Share this:

ILANA ISE SAA KIN-IN-NI

 

ISE EDE YORUBA

 

ISE: EDE YORUBA   KILAASI: JSS1

 

1  ÈDÈ Alifabeeti ede Yoruba Konsonanti ede Yoruba

ÀSÀ Itan isedale Yoruba: bi baba nla Yoruba se gbera lati ilu Meka wa tedo si ile ife

 LIT Oriki litireso

2  ÈDÈ Ihun oro onisilebu kan nipa aropo konsonanti ati faweeli [L+o]=Lo

ÀSÀ Ile Ife saaju dide Oduduwa ati idagbasoke ti Oduduwa mu ba awujo to tedo si.

 LIT Oriki Litireso.

3  ÈDÈ Akoto awon oro to ni iro ti ko ni itumo ninu [aiye=aye]

ÀSÀ: Awon eya Yoruba ati ibi ti won tedo si. Afihan lori maapu ile kaaro-o-jiire

 LIT: Awon ohun to ya litireso soto si ede ojoojumo  

ecolebooks.com

4  ÈDÈ: Akoto; Awon oro ti a sunki [alanu= alaanu ati pataki yiyamo sidi oro

 ÀSÀ: Awon eya Yoruba, ounje won ati awon nnkan pataki nipa won

 LIT: Ipa ti litireso ko lawujo Yoruba.

5  ÈDÈ: Onka Yoruba lati ookan de aadota [1-50].

 ÀSÀ: Iwulo ede Yoruba [oro siso].

 LIT: Litireso alohun to je mo aseye: [ege] ati agbegbe to n lo won.

6  ÈDÈ: Onka ookanlelaadota de ogorun [51-100]

 ÀSÀ: Bi asa se jeyo ninu ede Yoruba: Igbeyawo ati Isomoloruko

 LIT: Ltireso alohun to je mo esin. Esin ati eewo won

7  ÈDÈ: Ami ohun lori awon faweli oro onisilebu kan

 ÀSÀ: Bi asa se jeyo ninu edeYoruba.Oye jije ati asa iranra- eni- lowo

 LIT: Awon litireso apileko; alaye lori abuda won lapapo.

8  ÈDÈ: Ami ohun lori oro onisilebu meji ati ami ohun lori konsonanti aranmupe asesilebu [m/n]

 ÀSÀ: Bi asa se jeyo ninu edeYoruba: Aso wiwo ati oge sise

 LIT: Awon litireso apileko, itan aroso

9  ÈDÈ: Aroso atonisona alapejuwe [akole ilapa ero ipinafo koko aroko ati igunle

 ÀSÀ: Bi asa se jeyo ninu ede Asa ikini ati isinku

 LIT: Awon litireso apileko; ere onise

10  ÈDÈ: Aroko atonisona alapejuwe lori’ ile iwe mi’

ÀSÀ: Akaye kikawe sinu, fifa koko oro yo ninu ayoka ati fifi ero akekoo han lori ayoka.

LIT: Awon litireso apileko ewi

11  ÈDÈ: Isori oro ninu gbolohun, oro oruko, oro aropo oruko, oro aropo afarajoruko. Oro apejuwe,oro atokun ati oro asopo

 ÀSÀ: Akaye; lilo owe ati akanlo ede

 LIT: Ewi apileko; Mura sise.

12  ATUNYEWO ISE SAA YII

 

IWE ITOKASI

 • Egbé Akómolédè àti Asà Yorùbá (2002) Èkó èdè àti àsà Yorùbá ìwé kìn-ín-ní Longman Nig.
 • S. Y Adéwoyin (2004) New simplified Yorùbá ìwé kìn-ín-ní [J S S 1 ] Copromutt Publisher
 • Oyèbámjí Mustapha (2009) Èkó èdè Yorùbá titun Iwe kin-in-ni University Press Plc.

 

 

 

ỜSE KIN-IN-NI

ÀKÓRÍ ISE (EDE) ALIFABEETI

A B D E E F

 

G GB I H J K

 

L M N O O P

 

R S S T U W  

 

Y.

 

ALIFABETI

 

  ÌRÓ FAWEELI ÌRÓ KÓŃSONANTI

 

Fáwéèlì Airanmupe

Faweeli Aranmupe

A
Ìró Fáweli: Ìró faweeli ni àwon ìró tí èémí won kì í ní ìdíwó nígbà tí a bá n pè wón jade láti inú èdòfóró. Orisi méjì ni ìró faweeli pín sí. Àwon náà ni:

 • Faweeli Airanmupe a e e i o o u
 • Faweeli Aranmupe an en in on un.

B
Ìro Konsonanti: Ìró kónsónántì ni àwon ìró tí ìdíwó maa n wá fún èémí ti o n ti inú èdòfóró bò nígbà tí a ba n pè wón. Gbogbo àwon ìró kónsónántì wonyi kì í gba àmì sórí àfi kónsónántì àránmúpè àsesílébù [n/m] bakan náà ni won kì í parí òrò Yorùbá. Gbogbo kónsónántì èdè Yorùbá jé méjìdínlógún[18].

ÌGBÉLÉWÒN

1  Ko faweeli àìránmúpè sílè

2  Ko faweeli aàraánmuúpeè sílè

3  Ko kónsónántì èdè Yorùbá sílè

IWE AKATILEWA

New simplified Yorùbá L1 ìwé kìn-ín-ní [Js s 1] ojú ìwé 1 láti owó S Y Adéwoyin.

AKORI ISE (ASA) ÌTÀN ÌSÈDÁLÈ YORÙBÁ.

ÀKÓÓNÚ

Odùduwà ni baba nlá àwon Yorùbá, Lámúrúdu sì ni orúko baba rè. ìtàn fi yé wa pé okùnrin kan tí orúko re n jé Lámúrúdu ni oba ìlú Mékà ni ìgbà kan ri. Abòrìsà ni oba yìí, o sì máá n rúbo sí àwon orìsa re nigba gbogbo, kódà o ni aborè fún òrìsà rè.

 Ní àkókò tí a n sòrò rè yìí, èsìn mùsùlùmí sèsè wo ìlú Mékà ni, àwon omo léyìn mohammed n wàásù káàkiri gbogbo ìgboro mékà pé kí àwon ènìyàn dèyìn nidi òrìsà bíbo látàrì ìwáásù yìí, ìlú bèrè sí ní dá sí méjì àwon kan n tèlé Lámúrúdu oba won láti máa bòrìsà, àwon kan si darapò mo àwon elésin mùsùlùmí. Òkan lára àwon aborè Lámúrúdu tó n jé Bùrémò.

Ní àsikò odún òrisà , Asarà àti àwon ènìyàn re ti pese gbogbo ohun ti won fe fi bo òrisà sile nígbà tí Buremò ri pe Baba òun ti jade lo ni o ba sa iná sí gbogbo òrìsà won ti gbogbo òrisà won si jóná raurau- ìsèlè yìí ni o se okunfa ija laarin awon elesin musulumi ati àwon aborisà. Nínu ijà yìí ni Lamurudu oba kú sí.

Bayii ni Oduduwa ati àwon ènìyàn re to ku se kúrò ní ìlú Mékà wá si ile-ife tí won tedo sí tí o si di orirun àwon Yorùbá títí di òni.

