohun elo ni a n pe ni eroja isomoloruko. Won a maa fi oruko ti a n pe eroja kookan ati bi eledaa se seda won se adura fun omo naa. Bi apeere, won le fi aadun se adura fun omo naa gege bi oruko re pe aye omo naa yoo dun kale.

 

Oniruuru orin ni won maa n ko nibi ayeye isomoloruko ti won yoo si maa ke ewi lorisirisi. Ko si ewi kan pato ti a ko le lo ni iru ayeye yii, to ba sa ti ba inu didun lo, yato si awon bii meloo kan bii oku pipe, iremoje, ekun-iyawo.

Apeere orin to je mo ikomojade

A.  Iya abiye o ku ewu o

 Ewu ina kii pawodi

 Awodi o ku ewu

B.  Edumare fun wa lolu omo

 Edumare fun wa lolu omo

 Olu omo maa n da wa lorun o

 Edumare fun wa lolu omo  

 

Image From EcoleBooks.comOHUN ELO ISOMOLORUKO IWURE/ADURA

Odidi ataare Lagbaja, wa a dirun, wa a digba

Obi (abata) obi ni biku, obi ni bi arun ki iku maa pa o.

Orogbo orogbo re o, wa gbo wa to

Oti oti ki i ti, oti ki I te omo yii o ni ko ni ti/te

Omi tutu omi re o, ko ni gbodi lara re

Owo ki omo ma rahun owo

Eja aaro Eja re o, ori leja fi n labu ori re o ni buru

 

IGBELEWON

1. Ko ohun elo ismoloruko marun sile

2. Bawo ni won se n lo won nibi isomoloruko.

3.Awon ewi atenudenu wo ni a le lo nibi ayeye ikomojade

 

IWE AKATILEWA

S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba L1 Book Two Copromutt Publisher oju iwe 87-88

 

EYA ORIKI

Ohun ti o yani lenu ni wi pe ki i se eeyan nikan ni awon Yoruba ni oriki fun. Won a maa ki ounje, orisa, eranko abbl. Nitori, orisi eya oriki ni o wa, awon eya oriki naa ni: oriki abiso, oriki inagijetabi alaje,oriki amutorunwa, oriki borokinni, oriki orile,oriki ilu, oriki ounje orikiigi, oriki eye. E je ki a wo die lara won.

 

Oriki Borokini

 Nle o omo ola

 Akeremaseyeiyanje

 Ariwomasojo, ariwonmasaa

 Agba nla ojo ti I le eegun wole kerikeri

 Asoroogun bi igi obob

 Arolojukannikun

 

Oriki Abiso Amutorunwa (amutorunwa)

 Ojo yewuge alagbada ogun

 Ojo o si nle omo adie n dagba

 Iba wa nile, a ti paya e je

Okiinakiina, o toj aladie ki I sina

Aladie n logun, ojo n lota

Ojo Ajokoo-tolowuu-ma-ran

O feso eso mowo …………….

 

IGBELEWON

 1. k ni oriki ibeji
 2. ki Ojo

 

IWE AKATILEWA

Mustapha Oyebamiji (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji ( J S S 2) University Press Nig Ltd oju iwe 16-34

 

ISE ASETILEWA

 1. Atunko olopa ni …….. (a) olopaa (b) alapa (d)olopa.
 2. …….. ni sipeli titun ti awon omowe onimo ede fi kop e ki a maa lo ( a) akaye (b) sipeli titun (d) akoto
 3. ojo …….. ni won maa n so omo loruko nile Yoruba (a) meje (b) mejo (d) mesan-an.

4  …….. ni bi iku, ohun ni bi arun. (a) ataare (b) oyin (d) obi.

5 Eni ti ko ri omo bi ni awon Yoruba n pe ni ……… (a) iya olomo (b) iya ibeji (d)

agan.