 

ÌGBÉLÉWÒN

 1. Ta ni oba ìlú Mékà nigba kan ri?
 2. Ki ni o fa ti Odùduwà fi gbera lati ìlú Mékà wa si ile Ife

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Egbe Akomolede Ati Asa Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe kin-in-ni lati owo Oju iwe 1-2

 

AKORI ISE:   LÍTÍRÉSÒ YORÙBÁ

 

ÀKÓÓNÚ:-

 • Ki ni a n pe ni lítírésò?
 • Orisii litireso to wa
 • Awon iwulo lítírésò

 

Èdè àyálò ni lítírésò jé. Yorùbá yá a lati inú èdè gèésì ni, nigbà ti àwon elédeè gèésì ya a lati inú èdè Latini.. Lítírésò tumo si ohun ti a ko sile sugbon ninu èdè Yorùbá ìtumò rè gbòòrò jù bee lo.

 

Litireso je àkójopó àsà, ogbón, ìmò, òye, ìrírí ati isé àwon Yorùbá. Òrò èsìn àti òselu ko gbeyìn nínu litireso. Èkó tó wúlò fún ìgbà gbogbo, tó sì bá ìgbà gbogbo mu ni ó máá n wà nínú lítírésò Yorùbá. Lítírésò Yorùbá pín sí ònà méjì, àwon ni:-

 

 1. Lítírésò Àpilèko:- Èyí ni àwon Lítírésò tó wà ni àkosílé tí a si n ri ka tàbí tí a le rí ko
 2. Lítírésò Àtenudenu: Èyi ni lítírésò tí kò sí ní àkosílè, a máá n gbà á lati enu enìkan sí enu elomiran ni. A lè pe e ni lítírésò àbáláyé tàbi lítírésò alohùn. Ohùn enu ni a fi n gbé e jade, béè sì ni pé a bá à láyé ni.

   

ÌWÚLÒ LÍTÍRÉSÒ

1  Ó wà fún ìdárayá

2.  Ó n kóni lógbón

3.  Ó kún fún ìmo ìjìnlè nípa èdè Yorùbá

4  Ó n jé ká mò nípa isèlè tó ti selè láyé àtijó

5.  Ó n jé ká mo nípa àsà Yorùbá

6  Ó n tan imolè si èsìn Yorùbá

 

ÌGBÉLÉWÒN

1.  Ki ni a n pe ni lítírésò?

2.  Orisii l lítírésò mélòó ló wa?

3.  So ìwúlò lítírésò méta.

 

APAPO ÌGBÉLÉWÒN

1  Ko faweeli àìránmúpè sílè

 1. Ko faweeli aàraánmuúpeè sílè
 2. Ko kónsónántì èdè Yorùbá sílè
 3. Ta ni oba ìlú Mékà nigba kan ri?
 4. Ki ni o fa ti Odùduwà fi gbera lati ìlú Mékà wa si ile Ife
 5. Ki ni a n pe ni lítírésò?
 6. Orisii l lítírésò mélòó ló wa?
 7. So ìwúlò lítírésò meta.

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

 1. Eko ede ati asa Yoruba. Iwe kin-ni-ni oju iwe 55-56 lati owo Egbe Akomolede ati asa Yoruba
 2. S Y Adewoyin New Simplified Yoruba for Junior Secondary School JSS 1 Copromutt Publishers oju iwe 75-76.

 

ISE ASETILEWA

 1. Faweeli aranmupe ni ……. (a) I (b) o (d) an
 2. Faweeli roboto ni ….. (a) I (b) o (d) e
 3. ….. je konsonanti ti o maa n da duro bi odidi silebu ti o si maa n gba ami sori (a) m/n (b) b (d) f
 4. …….. ni oba ilu Meka nigba kan ri (a) Buremo (b) Okanbi (d) Lamurudu (e) Oduduwa.
 5. Litireso atenudenu naa ni a mo si …… (a) abalaye (b) apileko (d) itan

 

APAKEJI

 1. Salaye idi ti Oduduwa se gbera lati ilu Meka wa si ile Ife.
 2. a. Kin ni itumo litireso ede Yoruba?

b. Ko iyato meta ti o wa laarin konsonanti ati faweeli ede Yoruba?

 

 

 

ÒSÉ KEJÌ

ORO ONISÍLÉBÙ KAN

Bá Bé Bé Bí Bó Bó Bú

Dá Dé Dé Dí Dó Dó Dú

Gbá Gbé Gbé Gbí Gbó Gbó Gbú

Já Jé Jé Jí Jó Jó Jú

Má Mé Mé Mí Mó Mó Mú

Sá Sé Sé Sí Só Só Sú

Pá Pé Pé Pí Pó Pó Pú

ÌGBÉLÉWÒN

1   Pe àwon òrò wonyi

 • Fá Fé Fé Fí Fó Fó Fú
 • Gá Gé Gé Gí Gó Gó Gú
 • Ká Ké Ké Kí Kó Kó Kú

2 [a] ko faweeli airanmupe sile

  [b] ko faweeli aranmupe sile.

 

A
Konsonanti:- Kónsónántì ni àwon ìró tí ìdíwó maa n wá fún èémí won nigba ti o n ti inú èdòfóró bò nígbà tí a ba n pè wón.

Gbogbo àwon ìró kónsónántì wonyi kì í gba àmì sórí àfi kónsónántì àránmúpè àsesílébù [n/m] bakan náà ni won kì í parí òrò Yorùbá. Won le bere oro Yorùbá bee a si le ri won laarin oro Yorùbá sugbon won ki i pari oro yoruba. Gbogbo kónsónántì èdè Yorùbá jé méjìdínlógún (18). Apeere awon konsonanti naa ni:

Bb Dd Ff Gg GBgb Hh Jj Kk Ll Mm Nn Pp Rr Ss Ss Tt Ww Yy.

 

Awon iro konsonanti ki i pari oro Yorùbá. Koda bi oro ohun ba je oro ayalo, a maa n fi faweli pari iru oro bee ninu ede Yoruba. Fun apeere:

Class —— Kilaasi.

Bread —— Buredi

 

Ko tan sibe, konsonanti ki i tele ara won ninu ede Yorùbá. Iyen ni wi pe a ki i ni isupo konsonanti ninu oro Yoruba. Apeere:

Otta ———- Ota Oshodi ——- Osodi Shade ——– Sade

Ogbomosho — Ogbomoso  

 

Konsonanti ki i da duro bi iso kan ninu oro Yorùbá ayafi Konsonanti Aranmupe Asesilebu (m/n). Awon wonyi le da duro bi iso kan ki won si gba ami sori. Won maa n sise konsonaanti pelu ise faweli ninu gbolohun. Apeere:

Bamgbola Ba- m-gbo-la

Kongo Ko-n-go.

Ade n lo ile.  Ade n lo Ile

 

B
Fáweli:- Faweli ni àwon ìró tí èémí won kì í ní ìdíwó nígbà tí a bá n pè wón jade láti inú èdòfóró. Orisii méjì ni faweli pín sí. Àwon náà ni:

 • Faweli Airanmupe: Aa  Ee  Ee  Ii  Oo  Oo  Uu (7)
 • Faweli Aranmupe:  an  en  in  on  un (5)

 

Iro faweli a maa gba ami sori ki o si da duro bi odindi silebu. Apeere:

O lo si ilu Ota.  E wa ile Kunle ri i. Won pe e.

Alagbada. Bola gun keke.  Aja pa eku.

 

Faweli ‘u’ ki ibere ede ajumolo, o le bere oro ninu eka-ede Ekiti ati Ijesa. Apeere:

Yoruba Ajumolo: isu ile igba

Ekiti/Ijesa:  usu ule ugba.

 

APEJUWE IRO FAWELI

Gege bi a ti so saaju pe orisii iro faweli meji ni o wa ninu ede Yorùbá ati wi pe gbogbo awon iro faweli ohun je mejila ni apapo. Ki a ma gbagbe wi pe gbogbo iro faweli ni won je iro akunyun. Ni bayi a fe ye apejuwe awon iro faweli wonyi wo ni okookan. Ona merin ni a n gba se apejuwe iro faweli. Awon naa ni:

 1. Ipo Afase.
 2. Giga odidi ahon.
 3. Ipo Ete.
 4. Apa kan ara ahon to gbe soke

 

 1. Afase: je okan lara eya ara ifo/afipe ti a fi n pe iro jade. Enu ni afase yii wa, eran jobojobo ni. Afase yii le di ona ti o lo si kaa imu. Ni igba yii ni a maa n ni iro faweli airanmupe ( a, e, e, i, o, o o, u). Sugbon igba ti afase yii ba di kaa enu, eemi ko ni le gba enu jade ayafi kaa imu. Igba yii ni a maa n ni faweli aranmupe (an, en, in, un, on).
 2. Giga Odidi Ahon. Ayewon finnifinni fi ye wa pe bi a ba se la enu to ni ahon se maa n se wale si ti o sit un je wi pe bi a ba se pa enu de to ni ahon se maa n se ga to. Ahon le wa ni oke patapata, ebake, ebado ati odo. Ni ipo kookan yii ni a ti maa n pe orisii iro. Fun apeere ni igba ti ahon ba wa ni oke, a maa n pe faweli iro ‘i, in, u ati un” ti ahon ba wa ni ipo ebake ba wa ni ebake, a maa n pe ”e ati o’. ti ahon ba wa ni ipo ebado, a maa n pe ‘e, en, o, on’. Ni igba ti ahon ba wa ni ipo odo, a maa n pe iro faweli ‘a ati an”
 3. Ipo Ete: Ona meji ni ete le wa. Ete le wa ni perese. Igba yii ni o maa n dabi igba ti efin siga jade lenu. Awon iro ti a maa n pe jade ni igba naa ni: i, e, e, in ati en. Ona keji ni roboto. Awon iro ti a maa n pe ni igba yii ni: u, o, o, un ati on. /u/, /o/, /ɔ/.
 4. Apa kan odidi ahon: ona meta ni a le pin isori yii si. Awon naa ni: iwaju, aarin ati eyin. Ti ahon ba gbe soke si iwaju, awon iro ti a maa n pe ni: iro faweli i, e, e /i/, /e/, / ɛ/. ti ahon bag be soke ti o si wa ni aarin, awon iro ti a maa n pe ni. Iro faweli: a ati a, an ( /a/, /a/ ).

Apejuwe iro faweli airanmupe. Afase maa n di kaa imu nigba ti a ba n pea won iro wonyi ni ni eemi fi maa n gba kaa enu jade pea won iro wonyi.

 

ATE FAWELI AIRANMUPE

/a/: faweli airanmupe odo, ayanupe, akunyun, aarin a se enu perese pe e.

/e/: faweli airanmupe ahanudiepe, akunyun ebake iwaju a se enu perese pe e.

/ɛ/: faweli airanmupe ayanudiepe akunyun ebado iwaju a se enu perese pe e.

/i/: faweli airanmupe ahanupe akunyun oke iwaju a se enu perese pe e.

/o/: faweli airanmupe ahanudiepe akunyun oke eyin a se enu roboto pe e.

/ɔ/: faweli airanmupe ayanudiepe akunyun ebado eyin a se enu roboto pe e.

/u/: faweli airanmupe ahanupe akunyun oke eyin roboto.

 

ATE FAWELI ARANMUPE

/a/: faweli aranmupe ayanupe akunyun odo aarin a se enu perese pe e.

/Ɛ/: faweli aranmupe ayanudiepe akunyun ebado iwaju a se enu perese pe e.

/i/ faweli aranmupe ahanupe akunyun oke iwaju a se enu perese pe e.

/Ɔ/: faweli aranmupe ayanudiepe akunyun ebado eyin a se enu perese pe e.

/u/: faweli aranmupe ahanupe akunyun oke eyin a se enu perese pe e.

IGBELEWON

 1. ……. ni iro ti eemi re maa n ni idiwo nigba ti a ba n pe e jade (a) konsonanti (b) faweli (d) iro (e) konsonanti ati faweli.
 2. Iro ti iro re ko ni idiwo ni iro ………… (a) faweli (b) konsonanti (d) iro (e) ami.
 3. ……. je okan pataki ti iyato fi wa laarin konsonati ati iro faweli. (a) konsonanti ki i pari oro Yoruba (b) ko si ibi ti faweli ko le duro si ninu oro Yoruba (d) faweli le bere oro Yoruba bee si ni konsonanti naa le bere oro Yoruba (e) odiwon konsonanti ati faweli jo ara.
 4. Faweli ti ko ki n bere oro ajumolo ni …….. (a) a (b) b (d) m (e) e.
 5. Iro ti ki i tele ara won ninu oro Yoruba ni …….. (a) faweli (b) konsonanti (d) ami (e) omi.
 6. Ewo ni o maa n gba ami sori ninu awon iro wonyi? (a) b (b) d (d) f (e) m/n.
 7. ……. je iro iwaju. (a) a (b) u (d) o (e) i
 8. Ewo ni o je faweli eyin ninu awon wonyi? (a) a (b) e (d) in (e) u.
 9. Faweli roboto ni ………. (a) a (b) in (d) un (e) an.
 10. Faweli aranmupe ni ……….. (a) an (b) I (d) o (e) e
 11. Ko iyato meta laarin iro konsonanti ati iro faweli sile.
 12. Ko apeere faweli airanmupe meje sile.
 13. Ko apeere faweli aranmupe marun-un sile.

Se apejuwe awon iro yii sile: a, e, in, u, on, i ati un.

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

S Y Adewoyin New simplified Yoruba L1 iwe kin-in-ni Copromutt Publishers oju iwe 1-2

 

ORÍ-ÒRÒ – ILE-IFE SAAJU DIDE ODUDUWA

 • ÀWON TÓ BÀ PÀDÉ
 • ILU TO TI PÀDÉ WON
 • ÀJÓSEPÒ TÓ WÀ LÁÀRIN WON

   

  ILÉ IFÈ SÁÁJÚ DÍDE ODÙDUWÀ

  Gbogbo àwon ìlú tí Odùduwà àti àwon ènìyàn re la kojá ni won ti bá àwon ènìyàn pàde. Àwon ìlú bi Sudan, Òkè oya, Ile Boronu, Ile oba Sókótó. Gbogbo àwon ílú wonyi ni Odùduwà ti ba àwon ènìyàn pàde sùgbón kò fi bée sí ìbásepò to dan mórán láarin won, àwon tí kò le ba Odùduwà dé ile-ife nitori ààre tó mu won ni won tèdo si àwon ìlú wonyi títí di òní yìí. Èyí lo fa a to fi dabi pe èdè Yorùbá àti èdè àwon ìlú wonyi jo ara won die, bi a ba wo o dáadáa.