 

APA KEJI

 • Tun awon oro wonyi yii ko ni ilana akoto
  • Alanu
  • Oloto
  • Olopa
 • Bawo ni won se n fi awon wonyi se adura/iwure nibi isomoloruko
  • Oti
  • Eja

OSE KEWAA

AKOTO

ORISIRISI ORUKO

AKOONU:

 • Oruko amutorunwa
 • Oruko abiso
 • Oruko abiku
 • Oruko oriko

Oruko amutorunwa ni oruko eyi ti a n pe omo gege bi ona tabi ipo ti omo gba waye nigba ti won bi.

ORUKO ITUMO

Tiawo/Kehinde akobi ninu awon ibeji(aburo)

Kehinde omo ti a bi tele Taiwo

Idowu omo ti a bi tele awon ibeji

Ige omo ti o ba ese waye

Dada omo ti irun ori re ta koko

Ajayi omo ti o da oju bole nigba ti a bi

Oke omo ti o di ara re sinu apo felefele waye

Olugbodi omo ti ika owo re tabi ika ese re pe mefa

 

ORIKI ABISO: Awon oruko ti on toka si ipo tabi aaye ti ti awon obi omo wa nigba ti won bi omo naa.

 

ORUKO ITUMO

Abiodun/Adebodun omo ti a bi ni akoko odun Pataki kan

Babawale/Babatunde omobinrin ti a bi leyin iku baba re agba

Iyabo/Yetunde/Yewande omombinrin ti a bi leyin iku iya re agba

Abiona omobinrin ti iya re bi si oju ona

Abiose/Abosede omo ti a bi ni ojo ose (aiku)

Abiara omo ti oyun re ko ti I han ti baba re fi ku.

 

ORUKO ABIKU: Abiku ni omo ti a bi ti n ku lemlemo. Apeere oruko won ni Enilolobo, Kukoyi, Malomo, Kosoko, Durojaye.

 

ORUKO IDILE: Awon oruko wonyi ni se pelu, esin tabi ipo ebi ni awujo

ESIN ORUKO

Ifa Awoseeka, Fabunmi, Faleti, Dopemu.

Ogun Ogunbiyi, Ogunleye, ogundiran

Sanponna Babayemi, Obafemi, Anibaba

 

ORUKO ORIKI: Awon oruko yii je oruko ti a fi n pon eeyan le.

 

ORUKO OKUNRIN ORUKO OBINRIN

Alani, Ajani, Alabi, Adio, Alao Amoke Ajike, Ayinke, Ajihun, Akanke

Asamu, Ayinla, Ajagbe Adunni, Alake Asake, Ajoke.

 

ORIKI BOROKINI

 Aguntasoolo

 Ajiginjogo

 Kikunle okunrin bi eni duro ni

 Gagalo sise meji o bara iwaju

 Okunrin gbonrangandan.

 

IGBELEWON

1. Ko oruk amutorun meta sile

2. Ko oruko abiso meji sile

3. Ko oruko abiku meta sile

 

IWE AKATILEWA

S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba L1 Book Two Copromutt Publisher oju iwe 89-93

Mustapha Oyebamiji (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji ( J S S 2) University Press Nig Ltd oju iwe 16-27

 

ISE ASETILEWA

 1. Atunko otta ni….. (a) ata (b) oota (d) ota
 2. Ewo ni o wa ni ilana akoto ninu awon wonyi? (a) sagamu (b) shagamu (d) saggamu.
 3. Ewo ninu awon wonyi ni a bi tele Idowu? (a) Idogbe (b) Idohe (d) Idoha.
 4. …. Ni omo ti o doju bole nigba ti a bi (a) Ajayi (b) Dada (d) Oke.
 5. Omo ti a bi leyin iku iya tabi iya iya omo ni……. (a) Yetunde (b) Abiona (d) Abiara.

 

APA KEJI

1 Tuna won oro wonyi ko ni ilana akoto Olopa, alafia alanu, ogbomosho, oshodi

2 Salaye awon oruko wonyi

 1. Taye
 2. Dada
 3. Ojo
 4. Abiara
 5. FabunmiShare this:


EcoleBooks | 1ST TERM JSS2 YORUBA Scheme of Work and Note

subscriber

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Accept Our Privacy Terms.*