   

  Nígbà tí wón dé Ilé-Ifè, Odùduwà ba Àgbonmìrègún, Baba-ifá àti àwon ènìyàn re pade. Bi àwon òpitàn se so, won ni Obàtàlá ni oba ilú Ife nígbà náà sùgbón enu re ko ká ìlú, àwon Ugbo si wá ko àwon ife lérú, won sì je gàba lé won lórí. Gbogbo ohun to n selè yìí kò te Odùduwà lórun, o dìtè mo Obàtàlá, o si lee kúrò lórí oyè. Ki àwon ara ìlú to soro pe ohun to se ko te won lorun, o ti kogun ba àwon Ugbo, ó sì ségun won èyí lo sì mu ki àwon Ilé-Ifè so di àyànfé, ti won si fi joba gégé bi Òòni Ilé-Ifè.

   

  ÌGBÉLÉWÒN

  1.  Àwon wo ni Odùduwà bá pàdé nínú ìrìnàjò re?

  2.  Àwon ìlú wo lo ti pàdé àwon ènìyàn

  b.  Ibasepo wo lo wa láàrin Odùduwà àti àwon ènìyàn náà.

   

  ÌGBÉLÉWÒN

  1.  Àwon wo ni Odùduwà bá pàdé nínú ìrìnàjò re?

  2.  Àwon ìlú wo lo ti pàdé àwon ènìyàn

  3  Ibasepo wo lo wa láàrin Odùduwà àti àwon ènìyàn náà.

  4  Faweli ede Yoruba je ………. ni apapo

  5  Ko ofin meji ti o de konsonanti.

  ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

  Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe kin-in-ni lati owo Egbe Akomolede Ati Asa Yoruba, Oju iwe 1-2

   

  ISE ASETILEWA

 1. …….. je apeere faweeli aranmupe (a) a (b) o (d) in
 2. Gbogbo faweeli ede Yoruba je …….. ni apapo (a) ogun (b) mejidinlogun (d) mejila
 3. Ewo ni konsonanti ninu awon wonyi (a) a (b) in (d) m.
 4. …… je okan lara awon ti Oduduwa ba nile ife (a) Buremo (b) Oranmiyan (d) Obatala/Agbonmiregun.
 5. ……. Je litireso ti o ni akosile (a) apileko (b) atenudenu (d) atowoko

 

APA KEJI

 1. Àwon wo ni Odùduwà ba pade ninu irinajo re?

  Àwon wo ni Odùduwà ba pade ni ile ife?

 2. ko orisii lítírésò ti a ni ninu èdè Yorùbá.

 

 

 

ÒSÈ KETA

ÀKÓTÓ

ÀKÓÓNÚ

Àwon òrò tó ni ìró ti kò ni ìtumò.

Akótó ni sipeli titun ti àwon onimò èdè Yorùbá fi enu kò lé lórí ní odún 1974 lati ma lò.

SÍPÉLÌ ÀTIJÓ SÍPÉLÌ TITUN

 1. Aiye Ayé
 2. Aiya Àyà
 3. Eiye Eye
 4. Gan an Gan-an
 5. Enia ènìyàn
 6. Kini kin-ín-ní
 7. Okorin okunrin
 8. Obirin obìnrin
 9. Nkan nnkan
 10. Onje ounje
 11. Tani Ta ni
 12. Wipe wí pé
 13. Otta Otà
 14. Oshodi Osòdì
 15. Ogbomosho Ògbómòsó
 16. Iddo Ìdó
 17. Ottun Otun
 18. Shade Sadé

   

ÌGBÉLÉWÒN

1.  Tún àwon òrò wònyí kò ni ìlànà àkótó

 1. Aiya
 2. Ofon on
 3. Enia
 4. Obirin
 5. Li

2.  kin ni àkótó?

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

S Y Adewoyin New simplified Yoruba L1 iwe kin-in-ni Copromutt Publishers oju iwe 27-29

 

ÀWON EYA YORÙBÁ ÀTI IBI TÍ WÓN TÈDÓ SI

 ÈYÀ YORÙBÁ ÌLÚ ABÉ WON

Oyo Òyó,Ògbómosó,Ibadan, Iwó

Egbado Ilaro,Ado odo, Imeko,Igbogila

 Egba Abeokuta, Gbagura, Owu, Oke ona

Ijebu ìjèbú-ode, ìjèbú igbo, àgo ìwoyè,

  sàgamu,ìperu,epe

Ilesa   ìjèbú ijèsà, ibokun, èsà okè, ipetu ijèsà

 

ÌGBÉLÉWÒN

1  Ko èyà Yorùbá marun-un silè

2  Ko ilu marun-un ti a lè ba ni abe èyà Abeokuta silè

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1  New simplified Yoruba L1 iwe kin-in-ni [Js s 1] oju iwe 39-40 lati owo S.Y Adewoyin.

2  Eko ede ati asa Yoruba iwe keji [J s s 1] oju iwe 36-38 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

 

LIT AWON OHUN TI O YA LITIRESO SOTO SI ÈDÈ YORÙBÁ

A  LITIRESO: lítírésò èdè Yorùbá túmò si akojopò ogbon, imo, òye àti iriri àwon Yorùbá .

Lítírésò èdè Yorùbá pín sí orisii ònà meji.

lítírésò atenudenu ati lítírésò àpileko

B  ÈDÈ: Ede ni ònà ti a n gbà lati ba ènìyàn sòrò tàbí lati gbe èrò okan kale. Ni òpò igbà o maa n je òrò enu siso èdè je ohun tí a n lo ni ojoojumo. A ko le se lati ma lo ede lojumo.

Awon nnkan to ya lítírésò sotò si èdè ni.

A maa n se amulò èdè lojoojumo sugbon a le ma se àmúlò lítírésò.

Ninu ewi/ lítírésò atenudenu a lè maa se àmulo awitunwi, ààló àpamò tàbí korin.

Ede ni a fi n se katakara, a n lo èdè lati gbe ero okan jade.

A n lo ede lati gba ènìyàn ni ìmòràn.

 

ÌGBÉLÉWÒN

 1. Ki ni èdè ?
 2. Àwon nnkan wo ni o ya lítírésò soto sí èdè Yorùbá

 

APAPO ÌGBÉLÉWÒN

 1. Ko èyà Yorùbá marun-un silè
 2. Ko ilu marun-un ti a lè ba ni abe èyà Abeokuta silè
 3. Ki ni èdè ?
 4. Àwon nnkan wo ni o ya lítírésò soto sí èdè Yorùbá

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

S Y Adewoyin New simplified Yoruba iwe kin-in-ni [J s s1] Copromutt Publishers oju iwe 75-76

 

ISE ASETILEWA

1  Ewo ni o tona ninu awon oro wonyii? (a) aaye (b) ayee (d) aye

2  OTTA.Akoto oro yii ni —– (a) eta (b) otaa (d) Ota

3  Ewo ni ki i se eya Yoruba ninu awon wonyi? (a) Oyo (b) Abia (d) Ekiti

4  Abeokuta je ilu ti a le ri labe eya —— (a) Igbomina (b) Egbado (d) Egba.

5  —– ni ona ti a n gba ba ara wa soro. (a) ede (b) ife sisu (d) ija jija

 

APA KEJI

1  Ko eya Yoruba marun-un sile

2  Tun awon oro wonyi ko ni ilana akoto.

 Eiye Okorin. Enia. Shade.Wipe.

 

 

 

ÒSÈ KERIN

ÀKÓTÓ

 SÍPÉLÌ ATIJO SÍPÉLÌ TITUN


 Olopa  olópàá

 Na  náà

 Orun   Òórùn

 Anu  àànú

 Papa  pààpàà

 Suru  sùúrù

 Alafia  àlaafia

 Oloto olooto

 Dada daadaa

 miran  miiran

 Alanu alaanu

 Ologbe  oloogbe

 Lailai laelae

 

ÌGBÉLÉWÒN

1  Kin ni akoto ?

2  Tun awon oro wonyi ko ni ilana akoto.

 • Alafia
 • Papa
 • Alanu

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1  New simplified Yoruba iwe kin-in-ni [J s s1] oju iwe 27-29 lati owo S.Y Adewoyin.

2  Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni (J S S 1) oju iwe 70-75 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba

 

AWON EYA YORÙBÁ ATI OUNJE WON

ÀKÓÓNÚ  Awon eya Yoruba

Ounje awon Yoruba

 

ÈYÀ YORÙBÁ ÓÚNJE WON

Oyo  àmàlà isu.

Onko  èko yangan

Egba  àmàlà láfún

Yewa [egbado] àmàlà láfún

Ijebu  ikokore ati gaari mimu

Ife  àmàlà, ògèdè ati emu mimu

Ijesa  iyan.

Ondo  aja[lokili]

Eko  eja, ede ati akan.

 

ÌGBÉLÉWÒN

1 Ko eya Yoruba meta sile.

2 Ounje wo ni awon eya wonyi kundun/ feran lati maa je?

 Ekiti

 Ife

 Oyo

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

New simplified Yoruba iwe kin-in-ni [J s s1] oj ewe 39-40

 

IPA TÍ LÍTÍRÉSÒ KÓ LÁWÙJO YORÙBÀ

 • Kóríyá
 • Ìkìlò ìwà
 • Ipanilerin
 • Ó n jé ka mo nipa ìsèlè to ti sele laye atijo
 • Igbe ni lokan ro/atileyin fun ìforítì
 • Dídékun ìwà ìbàjé
 • Ó n jé ka mo ohun to dara yàtò sí nnkan ti o dara.

 

ÌGBÉLÉWÒN

Ko ipa marun un ti litireso n se ni awujo sile

 

APAPO ÌGBÉLÉWÒN

1  Kin ni akoto ?

2  Tun awon oro wonyi ko ni ilana akoto.

 • Alafia
 • Papa
 • Alanu
 1. Ko eya Yoruba meta sile.

4  Ounje wo ni awon eya wonyi kundun/ feran lati maa je?

 • Ekiti
 • Ife
 • Oyo

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1 .  New simplified Yoruba iwe kin-in-ni [J s s1] oju iwe 75-76 lati owo S.Y Adewoyin.

2.  Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni oju iwe 55-56 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

 

ISE ASETILEWA

1  Alanu. Atunko oro yii ni —– [a] alaanu [b] aleenu [d] alanuu [e] alannu

2  Ounje ti o wopo ni ilu ijebu ni —– [a] amala isu [b] ikokore ati gaari mimu [d] iyan [e] ede

3  ——-ni sipeli tuntun. [a] litireso [b] ede [d] akoto [e] eya Yoruba

4  Atunko alafia ni —–[a] alafiaa [b] aalafia [d] alaffia [e] alaafia.

5  A le ri Agege ati Osodi ni abe eya—— [a] Eko [b] Ijebu [d] Ondo

 

APA KEJI

1  Ko eya Yoruba marun-un sile pelu ounje won

2  Ko ipa meta ti litireso n ko lawujo

 

 

 

ÒSÈ KARUN-UN

ONKA (1-50)

1  Ookan okan

2  Eeji meji

3  Eeta  meta

4  Eerin merin

5  Aarun maru-un

6  Eefa mefa

7  Eeje  meje

8  Eejo  mejo

9  Eesan  mesan-an

10  Eewaa  mewaa

20  Ogun

30  Ogbon

40  Ogoji

50  Aadota

 

Ni eyin igba ti a ba ti ka onka wa de ori 14, o n ti o kan ni ki a ma se amulo ayokuro [-] ati aropo [+]. Fun apeere 16 maa je merindinlogun (Merin o din ni ogun),20-4. 27 je metadinlogbon {30-3}.

Ninu onka, lati 1-4 ni a maa n ropo sugbon lati ori 5-6, a maa n yo kuro. Fun apeere;

 1. ookanlelogun {20+1} okan le ni ogun
 2. mejilelogun {20+2} meji le ni ogun
 3. metalelogun {20+3} meta le ni ogun
 4. merinlelogun {20+4} merin le ni ogun
 5. marundinlogbon{30-5] marun din ni ogbon
 6. merindinlogbon {30-4} merin din ni ogbon
 7. metadinlogbon {30-3} meta din ni ogbon
 8. mejidinlogbon {30-2} meji din ni ogbon
 9. mokandinlogbon{30-1} ookan din ni ogbon
 10. ogbon.

   

  ÌGBÉLÉWÒN

  Ko onka lati 30 – 40 sile.

   

  ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

  1  New simplified Yoruba iwe kin-in-ni [J s s1] oj iwe 3-4 layi owo S Y Adewoyin

  2  Eko ede Yoruba titun iwe keji (J S S 1) oju iwe 76-80 lati owo Mustapha oyebamiji.

   

  ÌWÚLÒ ÈDÈ YORÙBÁ

  Èdè ni ònà tí à n gbà bá ènìyàn sòrò. Ìwúlò èdè Yorùbá ni;

 • À n fi ede sòrò
 • À fi n korin
 • Àfi n kewi
 • Èdè ni a fi n gbé àsà láruge.
 • A n lo lati le so bi ènìyàn se jé.
 • Àn lo lati gbe ero eni jade
 • À n lo nibi karakata
 • À n lo lati gba ènìyàn ni ìmòràn
 • À n fi polowo ibo
 • À fi n ko èkó ni ile eko

 

ÌGBÉLÉWÒN

Ko iwulo ede Yoruba marun-un sile.

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

S Y Adewoyin New simplified Yoruba Li iwe kin-in-ni [J s s1] Copromutt Publishers oju iwe 75-76

Mustapha Oyebamiji Eko Ede Yoruba Titun iwe kin-in-ni (J SS S 1) University Press Plc. oju iwe 86-90

 

EWI ALOHUN TO JE MO ASEYE

 

ÌGBÉLÉWÒN

1  Ko ewi alohun atenudenu/ alohun ayeye marun-un sile.

2  Ko ibi ti won ti maa n lo won.

 

APAPO ÌGBÉLÉWÒN

 1. Ko ewi alohun atenudenu/ alohun ayeye marun-un sile.
 2. Ko ibi ti won ti maa n lo won.
 3. Ko iwulo ede Yoruba marun-un sile.

   

  ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

  Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni oju we 64-65 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba

   

  ISE ASETILEWA

  1.  Ogun ni won n pe ni —–(a) 20 (b) 40 (d) 30

  2.  46 je ——(a) ookanlelogun (b) ookanlelogoji (d) merindinlaadota.

  3  A n lo ede lati ——- (a) jeun (b) soro (d) sare

  4  —- je okan lara ohun ti o so gbogbo omo Yoruba po gege bi omo iya(a) ede (b) akoto (d) oorun sisun

  5  Ewo ni ki i se ewi alohun ayeye nihin-in? (a) bolojo (b) rara (d) iyere ifa

   

  APA KEJI

  1.  Kin ni a n lo ede fun?

  2.  a. Ko ewi alohun ayeye meta sile

  b. Ko onka yii ni Yoruba 36, 37, 47, 48, 59.

   

   

   

  ÒSÈ KEFA

  ONKA (51-100)

  Gégé bí a ti so sáájúpe 50 ni àádòta.60 máa jé ogóta,80 máa ogórin, 100 máa je ogorùn-ùn

  60  ogóta (ogún meta) 20*3

  80  ogórin(ogún merin)  20*4

  100  ogorun-un (ogun marun) 20*5

   

  Leyin eyi a maa n ni aado, eyi si tumo si -10 Fun apeere .

  70  Aadorin (80-10) =70

 4. Aadorun-un (100-10) = 90
 5. ogota
 6. aadorin
 7. ogorin
 8. aadorun
 9. ogorun-un

   

  ÌGBÉLÉWÒN  

  Ko onka lati 70 titi de 80.

   

  ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

  New simplified Yoruba iwe kin-in-ni [J s s1] oj iwe 3-4 lati owo S Y Adewoyin

  Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni ( J S S 1) oju iwe 76-80 lati owo Mustapha Oyebamiji.

   

  BI EDE SE JEYO NINU ASA IGBEYAWO ATI ISOMOLORUKO

  Ninu asa igbeyawo ati isomoloruko, a ri orin owe, iwure Fun apeere.

   

  OWE (IGBEYAWO)

   Eyin iyawo o ni meni

   Bi ogede etido ki I ti yagan,o ni yagan

  Aye yin o dun bi oyin

   E o gbo bi kesekese bi orogbo

   

  ORIN

   Aduke dara o wu wa

   Bi egbin lori (2ce)

   Aduke dara o po

   

  Awa lebi oniyawo ebi olowo

   Awa lebi oniyawo ebi olowo

   Awa ki i segbe olosi

   Afigo loso

   O somo jeje

   Aduke dara o po

   O somo jeje

   

  IWURE

   Baba mi oni ni n o gbare e mi

  Kin n to maa rele oko

  Ire mi o po

  Bi ko ba kunnu igbaje a si kun nu aha

  Ire, ani ki n ma fabiku somo

  Ki n maa rin nipo awon agan.

   

  OWE (ISOMOLORUKO)

   Kadijo lo, kadijo lo

   Ibi olomo la n re

   Kadijo lo

   

  ORIN

   Edumare fun mi lolu omo(2ce)

   Olu omo maa n da mi lorun

   Edumare fun mi lolu omo.

   

  IWURE

  Wa a gbo, wa a to

  Yo o ni owo rere leyin.

   

  ÌGBÉLÉWÒN

  1  Ko orin ibi igbeyawo kan sile

  2  Ko orin isomoloruko

   

  ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

   Eko Ede Yoruba ode oni fun ile eko alakobere iwe kefa oju Iwe 37-41 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

  Eko Ede Yoruba Titun iwe kin-in-ni ( J S S 1) oju ewe 127-136 lati owo Mustapha Oyebamiji.

   

  LITIRESO ALOHUN TO JEMO ESIN ABALAYE

  Ki esin musulumi ati esin igbagbo to wo aarin awon Yoruba ni won ti ni esin ti won. Awon esin wonyii ni won n pe ni abalaye. Ninu esin kookan, won ni orisiirisii oro,orin,gbolohun ti won n lo nibe.Awon oro, orin ati gbolohun wonyi ni won n pe ni ewi alohun fun esin abalaye.

   

  EWI ALOHUN ESIN

  Esu pipe  Esu

  Oya pipe  Oya

  Ijala  Ogun/ode

  Orin oro/Arungbe Oro

  Iwi/Esa Egungun

  Iyere ifa  Babalawo

  Osun pipe Osun.

   

  ÌGBÉLÉWÒN

  Ko ewi atenudenu/alohun marun nibi esin abalaye sile.

   

  APAPO ÌGBÉLÉWÒN

  1. Ko ewi alohun esin abalaye marun-un sile
  2. Ko onka lati 90 de 100 sile.
  3. Ko orin ibile kan.

    

  ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

  Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni oju iwe 64-65 lati owo ebge akomolede ati asa Yoruba.

   

  ISE ASETILEWA

  1  70 je —– (A) ogorin (b) aadorin (d) aadojo

  2  95 je —- (a) marundinlogorun (b) marulelaadorun (d) marundilogorin

  3  Eyin iyawo ko ni meni.gbolohun yii maa n jeyo ninu asa Yoruba.(a) isomoloruko (b) oye jije (d) igbeyawo.

  4   —– je okan Pataki lara ohun ti o so awon Yoruba papo gege bi omo iya (a) iyere ifa (b) ile kiko (d) ede/asa

  5  Ijala ni won maa n lo nibi esin —– (a) egungun (b) osun (d) ogun

   

  APA KEJI

  1  Ko orin igbeyawo kan sile

  2  Ko ewi alohun esin abalaye merin sile.

   

   

   

  ÒSÈ KEJE

  AMI OHU

  ÀKÓÓNÚ  Ami

   Konsonsnti

   Faweeli

   Silebu

  Ede Yoruba je ede ami ohun.Ami ori oro meta ni a ni ninu ede Yoruba.Awon naa ni

  Ami ohun isale ( \ )

  Ami ohun aarin( )

  Ami ohun oke ( / )

   

  AMI OHUN ISALE

  Ba Fa Ge Gba

  Je Ka Na Ra

  AMI OHUNAARIN

  Be Fe Ge Gbe

  Je ki Lo Re

   

  AMI OHUN OKE

  Ba   Fe   Ge Gbe

  Ji   Ki   Ni Ri

   

  ÌGBÉLÉWÒN

  Fi ami si ori awon oro wonyii

  Ba-ba  (father)

  Gba-gbe  (forget)

  Gba-gbo  (believe)

  Ba-wi  (punish)

  Ri-ra  (To buy)

   

  ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

  Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni oju iwe 69-71 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba

  Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (JSS 1) oju iwe 76-80 lati owo Mustapha Oyebamiji.

   

  BI EDE SE JEYO NINU ASA OYE JIJE ATI ASA IRANRA-ENI-LOWO

  Awon asa ro suyo ninu oye jije ati asa iranra eni lowo ni orin,akanlo ede/owe ati orin ote ninu oye jije,iwure.

  ORIN

  Iwo lafi se

  Iwo lafi sagbalagba

  Iwo lafi se

  Benikan n se kondu kondu kondu

  Iwo lafi se

  Iwo lafi sagbalagba

  Iwo lafi se…….

   

  IWURE

  Oye a mori o.

  Igba odun odun kan.

   

  ASA IRANRA ENI LOWO

   Ode to loko ti o meran bo

   Yoo jorunla lai lomi obe

   

  OWE/AKANLO EDE

   Ajeji owo kan ko gberu dori.

   

  ÌGBÉLÉWÒN

  Ko orin kan ti a le ba nibi oye jije

   

  APAPO ÌGBÉLÉWÒN

  1  Fi ami si ori awon oro wonyii

  Ba-ba father .

  Gba-gbe (forget)

  Gba-gbo (believe )

  Ba-wi (punish)

  Ri-ra (To buy)

  2  Ko orin kan ti a le ba nibi oye jije

  3  ko orisii ami meta ti o wa.

   

  ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

  1  Eko ede Yoruba ode oni iwe kefa alakobere oju iwe 32-34 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

  2  Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni ( J S S 1) oju iwe lati owo Mustapha Oyebamiji.

   

  LITIRESO APILEKO

   

  ISE ASETILEWA

  1  Ami wo lo ye lori oro yii Baba (father) (a) baba (b) baba (d) baba

  2  Orisii ami ohun meloo lo wa ninu ede Yoruba? (a) meta (b) meji (d) merin

  3  Ewo ni ki i se asa Yoruba nihin? (a) omi mimu (b) igbeyawo (d) oye jije

  4  Iru asa Yoruba wo lati saba maa n ri orin ote (a) isomoloruko (b) oye jije (d) igbeyawo

  5  —- je litireso ti o maa n ni akosile. (a) atenudenu (b) orin (d) apileko

   

  APA KEJI

  1  Fi ami si ori awon wonyi

 • Baba father
 • Lo go
 • Wa come
 • So say
 • Ko write
 • Ki greet

2  Ko orin kan nibi oye jije sile

 

 

 

ÒSÈ KEJO

AMI OHUN

ÀKÓÓNÚ  Konsonanti

Faweeli

Gege bi a ti so saaju pe, ami ohun meta ni a ni ninu ede Yoruba. Ki a ranti pe faweeli nikan ni a maa n fi ami si lori afi konsonanti aranmupe asesilebu (m/n).

Awon wonyi nikan ni won maa n gba ami sori ninu konsnanti

bakan naa ni won le da duro gege bi odindi silebu ninu ede Yoruba.

 

AMI OHUN ONISILEBU MEJI

AMI OKE AMI ISALE AMI AARIN

 Sibi iji rere

 Kunle igba omo

 Wale ego ire

Batani akoko re mi

 Awo

 Ile

 Aje

Batani keji re do

 Aba

 Aje

 Ere

Batani keta do mi

 Egbe

 Ila

 Ilu

 

ÌGBÉLÉWÒN

1  Ami ohun meloo ni o wa ninu ede Yoruba

2  Fi ami sori awon oro wonyi (a) ede-shrimp (b) ede- language (d) ilu-drum

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

 1. Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni oju iwe 69-71 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba
 2. Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni ( J S S 1) oju iwe 76-80 lati owo Mustapha Oyebamiji.

 

ASO WIWO

ÀKÓONÚ   Oge sise

 Aso okunrin

 Aso obinrin

Leyin eyin fifo,iwe wiwe,ara pipa ni nnkan ti o kan leyin naa ni o kan mimu aso ti o dara si ara, eyi fi han pe onifaari ni awon Yoruba afinju ni won pelu.Iran Yoruba ki I wo aso ti o doti ohun ni won fi n pe won ni afinju niyen. Orisiirisii aso ni a nile Yoruba, aso obinrin oto bee naa ni aso okunrin yato gedegbe si aso obinrin.

Ni ile Yoruba obinrin ki i wo aso okunrin bee ni okunrin ko gbodo wo aso obinrin.

 ASO OKUNRIN ASO OBINRIN

Buba buba

Kafutaani iro

Adiro gele

Dandogo   iborun

Agbada   ipele

Dansiki

Sapara

Oyala

Sulia

Gbariye

Jalaabu

Kafutaani

Sokoto kenbe

Sooro

Atu

abunuju

kamu

Fila Abeti aja

Origi/ikori

Adiro

 

ÌGBÉLÉWÒN

1   Ko orisii aso okunrin meta sile

2  Ko orisi aso obinrin meji sile.

 

APAPO ÌGBÉLÉWÒN

 1. Ami ohun meloo ni o wa ninu ede Yoruba
 2. Fi ami sori awon oro wonyi (a) ede-shrimp (b) ede- language (d) ilu-drum
 3. Ko orisii aso okunrin meta sile
 4. Ko orisi aso obinrin meji sile.

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni oju iwe 44-57 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

 

ISE ASETILEWA

1  Awon ami ti a ni nile Yoruba ni ami oke,ami isale ati ami ——– (a) egbe (b) ori (d) aarin

2  Konsonanti ti o maa n gba ami sori ni —-(a) b (b) m/n (d) f

3   —- je okan lara aso ile Yoruba (a) saayan (b) gele (d) yeri

4  Ewo ninu awon wonyi ni ki i se aso obinrin? (a) yeri (b) buba (d) fila abeti aja

5  Eni ti o ni imototo ni awon Yoruba n pe ni —- (a) afinju (b) obun (d) oroju

 

APA KEJI

1  Fi ami si ori awon oro wonyi ade Alabi Kunle Bolanle

2  a  ko orisii okunrin meta sile

 b  Ko orisii aso obinrin meji sile

 

 

 

ÒSÈ KESAN AN

ORI-ORO

AROKO ALAPEJUWE

ITESIWAJU LORI AROKO ALAPEJUWE

 

ÀKÓÓNÚ

 • BI AROKO WA SE GBODO RI
 • SISE ILAPA ERO
 • BI A SE N SE ILAPA ERO

Aroko je ona ti a ngba gbe ero eni kale lori koko tabi ori oro kan fun elomiran lati gbe e yewo.

 

Aroko alapejuwe ni aroko ti a n fi n se apejuwe nnkan tabi enikan. Bi a ba fe ko aroko, a gbodo ni imo kikun lori ohun ti a nse apejuwe re, tabi ori oro ti a ba yan. O si le je ohun ti a ni iriri nipa re.

 

A gbodo se apejuwe yii lona ti eni ti o n ka aroko naa yoo fi le maa foju inu wo ohun ti a n sapejuwe re tabi ki o tile da nnkan naa mo bi o ba rii funra re.

Sise ilapa ero se Pataki ti a ba fe ko aroko apejuwe, bi o sise ri fun orisii aroko yooku niyen. Awon tigbese ti o se Pataki fun aroko kiko ni iwonyi:

 • Yiyan ori oro
 • Sise ilapa ero
 • Kiko aroko gan-an(iside/ifaara, aarin ati igunle/ikadi)
 • Lilo ojulowo ede (owe, akanlo ede,abbl)
 • Lilo akoto ode oni
 • Isowokowe ti o gunrege

 

ÌGBÉLÉWÒN

1.  Se alaye soki soki lori awon igbese ti a gbodo gbe bi a ba fe ko aroko

2.  Ko aroko alapejuwe lori ile-iwe re

3.  Se ilapa ero lori ori oro yii: Moto kan to wun mi ra

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1  Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni oju iwe 69-71 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba

2  Eko ede Yoruba titun iwe kjn-in-ni (J S S 1) oju iwe 107=112 lati owo Mustapha Oyebamji.

 

IKINI (GREETINGS)

AKOKO IKINI IDAHUN

Aaro/owuro Ekaaro o o o, a dupe

E e jiire bi o

Osan E kaasan o o o.

Irole E kuurole o o o

Ale E kale o o o

 

BI A SE N KI IKINI IDAHUN

Aboyun Asokale anfaani o e se o

Nibi isomoloruko E ku ijade oni adun a kari o

Nibi oku E ku aseyinde o eyin naa a gbeyin arugbo yin o

Onidiri Eku ewa/oju gbooro o o

Agbe Aroko bodun de o ase o

Osise ijoba oko oba o ni sayin lese o ami o

Ijoye kara o le wa a gbo.

Oba Kabiyesi o oba n ki o

Eni to n jeun lowo E bamiire o omo rere a ba o je

Nibi oku agba E ku aseyinde o e se o, eyin naa a gbeyin arugbo yin o

 

ÌGBÉLÉWÒN

1  Bawo ni won se n ki awon wonyi?

 • Onidiri
 • Agbe
 • Nibi oku agba

2  Bawo ni won se n ki eniyan ni

 • Aaro
 • Osan

 

APAPO ÌGBÉLÉWÒN

1.  Se alaye soki soki lori awon igbese ti a gbodo gbe bi a ba fe ko aroko

2.  Ko aroko alapejuwe lori ile-iwe re

3.  Se ilapa ero lori ori oro yii: Moto kan to wun mi ra

4  Bawo ni won se n ki awon wonyi?

 • Onidiri
 • Agbe
 • Nibi oku agba
 1. Bawo ni won se n ki eniyan ni
 • Aaro
 • Osan

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

New simplified Yoruba L1 iwe kin-in-ni [J s s1] oju we 5-7 lati owo S Y Adewoyin

 

ISE AMURELE

1  Ohun kin –in-ni ti a gbodo se bi a ba fe ko aroko ni —— (a) ilapa ero (b) ifaara (d) yiyan ori oro.

2  Idi ti a gbodo fi se ilapa ero ni —–(a) ki ori onkawe lewu (b) ki ero wa le kale ni sisentele (d) ki wa le dara .

3  Okan ninu awon wonyi je apeere ori oro ti a le ko aroko alapejuwe le lori (a) ija igboro ka ti o soju mi (b) ile iwe mi (d) ayeye ojo ibi ti o koja

4  E kaaro ni a maa n ki eniyan ni —- (a) oru (b) osan (d) aaro

5  Bawo ni won se n ki eniyan ni osan? (a) e ku aaro (b) e kaasan (d) e ku irole

 

APA KEJI

1  Awon ilana wo ni a le tele bi a ba fe ko aroko?

2  Ki awon wonyi

 • agbe
 • oba
 • nibi oku agba

 

 

 

ÒSÈ KEWAA

AROKO ALAPEJUWE ILE IWE MI

Bi a ba fe ko eyikeyi aroko, agbodo fara bale daadaa,ni akoko ti a ti ri ohun ti a fe ko ko aroko le lori ohun akoko ni yiyan ori- oro, leyin igba yii ni ilapa ero, ki aroko wa le gunrege pelu ero pipe.

 

A o gbodo fi owo kekere mu awon nnkan bi owe.akanlo ede,afiwe, akoto ode oni, ami ninu aroko. Awon nnkan wonyi dabi ki a fi iyo,magi,iru sinu obe ni. Fun apeere, e je ka wo aroko atonisona lori ile iwe mi.

 

ILE IWE MI

Oruko ile iwe mi

Agbegbe ibi ti o wa

Ipinle ibi ti o wa

Oruko oga ile iwe re

Kin ni ohun ti a koko mma ri bi a de ibe

Oluko melo ni o wa ni ile iwe re

Omo ile iwe melo ni o wa ni ile iwe re

Iru aso wo ni awon omo ile iwe re n wo

Se ile ile ni ile iwe re ni abi ile iwe alaja meta,merin……

Nje o feran ile iwe re

Kin ni o fa ti o fi feran ile iwe re

Ki ni o mu ile iwe re yato si ile iwe miiran……….

 

ÌGBÉLÉWÒN

Ko aroko lori ile iwe re

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWA

1  Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni oju iwe 82-84 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

2  Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni ( J S S1 ) oju iwe107-122 lati owo Oyebamji Mustapha

 

AKAYE

Labake je omo ti o ni iteriba pupo.Eniyan dudu ni. O ga to iwon ese bata merin.

 

O ja fafa lenu eko re.Okan baba ati iya re maa n bale ni opo igba tori pe won mo iru omo ti won bi.

 

Ni ojo kan. Idije waye laarin Labake ati awon egbe re sugbon Labake ko ko ibi ara si igbaradi idije yii.Fun idi eyi o siye meji, awon egbe re si ja a kule.Iyalenu gbaa ni eyi je fun awon obi re.

 

Won bi leere pe, eese ti awon elegbe re fi fidi e janle? O ni nitori pe oun maa n fidi janle ni ojoojumo.

 

ÌGBÉLÉWÒN

1  Ta ni o dudu ti o si ga to iwon ese bata merin?

2  Tani o ja kule ninu idije?

 

APAPO ÌGBÉLÉWÒN

1  Ta ni o dudu ti o si ga to iwon ese bata merin?

2  Tani o ja kule ninu idije?

3  Ko aroko lori ore re.

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni oju iwe 94-95 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

 

ISE ASETILEWA

1  Okan ninu awon wonyi ko se Pataki ti a ba fe ko aroko alapejuwe (a)ipinro (b) akoto ode oni (d) eka ede

2  Iru aroko wo ni ori oro yii oja ilu mi. (a) oniroyin (b) alaaye (d) alapejuwe

3  Bi a ba ti ko ori oro aroko tan, ohun ti o kan ni ……(a) ilapa ero (b) ifaara (d) ipirno

4  Ti a ba ka akaye tan ohun ti o kan ni …. (a) ki a dahun ibeere (b) ki a bere si ni dahun ibeere (d) ki a tun aroko naa ko

5  Nnkan ti a fe mo bi a ba fun akekoo ni aroko ni…..(a) bi o se gbo ede Yoruba to (b) bi o se mo owe to (d) bo se le ka iwe to.

 

APA KEJI

1  Ko ilapa ero lori ore mi ti iwa re wu mi

2  Ko aroko lori ile iwe mi
Share this:


EcoleBooks | 1ST TERM JSS1 YORUBA Scheme of Work and Note

subscriber

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Accept Our Privacy Terms.*